Mọ̀ nípa òògùn olóró Fentanyl tí àwọn kan fẹ́ má tà ní Naijiria báyìí

Oogun oloro Fentanyl

Oríṣun àwòrán, ndlea

Ajọ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro ni Naijiria, NDLEA ti fi ikede sita lori oogun oloro tuntun kan to fẹ ẹ di tita ni Naijiria.

Agbẹnusọ ajọ NDLEA, Femi Babafemi sọ ninu ikede kan ni ọjọ Iṣẹgun pe aṣiri ṣẹṣẹ tu si ajọ naa lọwọ nipa eto ti awọn kan n ṣe lati ko oogun oloro Fentanyl wọ Naijiria.

Babafemi sọ pe oogun oloro naa l’agbara ju Tramadol lọ ni ilọpo ọgọrun.

Bakan naa lo kilọ pe oogun naa ti wọn ṣe ni ọna ti ko tọ ọ, tun le fa iku ọwọọwọ laarin awọn ọdọ ti awọn oniṣowo rẹ fẹ ma a ta a fun.

Ajọ NDLEA sọ ninu atẹjade naa pe gbogbo igbesẹ to yẹ ni lo waye, lati ri i pe oogun oloro naa ko di tọọrọ fọn kale ni Naijiria.

O ni oogun naa n ko ipa to ju ìdá aadọrin lọ ninu iku, to si tun jẹ gboogi nkan to n fa aloju oogun ni America.

Nkan to yẹ ki o mọ nipa Fentanyl

Ajọ NDLEA sọ pe oogun oloro Fentanyl le jẹ olomi tabi lubulubu, to si le ma ni i iwe alẹmọ lebẹẹli lara. O ni wọn tun le da a papọ mọ awọn oogun mi ti dokita ba kọ fun alaisan.

“Eyi to jẹ olomi rẹ le wa lori igba gẹgẹ bi oogun ti wọn n fin sin iho imu, oogun oju tabi ipanu kekeeke.

“Nitori naa la ṣe n ke si awọn obi lati kiyesara, ki wọn si kilọ fun awọn ọmọ wọn lati ma dan oogun naa wo.

Nkan ti Fentanyl le ṣe ninu agọ ara

Onimọ nipa ilera kan, Bruce Ibiso, sọ fun BBC Pidgin pe oogun fun irora ni Fentanyl jẹ́.

Ọgbẹni Ibiso ṣalaye pe awọn akọṣẹmọṣẹ nikan lo ma n lo o fun alaisan, ti kii ṣe nkan ti wọn n ta lori igba laarin ilu.

O ni wọn ṣaba ma n lo fun alaisan ti wọn fẹ ṣe iṣẹ abẹ fun, tabi lati kun alaisan ni oorun.

“Ṣugbọn awọn eeyan buruku kan ti n gbiyanju lati ṣi i lo bi wọn ṣe ṣe si tramadol ati awọn oogun ikọ́ mii to ni codeine ninu nitori bo ṣe ma n mu ara gba yagi-yagi.”

Awọn ami lara ẹni to lo fentanyl

Ajọ NDLEA sọ pe wọn ami ti o fi le mọ ẹni to ti lo Fentanyl tabi lo o ju bo ṣe yẹ ni pe:

  • Ẹyin oju rẹ yoo ràn kankan
  • Yoo ma a sun ṣa a
  • O le daku
  • Eemi rẹ ko nii ja geere
  • Yoo da bi ẹni ti nkan fun ni ọrun
  • Yoo dara nu, awọ ara rẹ yoo da bi ẹni ti ko ni ẹjẹ tabi ko tutu.

Lootọ ni oogun naa jẹ eyi ti wọn n ṣe nileeṣẹ apoogun, amọ eyi ti a sọ yii ni awọn kan n ṣe lọna aitọ.

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni America, CDC, sọ pe oriṣiriṣi ọna ni ‘ayederu’ yii wa.

O ni eyi to jẹ lubulubu rẹ bi atike fi ara jọ awọn oogun mii.

Amọ wọn ṣaba ma n pòó mọ awọn oogun bi heroin, cocaine ati methamphetamine, ti wọn si tun ma n ṣe si onikoro ko le jọ awọn oogun irora mii.