Ogun tí Russia ń gbé kojú wá ń parí lọ díẹ̀díẹ̀ - Ààrẹ Ukraine, Zelensky

Volodymyr Zelensky

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ti sọ pe ogun ti Russia n gbe ti orilẹ-ede naa ti n pari lọ diẹdiẹ ni bayii ti awọn ti gba ilu Kherson pada.

Zelensky lo sọ bẹẹ lasiko to ṣabẹwo si awọn ọmọ ogun to wa nibẹ.

O sọ fun awọn ọmọ ogun naa pe orilẹ-ede ọhun ni itẹsiwaju ninu ogun naa, awọn si ti ṣetan bayii fun alaafia.

Volodymyr Zelensky

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bo tilẹ jẹ orilẹ-ede Russia ṣi n sọ pe ikawọ oun ni ilu naa wa, Ukraine ni oun ti gba ilu naa pada.

Inu oṣu Kẹta ọdun yii ni Russia kọkọ gba ilu Kherson lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn kọkọ gbogun ka orilẹ-ede naa mọle.

Lẹyin ti wọn gba ilu naa, Russia kede pe o di ọkan lara awọn ilu to wa ni iṣakoso oun gẹgẹ bo ṣe gba awọn ilu mii bii Luhansk, Donetsk ati Zaporizhzhia.

Laarin ọsẹ diẹ sẹyin, Ukraine ti ṣe awọn aṣeyọri diẹ ninu lati gba Kherson lọwọ ikọ ọmọ odun Russia.

Lọsẹ to kọja, ikọ ọmọ ogun Russia fi agbegbe naa silẹ, ti ikọ ọmọ ogun Ukraine si wọle sibẹ.

Igbesẹ naa dun mọ awọn eeyan to n gbe nibẹ ninu to bẹẹ ti wọn fi n kọ orin ọpẹ, nibẹ naa lawọn mii ninu wọn ti n yọ mọ awọn mọlẹbi wọn ti wọn ko tii ri fun ọjọ pipẹ.

Nigba ti Aarẹ Zelensky yoo fi de ibẹ lọjọ Aje, awọn eeyan naa kọ orin ogo Ukraine, wọn si ri asia orilẹ-ede naa si oke ile kan nibẹ lati ṣafihan pe o ti pada si ikawọ awọn.

Zelensky sọ fun wọn pe Ukraine “ti ṣetan lati gba alaafia laaye” fun gbogbo orilẹ-ede naa.

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ ajọ Nato atawọn ajọ mii to ti orilẹ-ede rẹ lẹyin ninu ogun ọhun.