''Yíyan Shettima ní igbákejì mi kò níí ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìdí abájọ rèé...''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Oludije sipo aarẹ lati inu ẹgbẹ́ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Ahmed Tinubu ti salaye idi to fi yan gomina ipinlẹ Borno nígbà kan, Kashim Shettima, gẹgẹ bi igbakeji rẹ fun eto idibo ọdún 2023.

Tinubu sọ ọrọ naa lasiko to ṣe ipade pẹlu awọn adari ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, n'ilu Abuja lọjọru.

O ni yiyan Shettima ko ni nkankan ṣe pẹlu ọrọ ẹsin rara, àmọ́ o jẹ ète lati bori ìdìbò.

"Yiyan ẹlẹ́sìn Kristẹni ni kò bá rọrùn ju, àmọ́ eto oṣelu asiko yii ko gba bẹẹ. Mimu Shettima ni igbakeji mi jẹyọ lati ara èròngbà mi lati koju àwọn ipenija ti Naijiria ni."

Tinubu sọ pe Shettima ni àwọn amuyẹ adari to ni túmọ̀, iru eyi to lo nigba to fi jẹ gomina ipinlẹ Borno.

O ni àwọn ipenija to n koju Naijiria ko gba fifi ọrọ ẹsin yan eeyan sipo, biko ṣe awọn to kaju ẹ.

Bakan naa lo sọ fún àwọn adari CAN pe bi oun ati igbakeji rẹ, Shettima ṣe jọ jẹ Musulumi, kò nii ṣe akoba fun ohunkóhun.

Ẹgbẹ CAN ṣètò ipade ati ijiroro naa lati gbọ nkan ti gbogbo àwọn olúdíje fun ipo aarẹ ni lọkan lati ṣe.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ́ karundinlogun, oṣu Kọkanla, ni ijiroro naa ti bẹrẹ.

''Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dára fún wa láti ìgbà tí Tinubu ti gbàdúrà fún PDP''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni lati igba ti oludije lẹgbẹ oṣelu APC ti gbadura fun wọn ni nkan ti bẹrẹ si ni dara fun ẹgbẹ osẹlu PDP

Ninu atẹjade ti wọn fi si oju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni ẹgbẹ oṣelu naa ti sọ.

Eyi ko ṣẹyin bi Tinubu to n dije du ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ṣi ọrọ sọ lasiko to n si ikede ipolongo idibo rẹ ni ilu Jos.

Tinubu sọ pe ki Ọlọrun bukun fun ẹgbẹ oṣelu PDP amọ APC lọ fẹ sọ.

PDP ni lati igba ti Tinubu ti gbadura naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti n gba ipe ayọ ati atẹjisẹ ibanidọrẹ lati ọdọ awọn eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC.

Wọn ni igbagbọ awọn ni pe Ọlọrun gba ẹnu Tinubu lati ṣọ aṣẹ ayọ si ẹgbẹ oṣelu naa lati tukọ orilẹede Niajiria.

Atẹnumọ pe Bola Tinubu ko kunjuwọn lati tukọ Naijiria – PDP

Aworan Asiwaju Bola inubu

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni igbagbọ awọn nipe Tinubu ko kunjuwọn lati tukọ orilẹede Naijiria lo ṣe n ṣi ọrọ sọ.

Wọn ni ẹsun gbigbe oogun oloro ti wọn fi kan an, ti wọn ko ri ọrọ sọ si, to fi mọ aisi ẹkunrẹrẹ iroyin nipa ọjọ ori, oruk̀ọ rẹ ati ibi to ti ṣẹ wa fihan pe, ipọ aarẹ ko tọsi Tinubu.

Wọn ni olootọ eniyan ni ipo naa yẹ fun ti yoo si ṣe atunṣe si eto ẹkọ, ọrọ aje, igbanisiṣẹ ati eto aabọ to dẹnukọlẹ ni Naijiria.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni ti wọn ba dibo fun Tinubu, iwa jẹgudujẹra to n waye ni ijọba aarẹ Buhari yoo tẹsiwaju, ti yoo si buru ju ti tẹlẹ lọ.

Bakan naa ni wọn kesi Tinubu ko tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria ko si kọ iwe fi ipo silẹ.

Amọ Tinubu ati ẹgbẹ osẹlu APC ko i tii fesi si ọrọ ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi lede naa.

Ṣé lóòtọ́ ní Tinubu polongo pé kí Olórun bùkún fún PDP ní Jos?

Aworan ibudo eto naa

Oríṣun àwòrán, APC special ops new media

Eto ipolongo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti gbera sọ ni ilu Jos to jẹ olu ilu Plateau.

Ọ̀pọlọpọ ero lo kun papa iṣere naa fọfọ ti wọn si n pariwo ẹgbẹ APC ati orukọ Tinubu ati Shettima.

Sugbon lẹyin ti oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu naa gba gbohungbohun lati sọtọ lo ba awọn ero ibẹ sọrọ akin pe Naijiri aṣi maa dara sii.

Bakan naa ni Bola Tinubu gbadura pe ki Olorun bukun fun Naijiria lẹẹmeji ko to dabi pe o wa ṣẹṣi sọ pe ki Olorun bukun fun ẹgbẹ oṣelu alatako rẹ, PDP nibi to si ti sare yi ọrọ rẹ pada pe ki Olorun bukun fun ẹgbẹ oṣelu rẹ iyẹn APC.

Eyi lo si ti n fa awuyewuye lori ayelujara bayii

Tinubu, Shettima bẹ̀rẹ̀ ìpolongo ìbò ààrẹ wọn nílú Jos

Nṣe ni eto abao gbopọn dọindọin ni ilu Jos tii ṣe olu ilu ipinlẹ Plateau ni Naijiria.

Loni ọjọ Iṣẹgun pẹlu bi ikọ oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa ṣe fẹ lọ ṣe ifilọlẹ ipolongo ibo fun aarẹ nibẹ.

Ọpọ awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu APC lo ti kun papa iṣire Rwang Pam nilu Jos ni kutukutu owurọ.

Lati kopa ninu eto naa ti wọn si n reti ifarahan Ahmed Bọla Tinubu ati igbakeji rẹ Kashim Shettima lati wa ṣide ipolongo wọn.

Nṣe lawọn ọmọ ogun ti wọn di ihamọra ogun, awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ agbofinro abo ẹni labo ilu ti lu agbegbe naa pa lati rii pe abo to peye wa nibi eto naa.

Aarẹ Muhammadu Buhari lo lewaju awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC nibi ayẹyẹ naa.

Aarẹ Buhari gunle si Jos fun iside ipolongo ibo fun Tinubu ati Shettima

Oríṣun àwòrán, APC

Lara awọn to ti gunlẹ sibi eto naa ni Oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu pẹlu igbakeji rẹ, Kashim Shettima.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Abdullahi Adamu, gominia ipinlẹ Plateau to tun jẹ oludari agba fun igbimọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC, Simon Lalong.

Tinubu n lepa ipo aarẹ Naijiria ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Abubakar Atiku (PDP), Peter Obi (LP) ati Kwankwaso (NNPP)