Ọ̀lẹ ní àwọn DSS ní Naijiria, TV ni wọ́n máa ń wò nígbà tí mo wà ní páńpẹ́ wọn- Ṣowore

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu ni Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ijọba lori eto ọrọ aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
Awọn oludije ti ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, Omoyele Sowore, oludije lẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, Yabagi Sani, oludije lẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, Adewole Adebayo ati oludije lẹgbẹ oṣelu the All Progressives Grand Alliance, Peter Umeadi lo fi ero wọn lede
Awọn wọnyii ni awọn yoo ṣe gudugudu meje lori eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
Àwọn olùdíje tàbùkù ìjọba Buhari lórí ìwà ìbàjẹ́ àti ọ̀rọ̀ ètò ajé tó dẹnukọlẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn oludije yii ni wọn sọ eyi lasiko ipade itagbanga ti ileeṣẹ iroyin Tẹlifisọn Arise TV gbe kalẹ fun awọn oludije sipo aarẹ lorilẹede Naijiria.
Awọn oludije yii ni wọn bu ẹnu atẹ lu aibikita ijọba aarẹ Buhari si eto aabo , eleyii ti wọn ni ohun lo faa ti o fi dojubolẹ lasiko yii.
Ninu ọrọ rẹ, Sowore ni awọn eṣọ alaabo to wa ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ ko ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ ni ko ṣe si ọna abayọ si igbesunmọmi ati iṣẹlẹ awọn agbebọn ni Naijiria.
‘’Oṣu marun un gbako ni mo lo ni panpẹ awọn DSS, niṣe ni wọn wo BB Naijiria yala ki wọn maa ṣe iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wọn.’’
‘’Bakan naa ni ko si adari fun ẹka eto aabo ni Naijiria, wọn kan n ṣe nkan to wu wọn ni ẹka naa.’’
Ninu ọrọ tirẹ, oludije lẹgbẹ osẹlu ADP sani fi ẹsun kan aarẹ Buhari lori ijọba rẹ, wi pe iwa ajẹbanu pọ lasiko rẹ.
Bakan naa ni oludije fun SDP, Adebayọ wa rọ awọn oludije gbogbo lati mu eto eto aabo ni kunkundun lati doola ẹmi awọn eniyan.
O ni ijọba to wa lode yii ko tilẹ karamasiki ọrọ eto aabo araalu, eleyii to kọ ohun lominu.















