Ojútì, ìrẹ́nijẹ àti ìyà àìkàwé nídìí iṣẹ́ tíátà ti ọ̀pọ̀ òṣèré padà sí fásitì
Celebrity Education: Latin, Igwe, Imalian Boy àtàwọn òṣèré míì fi ewú orí kẹ́kọ̀ọ́jáde ní fásitì
Awọn agba lo ni a kii dagba kọja ohun ti a ko ba mọ nitori pe agba ko kan ọgbọn nini.
Bi ọrọ se ri ree pẹlu awọn agba osere tiata kan ti wọn ti wọn jẹ gbajumọ lagbo tiata amọ ti wọn ko jẹ ki okiki ti wọn ni ko si wọn lori.
Awọn osere tiata yii, ti wọn ko ko lọ sile ẹkọ fasiti ki wọn to di ilumọọka lawujọ lo pakiti mọlẹ lati gba ile ẹkọ fasiti lọ lati gba oye imọ ijinlẹ akọkọ pẹlu agbalagba ara.
Lara awọn gbajumọ osere tiata to lọ kẹkọ ni fasiti Crescent ni Olaiya Igwe, Mr Latin, Iya Sapon, Imalian Boy ati Yeye Yetunde.
Ọpọ eeyan ni yoo maa beere pe ki lo sun awọn Grandma ati Grandpa yii pada sile ẹkọ pẹlu awọn ọmọ ọmọ wọn lati dijọ joko kẹkọọ ni kilaasi?
Idi ree ti BBC Yoruba se fi ẹsẹ kan bẹ awọn akẹ́kọ agba yii wo ni kilaasi wọn lati mọ bi wọn ti n se si, ka si fi ọrọ wa wọn lẹnu wo.
Amọ a tete seto abẹwo ati ifọrọwanilẹnuwo naa, ko to di pe awọn akẹkọọ agba naa, to ti wa nipele eto ẹkọ to kẹyin, yoo kẹkọọ yege.

Oju ti mi lọjọ ti wọn fun mi lami ẹyẹ ni UK amọ ti ko si iwe akọsilẹ ile ẹkọ ti mo lọ, ti wọn le ka seti araye – Olaiya Igwe

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, ohun to gbe gbogbo wọn de kilaasi fẹrẹ fi ara jọra, to si ni nnka se pẹlu ojuti ati irẹwẹsi ọkan nitori aikawe bi awọn akẹẹgbẹ wọn kan.
Ninu ọrọ Ẹbun Oloyede, ti ọpọ eeyan mọ si Olaiya Igwe ni nnkan toun tori rẹ wa si ile-ẹkọ pada nipe o wu oun lati kọ ẹkọ kun ẹkọ mọ eyi ti mo ti ni lori iṣẹ ti mo n ṣe.
“Ni ọdun 2003, ni mo kọkọ rin irinajo lọ si United Kingdom, mo lọ gba ami ẹyẹ, nigba to to akoko ti wọn fẹ fun wa ni ami ẹyẹ, bi wọn ṣe bẹrẹ si n ka CV awọn to ka iwe ninu wa bayii, ori mi n wu ni.
Mo wa ni o maa ṣe o, lotitọ aye gbọ okiki, aye gbọ orukọ mi ṣugbọn ẹkọ ti o si n bẹ yii yoo maa jẹ idọti diẹ fun mi.
Igba ti a wa kuro ni ibi ti a ti gba ami ẹyẹ, ti a de ile ti wọn ko wa si, mo wa n ronu.
Mo ni Ọlọrun ọba sa aanu mi, wọn ni eeyan le kawe lagba, ti mo ba ri anfani ati kawex, gbogbo ọna ni maa fi lọ.”
Igwe ni ngba ti oun wa de 'Cresent University' oun tun ri pe oriṣiriṣi awọn nnkan tun wa ti oun ko mọ, to si jẹ pe ile ẹkọ naa ni wọn ti kọ oun.
Yẹyẹ ti awọn akẹẹgbẹ wa to kawe maa n fi wa se, lo gbe mi pada sile ẹkọ - Mr Latin

Ohun to gbe Bolaji Amusan, ta tun mọ si Mr Latin lọ sile ẹkọ naa ko yatọ si ti Olaiya Igwe ntori o ni aini imọ nipa akosilẹ iwe lo fi iya jẹ awọn, bi awọn tilẹ mọ nipa ba se le lo akọsilẹ naa.
O ni idi ree tawọn se pinnu lati lọ kọ akọsilẹ mọ ba se le lo o, ki mejeji wa papọ, ki iṣẹ naa le tẹsiwaju naa ni.
“Bi mo ṣe wa yii nisin, agbalagba ni mo fi n ka gbogbo iwe ti mo n ka, o di ile-ẹkọ giga mẹta ti mo lo bayii.
Agbalagba ni mo fi n ka iwe, ko dẹ si n nnkan to fa bi o ṣe wipe nigba ti a ba pe jọ pẹlu awọn ẹgbẹ wa ti wọn kawe, yeye ni wọn maa n fi wa ṣe.
Owo ti wọn maa fi n lọ awa, o kere amọ ko si nnkan ti wọn fi lọ awọn to kawe nitori awọn ẹgbẹ wọn lo wa nibi ti wọn ti maa tọwọ bọ iwe.
Wọn maa ba ara wọn sọrọ ni ọna ti o ma gba ye ara wọn, ṣugbọn awa ti a lọ kọ nita, bi o tilẹ jẹ pe a mọ isẹ naa gan, wọn ko gboriyin fun wa.”
Nigba to n dahun ibeere pe se ko mọ pe gbajumọ ati ilumọọka ni oun, ki lo de to gbe eyi silẹ, wa maa ka iwe.
Latin ni “ki ni a fẹ sọ pe a ti jẹ, ki ni a fẹ sọ pe a ti ni, to ba ni o ni orukọ ninu iṣẹ yii, ṣe o ti ni orukọ to Sunny Ade ni?
To ba ni o lorukọ ninu iṣẹ yii, se o ti lorukọ to Baba wa Ebenezer Obey ni abi Obasanjo.”
Wọn n fi ẹkọ rẹ mi jẹ ninu isẹ tiata tori aile sọ Gẹẹsi daadaa, lo gbe mi wa sile ẹkọ - Iya Sapon

Nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwafunmilayo Shonuola, ti wọn mọ si Iya Sapon lagbo tiata ni aimọye nnkan ni wọn ti fi ẹkọ rẹ oun jẹ ninu idi iṣẹ tiata.
O ni pe aini oye to ati aile sọ ede gẹẹsi daadaa si lo fa irẹnijẹ naa, idi si niyii to jẹ ki oun wa si ile-ẹkọ lati wa fi imọ kun imọ.
“Awọn nnkan mi wa ti a n ṣe, ti a ro pe ibẹ yẹn lopin si, amọ nigba ti a n gbọ idanilẹkọ nipa Yoruba, o yatọ.
Awa ti a n sọ Yoruba yii, ti a ro pe Yoruba ni a n sọ, a ṣe nnkan miran ni a n ṣe amọ ninu idanilẹko ti awọn olukọ wa fi n kọ wa, o jẹ ki awa mọ ọtun yatọ sosi.
Bi a ṣe le sọ Yoruba, agbekalẹ ẹ lerefe ati ni ijinlẹ bi a ṣe le lo, bi a ṣe le fi ami si awọn ọrọ wa ati lori, gbogbo ẹ ni wọn kọ wa to dẹ ye wa”
Aini iwe ẹri fasiti lọwọ fiya jẹ mi pupọ, wọn kii fẹ gbọ ọrọ ẹnu mi nibi tawọn to kawe ba wa – Imalian Boy

Gbajumọ osere tiata miran, Olugbenga Oladunni, taye mọ si Imalian Boy lagbo tiata naa ba BBC Yoruba sọrọ lori oun to sẹ di ẹlẹkọ agba lojiji.
O ni ko ti si ohun to jọ mọ tiata ninu gbogbo nnkan ti oun ṣe ere oritage mọ, a n ṣe sinima,.
Mi o ni iwe ẹri lọwọ, ti wọn ba n sọrọ nipa iwe ẹri nigboro, o ma n ri bakan lọkan mi tori pe, o ma n kan yan labuku.
Ti ẹ ba sọrọ de ibi kan, ti wọn ba ti ri awọn to ni iwe ẹri lọwọ, wọn a ni ẹyin ẹ dakẹ, ẹyin to ni iwe ẹri yẹn, ẹ jẹ ki a gbọ ohun ti wọn fẹ wi.”
Imalian Boy ni ile-ẹkọ ti oun wa bayii, jẹ ki oun tun wa ri pe ohun ti oun n ṣe tọ, yoo si dara ki oun wa fi awọn ọna kan kun un, ki ilọsiwaju le de ba ni pupọ.
Mo ri pe ẹni ti ko ba nimọ to pe, to ba ya yoo ki ika abamọ bọnu, lo jẹ ki n wa sile ẹkọ - Yeye Yetunde

Ni ti Yeye Yetunde Aina, o ni oun ri wipe nibi ti ere oritage n lọ nisinyii, o yẹ ki awọn ni imọ si ju bi awọn ṣe ni imọ si ti tẹlẹ lọ.
O ni iyẹn ni oun ṣe wa wo pe igba ti oun ba ri awọn ti wọn tun dagba ju oun lọ, ti wọn ba ṣi n lọ si ile-ẹkọ, ki wa lo de ti oun naa ko ṣe ni lọ si ile-ẹkọ yẹn, ki iṣẹ oritage oun ba le lọ siwaju.
O ni “Pupọ ninu awọn aṣiṣe miran wa ti a ma n ṣe amọ ti a ko ka kun un aṣiṣe sugbon lẹhin ti a de ile-ẹkọ yii, a ri pe aṣiṣe ni.
Emi n ri pe ni ọjọ iwaju, to ba to asiko kan, ẹni ti o ba ni imọ to pe, osuwọn to kun un daadaa ninu ẹkọ ere oritage yii, lo ṣeṣe ki o ki ika abamọ bọ enu.”
Bakan naa ni BBC Yoruba tun bawọn olukọ wọn sọrọ, ti wọn si salaye fun wa bawọn gbajumọ osere naa se n se ni kilaasi.
Bakan naa ni wọn sọ ọna ti wọn n gba kọ wọn ati ayipada to ti bawọn osere tiata naa.
Lọwọ lọwọ bayii, awọn osere yii ti kẹkọ jade ni fasiti Crescent, ti wọn si ti gba iwe ẹri moyege.






