Fídíò Tiktok kò èèyàn méjì sí gbaga Ọlọ́pàá torí wọ́n tàbùkù gómìnà Ganduje

Oríṣun àwòrán, Tiktok
Eeyan meji ti orúkọ wọn n jẹ Mubarak Muhammad ati Nazifi Bala ti fori ko ẹjọ́ niwaju ile ẹjọ́ Majisireeti Kano fun ẹsun pe wọn sọ ọrọ ibanilorukọjẹ nipa gomina Ìpínlẹ̀ Kano, Ọmọwe Abdullahi Ganduje.
Gẹgẹ bi ọrọ ti a kọ́kọ́ gbọ, nínú fidio kan to wa loju opo Facebook ni awọn mejeji ti sọ pe kii rì ilẹ̀ sójú afi ko taa wọn si tun ni o maa n sun gan.
Awọn mejeji yii lo maa n ṣe ẹfẹ ranpẹ ti oloyinbo n pe ni "comedy skit" ninu eyi ti wọn ti maa n sin ohun awọn eeyan pataki jẹ.
Àjọ to n ṣàyẹ̀wò fiimu ni Ìpínlẹ̀ Kano ti yẹ fidio naa wo ti wọn si pe awọn ọdọ mejeji ọhun lẹjọ́ nile ẹjọ́.
Ṣe wọn gba are tabi ẹbi nile ẹjọ?
Agbẹjọ́ro to gbe ẹjọ́ ọhun lọ sile ẹjọ́, Wada Ahmed Wada sọ fun BBC pe tori ẹsun biba gomina Ìpínlẹ̀ Kano lórúkọ ni wọn ṣe wọ wọn wa sile ẹjọ́.
O ṣàlàyé pe awọn ọdọ mejeji naa ṣe bii olùkọ́ni ati sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ ti wọn si ṣe bii pe wọn ń ka ìwé, wọn bẹ̀rẹ̀ si ni sọ̀rọ̀ ibanilorukọ si gomina Ganduje ti wọn si ṣàpèjúwe rẹ bíi obayejẹ olóṣèlú ti ko lè rí ilẹ̀ soju ko ma taa.
Ẹwẹ, Agbẹjọ́ro fun awọn afurasi, Anas Idris Baba sọ fun BBC lẹyin ti wọn tẹle gbogbo ilana ile ẹjọ́ tan pe awọn mejeji ọhun gbà pé àwọn jẹbi ẹsun náà, wọ́n sì jẹwọ ẹṣẹ wọn. Eyi kii ṣe igba àkọ́kọ́ ti wọn yoo fi èèyàn jofin nílé ẹjọ́ lori ẹ̀sùn pe wọn ba orúkọ gomina Ìpínlẹ̀ Kano, Abdullah Ganduje lórúkọ jẹ. Ile ẹjọ́ ti wa paa láṣẹ pe ki ki awọn mejeji wa ni àtìmọ́lé titi di ọjọ Aje ọjọ Keje Oṣù Kọkànlá ọdun 2022 lati da ẹjọ́ wọn.











