Aago mẹ́ta òrú ní Joseph ẹni ọdún 65 dáná sún àwọn ọmọ ti Esther ẹni ọdún 35 kò wá fẹ́ ẹ

Àkọlé fídíò, Aago mẹ́ta òrú ní Joseph ẹni ọdún 65 dáná sún àwọn ọmọ ti Esther ẹni ọdún 35 kò wá fẹ́ ẹ

Ọsẹ to m bọ ni mo pinnu lati ko awọn ọmọ mi sọdọ ki ọkọ tuntun ti iyawo mi fẹ to dana sun wọn- Akinfolarin Liadi

BBC wa arabinrin to bi ọmọ marun un ti wọn jona mọle ni Ondo kan lati mọ ohun to ṣẹlẹ gangan.Ọlọ́pàá mú ọkùnrin tó d-áná sun ọmọ ìyàwó rẹ̀ márùn-ún ní Ondo

Esther Ojo to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji ṣalaye fun BBC Yoruba pe lẹyin ti oun kọ Liadi silẹ ni oun lọ fẹ Joseph ẹni ọdun marunlelọgọta.

O bimọ meji fun Joseph Ojo, o si ko ọmọ marun un to bi tẹle fun Liadi wa sile Joseph.

Liadi baba awọn omo to jona mole
Àkọlé àwòrán, Liadi baba awọn omo to jona mole ni Ondo

BBC tun wa Arakunrin Akinfolarin Liadi to jẹ baba awọn ọmọ to jona naa kan.

O salaye ipinnu rẹ lati mu awọn ọmọ naa sọdọ ṣaaju iṣẹlẹ yii ati ohun ti oun mọ nipa iṣẹlẹ naa pẹlu ibanujẹ.

Awọn ọlọpaa ti mu Joseph Ojo to dana sun awọn ọmọ naa bayii.

Meji ninu wọn si ti ku ni asiko ti a n ṣe ifọrọwanilẹnuwo yii.