Owó Náírà tí kò lè ra búrẹ́dì ni àwọn ọ̀ga wá fẹ́ ṣé àtúnṣe si - Adeboye

aworan

Oríṣun àwòrán, others

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Olori ijọ Redeem lagbaye, Pasitọ Enoch Adeboye ti bu ẹnu atẹ lu bi banki apapọ ati ijọba apapọ ṣe fẹ gbe igbesẹ lati ṣe atunṣe si owo beba N200, N500 ati N1000.

Pasitọ Adeboye ni ohun ibanujẹ lọ jẹ fun oun pe nnkan to kan ijọba lọwọ bayi ni bi wọn yoo ti ṣe atunṣe si owo naira eyi to ti lulẹ lawujọ agbaye.

Adeboye, sọ eleyi nibi ayẹyẹ ijọsin kan to waye nile ijọsin rẹ.

O ni koda owo naira ko yẹ ni owo beba rara nigba ti awọn araalu n koju inira lati ri nkan jẹ sẹnu wọn.

“Ti ẹ ba mọ ohun to n lọ lorilẹede wa, ko mu ọpọlọ wa rara mọ. Owo naira wa ko ti ẹ yẹ ni eyi ti yoo jẹ beba rara.

“Bẹẹ ni ebi pa awọn eeyan, ti wọn wa owo lati fi ra burẹdi ti wọn ma jẹ sinu.

Awọn ọga si ro pe ki a ṣe atunṣe si owo naira lo yẹ, ti ko ba tiẹ le ra burẹdi, yoo sa rẹwa loju.”

Adeboye ni Ọlọrun ko ti sọ fun oun boya eto idibo ọdun 2023 yoo waye

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, Adeboye ni pupọ awọn ọrọ gidi to n waye lorilẹede Naijiria lo ti di nnkan awada.

“A ni isoro lorilẹede wa, ti nnkan ko si jọ ara wọn mọ, to si ti di nnkan awada.

“Ti a ko ba lọ kọ bi wọn se n rẹrin lorilẹede Naijiria, eeyan le ni ẹjẹ riru.”

Adeboye ni Ọlọrun ko ti sọ fun oun boya eto idibo ọdun 2023 yoo waye sugbọn o kede awẹ ati adura fun orilẹede Naijiria.

O ni aawẹ naa yoo bẹrẹ lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kọkanla di ọjọ keji oṣu kejila ọdun 2023.