Ilé ijó "Gay Club" dàrú! Ẹ wo bí agbébọn ṣe pa èèyàn márùn-ún lásìkò ìgbádùn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn eeyan to wa ni ile igbafẹ awọn ọkunrin to n fẹ ọkunrin ẹgbẹ wọn ni wọn ti kan sara si fun ipa ti wọn ko lati doola ẹmi awọn eeyan kan lasiko ti ọkunrin agbebọn kan kọlu ile igbafẹ naa.

Ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Colorado, John Suthers ni lasiko ti ọkunrin naa n ṣe ikọlu si Ile igbafẹ Club Q, ọkan lara awọn to wa nibẹ lo gba ibọn lọwọ rẹ, to si gba a mọ lori lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja.

Bakan naa ni ẹlomiran naa ṣe akitiyan lati mu ọkunrin ọhun mọlẹ titi di asiko ti awọn ọlọpaa de sibi isẹlẹ naa.

Ọkunrin ọhun ṣekupa eeyan marun un, ti eeyan mẹẹdogbọn miiran si farapa yanayana ki ọwọ to tẹ.

Afurasi naa, Anderson Lee Aldrich, ẹni ọdun mejilelogun lo ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa bayii.

Suthers ni oun kan sara si awọn eeyan fun bi wọn ṣe fi iṣẹlẹ to ileeṣẹ ọlọpaa leti, o ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii iwa akinkanju.

“Ipe wọn dun ni ileeṣẹ ọlọpaa ni dede ago mejila ku isẹju mẹta, ti a si de sibẹ ni dede ago mejila.” O sọ fun CNN.

“Iṣẹlẹ naa ti wa sopin ni dede ago mejila kọja isẹju meji sugbọn a ri igbinyanju awọn eeyan kọkan lati dola ẹmi awọn eeyan, ti wọn si koju ọkunrin agbebọn ọhun.

“Bii o ṣe jẹ isẹlẹ buburu fun wa to, a ni lati kan sara si awọn eeyan yii fun iwa akikanju ti wọn hu.

Gomina Cololardo ati oludadilẹ Club Q naa ti kan sara awọn eeyan ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ko tii le ṣafihan iye awọn eyan to farapa ninu isẹlẹ naa sugbọn awọn ti ko awọn eeyan to farapa lọ si ile iwosan.