Njẹ́ lílo òògùn tàbí gba abẹ́rẹ́ láì jẹun le fa ikú òjijì?

Nọọsi to n fun alaisan ni abẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Broadcast Journalist

Laipẹ yii ni iroyin jade lori bi ẹbi kan ṣe n wa idajọ lẹyin ti ọmọ wọn, ọmọ ọdun mẹrin kan ku, ti wọn si ni abẹrẹ ti nọọsi fun nileewosan lai tii jẹun lo fa iku rẹ nipinlẹ Eko.

Nitori eyi ni BBC se ba awọn onimọ sọrọ pe ṣe lootọ lo ṣeeṣe ki eeyan kú to ba gba abẹrẹ inu ofifo.

Ṣe gbigba abẹrẹ lai tii jẹun le fa iku?

Onimọ kan nipa bi ọkan ṣe n ṣiṣẹ si ninu ara, Dokita Habibah Aminu, to n ṣiṣẹ ni ileewosan ijọba apapọ, Federal Medical Centre, Lokoja, sọ pe ẹnikẹni ko le sọ pe abẹrẹ ti alaisan gba lo ṣekupa a, lai ṣe ayẹwo oku naa.

O ni ki eeyan to le sọrọ nipa nkan to fa iku, eeyan nilo lati mọ ibi ti ọrọ ti wọ́, nitori pe awọn oogun kan wa ti ko ni ewu tabi pa ẹni ti ko tii jẹun lara.

“Àwọn oogun kan wa ti awọn dokita ma n sọ fun alaisan lati lo lai jẹun.”

Bakan naa lo sọ pe ko ṣe e ṣe ki abẹrẹ ti eeyan gba fun itọju dá fa iku alaisan.

“Nkan to ṣe e ṣe ko ṣẹlẹ ni ki oogun l’agbara ju fun ara ẹni naa, eyi to le fa gìrì.”

Onimọ ilera mii, Dokita Mariam Kadri, to jẹ Ọga agba ni ẹka itọju awọn ọmọde nileewosan FMC niluu Bida nipinlẹ Niger naa sọ pe, gbigba abẹrẹ sinu ofifo ko le fa iku ojiji.

Dokita Kadri ni nkan ẹyọkan to le ṣẹlẹ ni pe ki aarẹ mu ara ẹni naa.

Idi ti to fi ṣe pataki lati gba awọn abẹrẹ tabi oogun kan lai tii jẹun

Nọọsi to n fun alaisan ni abẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi akọilẹ ni oju opo ayelujara ajọ ilera ilẹ Gẹẹsi, awọn oogun kan nilo ki alaisan lo wọn lai ti jẹun tabi lẹyin ounjẹ.

Awọn idi mẹrẹ̀ẹ́rín naa ni:

  • Nitori ki eeyan o ma ba a bì tabi ki àyà ma a rìn-ín

Eyi ri bẹẹ nitori pe awọn oogun kan ma n fa ki eeyan o bì tabi aya rinrin.

  • Lati mu adinku ba inu rirun, to fi mọ ki ounjẹ o ma dà, ọgbẹ inu ati inu wíwú

Awọn oogun kan wa to ma n da inu ikùn rú, nitori naa lo ṣe ṣe pataki lati lo wọn pẹlu ounjẹ. Awọn nkan jijẹ bii bisikiiti, burẹdi tabi ife miliiki kan ti to lati mojuto awọn nkan bi aya tita, ati bẹẹbẹẹ l.

  • Lati rii daju pe oogun wọ inu ẹjẹ

Awọn oogun nilo ki ounjẹ wa ninu ikun, ki wọn to raaye ṣiṣẹ daadaa ninu ara nipasẹ ẹjẹ

  • Lati mu ki ara ṣe atupalẹ ounjẹ

Awọn oogun fun aisan bii it ṣuga, ti wọn maa n lo lati ẹnu ma n ṣaba nilo ki eeyan lo o ni asiko ounjẹ.

Eyi yoo mu adinku ba iye ṣuga ti yoo wọ inu ẹjẹ lẹyin ti a ba jẹun tan, yoo si tun dena ki ṣuga inu ara kere.

Ajọ eleto ilera naa sọ pe o sàn ki eeyan beere lọwọ dokita tabi apoogun to fun ni oogun dipo ki o kan lo o lai tẹle ilana to yẹ.