Ariwo Yoruba Nation yóò lólẹ́ tí Tinubu bá di Ààrẹ - Folarin

- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo. Oloye Teslim Folarin ti ṣalaye pe oun ko nifẹ si bi nkan ṣe n lọ lorilẹede Naijiria amọ oun ni igbagbọ pe kete ti oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ba ti wọle, iyipada a de.
Folarin sọ eleyi nigba to kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba lori opo ibanidọrẹ Facebook laana.
O ni latari bi nkan ṣe ri, eyi ti ko dun mọ ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ninu, ti wọn si fẹ atunṣe, lo mu ki awọn eeyan kan maa pe fun idaduro ilẹ Yoruba.
“Mo fẹran Naijiria gan sugbọn n ko fẹran bii nkan ṣe n lọ lorilẹede Naijiria .
“Awọn eeyan to pariwo Yoruba Nation ko fẹran bii nkan ṣe lọ ni ara fi n kan wọn, ti a ba ti ṣe ti onikaluku ni ijọba ẹlẹmẹkun ti rẹ , Naijria a da, iyipada a de.
“Lagbara Ọlọrun, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni yoo ṣe aarẹ orilẹede Naijiria, mo ni igbagbọ pe iyẹn gan yoo mu ki ariwo Yoruba Nation lọ silẹ.”
Àìsunwọ̀n Seyi Makinde ni èèyàn Oyo fi ń rántí Ajimobi
Bakan an ni Oloye Teslim Folarin tun salaye pe ijakunlẹ iṣejọba Seyi Makinde nipinlẹ Oyo lo mu ki awọn eeyan ipinlẹ naa ma ṣe iranti iṣejọba gomina ana to doloogbe, Abiola Ajimobi.
O ni kudiẹkudiẹ eyi ti ko ni ẹlẹgbẹ ni Seyi Makinde fi n ṣe ijọba ipinlẹ naa, paapa julọ bii eto abo ṣe mẹyẹ, eyi ti ko si ri bayẹn tẹlẹ laye Gomina ana, Abiola Ajimọbi
“Laye Ajimobi, ko ni aye silẹ fun iwa jagidi jagan rara, ti o si tun pe abo kaakiri origun mẹrin ipinlẹ Oyo.
“Ẹni to ba nipa ipinlẹ Oyo, a ripe nnkan ti bajẹ jina.
“Seyi Makinde lọ mu ẹlẹwọn ko wa ma dari awakọ nipinlẹ Oyo, ẹlẹwọn ọhun naa lo lepa ẹmi mi kaakiri.”
Ọ̀tẹ̀ ni Ibadan ń ṣe, kìí ṣe òṣèlú, ló gbé Makinde wọlé gómìnà - Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, OTHERS
"
Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Oyo, Oloye Teslim Folarin ni iwọle gomina Seyi Makinde gẹgẹ bii gomina ko ṣeyin bii awọn oloṣelu kan ṣe fọwọsowọpọ lati ṣe ọtẹ gomina ana to ti di oloogbe, Abiola Ajimobi, eyi ti wọn ni awọn fẹ fi fi iya jẹ ẹ.
Folarin ṣalaye awọn ọrọ yii nigba to kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC News Yoruba lori opo ibanidọrẹ Facebook lọsan oni.
O ni awọn oloṣelu kan lo gbimọ pọ pe ki awọn sisẹ pọ pẹlu ọtẹ lati gbe Makinde wọlẹ nitori pe oun lo gba asia ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun naa.
“Ọtẹ ni Ibadan n ṣe, kii ṣe oṣelu, ọtẹ lo gbe Makinde wọle Gomina ipinlẹ Oyo.
“Ifọwọsowọpọ awọn oloṣelu kan lo gbe Makinde wọlẹ nitori wọn ni awọn ko fẹ Ajimobi mọ, ko ki n ṣe pe Makinde ni riri to pọ to bẹ lati ṣe oṣelu.
“Makinde n kọ oṣelu lọwọ lo di gomina nitori ibẹẹrẹ oṣelu ni ki awọn eeyan mọ eeyan. Ko mọ bi wọn ṣeṣe pẹlu awọn eeyan to wa ni ẹsẹkuku ati pẹlu awọn alakọwe.
“Ọkan lara awọn fasiti to daraju ni mo lọ, fasiti ilẹ Ibadan ati Havard niluu London sugbọn nigba ti mo pada de, Baba Adedibu ni to ba ṣe oṣelu, o ni lati gbe gbogbo iyẹn si ẹgbẹ kan.
“Makinde o mọ bi wọn ṣe ba awọn eeyan sọrọ ni ẹsẹkuku ati igberiko.
Folarin ni ti a ba wo itan ipinlẹ Oyo, gbogbo awọn to ti jẹ gomina ni wọn bẹrẹ lati ibi kan ki wọn to di gomina ṣugbọn oun ni igbagbọ pe oye Makinde ko kun to.
“Baba Lam jẹ aṣofin, ki wọn to jẹ gomina, Ladoja jẹ sẹnẹtọ, ko to di gomina, Akala jẹ alaga ijọba ibilẹ ati igbakẹji gomina ko to di gomina, Ajimobi naa ṣe sẹnẹtọ ko to di gomina.
“Gbogbo wọn mọ bi wọn ṣe ṣe kini yii ki wọn to di gomina ṣugbọn ti Ọlọrun ba ṣe fẹ ṣe nkan rẹ ni yoo ṣe.”

Ida maaki kan ati abọ ninu maaki mẹwaa ni maa fun iṣejọba Makinde
Oloye Teslim Folarin ni ti wọn ba ni ki oun wọn maaki fun iṣejọba Seyi Makinde nipinlẹ Oyo, oun yoo fun ida maaki kan ati abọ ninu maaki mẹwaa.
O ni gbogbo ọna ni kudiékudiẹ ti de ba iṣejọba rẹ, to fi jẹ wipe ọpọ igba ni awọn araalu n rẹnti alaafia ti wọn ni anfani eto abo to peye lasiko iṣejọba Oloogbe Abiola Ajimobi.
“Ti wọn ba ni ki n wọn iṣejọba rẹ, maa fun un ni ida maaki kan ati abọ ninu ida maaki mẹwaa.
“Pẹlu gbogbo iriri mi kaakiri, nkan to yẹ ki wọn ṣe kọ ni wọn ṣe, eyi ti n ba tiẹ ni pe ko fi pe meji ni ti papa iṣere ti wọn tunṣe, ti gbogbo yin si mọ nnkan to tẹ yin rẹ yọ.”















