"Ọkọ mi kò ráyè wọ ojú ara mi láti já ìbálé lẹ́yìn oṣù kan ta ṣe ìgbéyàwó"
Vaginismus: Obìnrin kan tó ní àìsàn Vaginismus rí sọ ìrírí rẹ̀ àti bó ṣe bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀
Ọpọ ipenija lo maa n koju tọkọtaya ti wọn si maa n se ni iso inu ẹku, arunmọra.
Lara iru ipenija bẹẹ ni awọn ipenija to nii se pẹlu ọrọ ibalopọ laarin wọn eyi to maa n nira lati sọ fun ẹbi, ara tabi awọn ọrẹ wọn.
Lara awọn ipenija bẹẹ ni aisan kan to maa n bawọn obinrin ja eyi ti wọn n pe ni Vaginismus.
Ọpọlọpọ awọn obinrin ni aisan yii n ba finra, to si maa n nira fun wọn lati sọ sita, paapaa pẹlu awọn eeyan to sun mọ wọn.
Koda, ọpọ igbeyawo lo ti daru nitori aisan Vaginismus yii, nigba ti ọkọ iyawo ko ba le fi ara da mọ pẹlu iyawo rẹ.

Ki ni itumọ aisan Vaginismus?
Onimọ isegun kan to ba BBC Yoruba sọrọ, Ranti Ajayi ni itumọ aisan Vaginismus ni “isoro ti ọkunrin n ni lati wọle si oju ara obinrin.”
Vaginismus yii si lo tun ni o le tumọ si “ti obinrin ba ni inira lati ni ibalopọ pẹlu ọkunrin tabi ti ti o soro fun obinrin lati gba nnkan ọkunrin wọle sinu ara rẹ.”
Eyi tumọ si pe ọkunrin ko ri aaye wọle sinu oju ara obinrin nitori pe oju iho naa ko la to bo se yẹ tabi ko ran lati gba nnkan ọkunrin wọle.
Bi ọkunrin naa si fi tipa wọle, o le fa oju ara naa ya tabi ko se akoba nla fun iru obinrin bẹẹ.
Amọ aisan yii kii se wipe obinrin naa ko ni oju awẹ tabi pe obinrin naa ko ni oju ara sugbọn oju ara naa kan di pupọ ju tawọn obinrin mii lọ ni.
Ni asiko ibalopọ, iru obinrin bẹẹ le maa sọkun, ti ara r yoo si le gidi lati fa nnkan ọkunrin sinu ara rẹ.
Ki lo n fa aisan Vaginismus fun obinrin?
Gẹgẹ bi Ranti Ajayi ti wi, Aisan Vaginismus le jẹ amutọrunwa tabi adayeba.
Gẹgẹ bo se wi, amutọrunwa yii ni bi oju ara obinrin sa kan di lati ọrun, ti ko si fẹ to lati gba nnkan ọkunrin.
Tabi ki ara rẹ ma balẹ tabi tuka lati fa nnkan ọkunrin wọle lasiko ibalopọ.
Amọ aisan Vaginismus to ba jẹ adayeba ni eyi ti obinrin ba ni nitori awọn iriri to ti la kọja bii ki wọn ti fipa ba lopọ ri, to si n ranti iriri naa loore koore.
Iriri ifipabanilopọ naa si lo le mu ki ara obinrin ma balẹ mọ lati fa nnkan ọkunrin mọra fun ibalopọ tabi ki oju ara rẹ ma si silẹ lasiko ibalopọ.

Ọkọ́ mi ko raye wọle soju ara mi lati ja ibale mi lẹyin osu kan ta se igbeyawo – Obinrin to ni aisan Vaginismus
Ọna lati mọ bi aisan yii se maa n se awọn obinrin to ba ni iru rẹ, lo mu ki BBC Yoruba kan si obinrin kan to ti ni aisan yii ri, Titotluwa Sam-Oladapo.
Nigba to n ba wa sọrọ Titoluwa ni o soro fun ọkọ oun lati ni ibalopọ pẹlu oun, ti ko si ri aaye ja ibale oun lẹyin osu kan ti awọn ti se igbeyawo.
Obinrin naa, ti o ti bọ lọwọ aisan yii ni akoko to yẹ ki oun ati ọkọ oun maa sere ifẹ lati sere ọmọ ni awọn maa fi n sọrọ tabi dọwẹkẹ.
“O soro gan fun mi, mo maa n sunkun ni, n ko gba ki ọkọ mi fi ọwọ kan mi, ti ara mi yoo si le.
Bi mo se n se yii gan n mu ki ọkọ mi maa ro pe oun ni oun ko le ba obinrin se ni nitori o nira fun lati ri aaye wọle sinu ara mi.”
Bawo ni a se le wo aisan Vaginismus?
Dokita Ranti Ajayi ni obinrin le ran ara rẹ lọwọ lati bori aisan naa tabi ko sisẹ abẹ.
Dokita naa ni ki iru obinrin bẹẹ pọn omi sinu baafu, ko joko sinu rẹ, kos i fi ororo pa oju ara rẹ, ko maa ki ọwọ bọ oju ara rẹ diẹ diẹ, titi ti yoo fi maa la.
O wa gba awọn obinrin nimọran lati f ẹni to jẹ ọrẹ wọn, ko le rọrun fun lati ju ara silẹ ti akoko ibalopọ ba to.
“Bi obinrin funra rẹ ba n fi ororo ra oju ara rẹ loore koore, nigba to ba ya, oju ara naa yoo la, ti nnkan ọkunrin yoo si raye wọle to ba ya.
Koda, irora yẹn yoo maa dinku diẹ diẹ, ti yoo si bori aisan naa.
Bakan naa ni obinrin le se isẹ abẹ lati fẹ oju ara rẹ, ti nnkan ọkunrin yoo fi ri aaye wọle si lara.’

Mo se isẹ abẹ lori aisan Vaginismus amọ ko sisẹ, o tun n buru si ni – Titoluwa Sam-Oladapo
Nigba to n salaye fun BBC Yoruba lori ọna abayọ isẹ abẹ lati fẹ oju ara obinrin, Titoluwa Sam-Oladapo to ti la iriri yii kọja ni isẹ abẹ ko tan isoro toun.
“Mo se isẹ abẹ amọ ko sisẹ fun mi . Isẹ abẹ le wo oju ara amọ ko le wo ọkan, tori aisan naa ni nnkan se pẹlu ipo ti ọkan obinrin wa.
Se ni aisan yii tun le fun mi lẹyin ti mo se isẹ abẹ oju ara tan nitori ara mi kii si silẹ lati fa nnkan ọkunrin mọra lati j ko raye wọle.
Akoko yẹ le fun wa amọ a fi gbogbo ara wa si gan ni.”
Titoluwa wa gba awọn tọkọtaya to n la iru isoro yii kọja lati maa se nnkan meji yii:
Akọkọ, ki wọn tọkọtaya maa sere papọ, yatọ si akoko ibalopọ, ki wọn dijọ maa sere, ki wọn maa gbadun ara wọn, ki si maa kọkọ jẹ igbadun lai lo ibalopọ, ki ara obinrin naa fi silẹ.
Ikeji, ki ọkunrin gbe gbogbo igbesẹ lati jẹ ki ara obinrin naa balẹ pẹlu oun, ko le gba fun lati wọle nigba ti wọn ba setan lati ni ibalopọ.






