Kanu kọ̀ láti farahàn ní ilé ẹjọ́, Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ míràn ọjọ́ ire

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, other

Ile ẹjọ giga apapọ Naijiria kan nilu Abuja ti sun igbẹjọ di ọjọ miran ọjọ ire lori ẹjọ ẹsun meje tuntun to da lori igbesunmọmi eyi ti ijọba apapọ tun n pe tako aṣiwaju ẹgbẹ to n ja fun ominira ẹya Igbo, IpoB, Nnamdi Kanu lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti daa silẹ.

Ijọba apapọ Naijiria n pe Nnamdi Kanu lẹjọ miran lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti da a lare lọsẹ diẹ sẹyin lori ẹsun marundinlogun ti ijọba apapọ gbe lee laya lori ọrọ igbesunmọmi yii kan naa.

Agbẹjọro fun Kanu, Mike Ozekhome SAN sọ fun ile ẹjọ pe ko si idi fun ile ẹjọ naa lati tun maa gbọ ẹjọ yii nigba to wulẹ jẹ wi pe ijọba apapọ Naijiria yii kan naa ti pe ẹjọ kotẹmilọrun niwaju ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Ozekhome rọ ile ẹjọ giga apapọ naa lati kuku sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ miran, ọjọ ire titi ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ kotẹmilọrun ti ijọba pe tako idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Agbẹjọro fun ijọba apapọ, Amofin Abubakar ni oun ko tako ipe fun isunsiwaju igbẹjọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ṣe lootọ ni pe Nnamdi Kanu kọ lati fara han niwaju ile ẹjọ lọjọ Aje?

Ṣaaju ki ọrọ isunsiwaju naa to bẹrẹ ni Onidajọ Binta Nyako ti beere aṣiwaju ẹgbẹ to n ja fun ominira ẹya Igbo, IpoB naa nile ẹjọ nigba ti ko kofiri rẹ ninu yara igbẹjọ naa lọjọ Aje.

Agbẹjọro fun ijọba apapọ fesi pe olujẹjọ, Nnamdi Kanu kuna lati farahan nile ẹjọ.

O ni nigba ti oun kan si ọfiisi awọn ajọ agbofinro DSS pe ki wọn gbe olujẹjọ naa wa sile ẹjọ ni wọn fi to oun leti pe o ti faake kọri nibẹ pe oun ko ni yọju si ile ẹjọ lọjọ Aje.

O ni lati ọsẹ to kọja ni wọn ti fi to Nnamdi Kanu leti pe yoo foju ba ile ẹjọ loni nitori naa iyalẹnu lo jẹ pe “olujẹjọ naa ji loni o si kọ lati wa si ile ẹjọ.”

Agbẹjọro fun Nnamdi Kanu, Mike Ozekhome sọ pe kayefi nla leyi o nitori pe ohun to han si gbogbo araye ni pe, olujẹjọ yii kii fẹ pa ile ẹjọ jẹ rara lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ.