Àrá sán lù ojú òpó ìgbéra ní pápákọ̀ òfúrúfú, kò sí bàálù tó lé gbéra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo iwọlejade baluu ni papakọ ofurufu Valencia lorilẹede Spain ti duro bayii lẹyin ti ara san lu oju opo igbera ati ibalẹ baluu ni papakọ ofurufu naa lọjọ Satide lẹyin ti obitibiti ojo ti rọ nibẹ.
Awọn alaṣẹ lorilẹede naa sọ pe alẹ ọjọ Ẹti ni iji lile naa ti bẹrẹ da ọpọwahala silẹ lẹkun ila oorun orilẹede naa pẹlu ọwọ atẹgun lile ati ojo, eleyi to tun pọ si lọjọ Satide.
Ileeṣẹ to n ṣe amojuto papakọ ofurufu lorilẹede Spain AENA sọ pe, “Papakọ ofurufu Valencia ko si fun lilo mọ bayii lẹyin ti ara san lu u. Iṣẹ atunṣe yoo bẹrẹ laipẹ.”
Bakan naa lo tun sọ pe wọn ti gbẹsẹ le gbogbo awọn irinajo ofurufu wọ papakọ ofurufu naa tabi jade nibẹ nitori iji lile naa.
Gẹgẹ bi iroyin ti papakọ ofurufu Valencia fi sita, ko din ni baluu mẹsan an to n ko ero bọ ni papakọ ofurufu naa ti wọn ti da ori rẹ kọ awọn papakọ ofurufu miran to wa layika rẹ ni Alicante, Barcelona, Ibiza ati Madrid.
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri lagbegbe naa kọọ soju opo Twitter rẹ pe nigba ti omi kọkọ ya bo oju opo baluu to wa ni papakọ ofurufu naa ni wọn ti kọkọ da owo lilọbibọ baluu duro nibẹ
Awọn fọnran aworan ti wọn fi si oju opo Twitter ṣafihan ọwọ agbara omi ti ọwọ rẹ le nitosi papakọ ofurufu naa.
Bakan naa ni iji lile yii tun mu idaduro ba ọpọ reluwe ayarabiaaṣa lagbegbe Valencia gẹgẹ bi ileeṣẹ ADIF to jẹ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ to n mojuto igbokegbodo ọkọ reluwe nibẹ.












