Ọ̀pọ̀ àṣeyọrí Funke Akindele ló ń já Tinubu láyà tó fi ń sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí nípa rẹ̀ – Jandor

Bola Tinubu ati Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Collage

Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Eko fẹgbẹ oṣelu PDP, Ọlajide Adeniran, ti ọpọ mọ si Jandor, ti sọ oko ọrọ ranṣẹ si gbogbo awọn to n sọ ọrọ alufansa nipa Funkẹ Akindele, ti ọpọ mọ si Jẹnifa, ẹni to n dije pẹlu rẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Jandor sọrọ yii lẹyin wakati mẹrinlelogun ti fidio kan gbode lori ayelujara.

Ninu fidio naa ni oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ APC, Bọla Tinubu, ti ni ki ẹnikẹni maṣe darukọ Funkẹ Akindele niwaju oun nitori abuku nla lo jẹ.

Aworan atẹjade Jandor loju opo rẹ

Oríṣun àwòrán, screenshot

Jandọr sọ loju opo witter rẹ pe, gbogbo awọn to n tabuku igbakeji oun, kan n binu awọn aṣeyọri gọbọi to ti ṣe ni.

O ni, “Oniruuru ibeere lo ti jade fun mi lawọn ifọrọwerọ gbogbo ti mo ti ṣe ni redio, telifiṣan atawọn ileesẹ igbohunsafẹfẹ miran.

Nibẹ si ni mo ti yanana idi ti mo fi yan Funkẹ Akindele gẹgẹ bi oludije fun ipo igbakeji gomina ipinlẹ Eko pẹlu mi."

Aworan atẹjade Jandor loju opo rẹ

Oríṣun àwòrán, screenshot

Oniṣowo to da muṣe ni Funke, o kopa gidi ọrọ̀ aje Eko nibi tawọn to n bu ti ri ọrọ̀ wọn ko jọ laijẹ pe wọn ni okoowo kankan - Jandor

Jandor tẹsiwaju pe "Pẹlu gbogbo alaye mi pẹlu wọn, awọn eeyan ṣi n gbiyanju lati ta ẹrẹ si orukọ Funkẹ Akindele lara.

Ọna lati lee tabuku ikunojuiwọn rẹ lati dari si ni eyi jẹ; ti wọn si n lo awọn ohun amuyamgan to mu u de ibi giga to de yii, lati fi ta ko o.”

Ọgbẹni Adeniran ni onyẹ kan ko le yẹ Funkẹ Akindele gẹgẹbi igbakeji oun nitori pe “ọkan lara awọn ọmọ Eko to ṣiṣẹ laluyọ ni.

Bakan naa, oniṣowo ti muṣemuṣe rẹ gba muṣe, ti o si ti ko ipa to jọju ninu ọrọ aje ipinlẹ Eko.

Ni Eko yii si ni awọn to n bu ẹnu atẹ lu u ti n ri ọrọ̀ wọn ko jọ, lai si ipa pe wọn ni okoowo ara wọn kankan, ki wọn to de ipo iṣejọba.”

Aworan atẹjade Jandor loju opo rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Dídá orúkọ Funke Akindele níbí tí mó wá, àrífín àti ìwọ̀sí ńlá ni - Tinubu

Bola Tinubu ati Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Collage

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti sọ fun awọn alatilẹyin rẹ pe dida orúkọ igbakeji oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Funke Akindele, ní iwaju oun jẹ ohun arifin nla ati ìwọsi.

Tinubu sọ eleyi lọjọbọ nigba ti awọn alatilẹyin rẹ mu orin bọ ẹnu lati bu Funke Akindele nibi ìpolongo ibo to waye fun Gomina Babajide Sanwo-Olu.

Tinubu, ẹni to n ṣe atilẹyin fun Gomina ọhun fún ṣaa kejì sapejuwe orin naa ati dída orúkọ naa gẹgẹ bii arifin nla si oun.

Ninu fidio ti Tinubu ti sọrọ naa sita, eyi to n ja ran-in lori ayelujara bayii, ni oludije sipo aarẹ fẹgbẹ APC nilẹ wa, ti se apejuwe Funke Akindele bii eera lasan.

"Ta ni Funke Akindele ni iwaju Sanwo-Olu ni Ipinlẹ Eko? Eera lasan ni.

Ẹ ma tiẹ se bii ẹni pe ẹ ranti orikọ yẹn, iwa abuku gba a ni, koda, arifin nla ni.

Adiẹ to fẹ wọle, to n bẹrẹ, bawo lo se ga si gan?"

Awọn ọrọ ti Tinubu sọ nipa Funke Akindele yii lo ti wa n fa awuyewuye lori ayelujara.

Àkọlé fídíò,  Ta ló gé ẹran ara ìya wa lọ nílé ìwòsàn lẹ́yìn ọjọ́ kan tó kú?

Ta ni Funke Akindele, to mu ki Bola Tinubu yari lati gbọ orukọ rẹ?

Gbajumọ osere tiata, onkọtan, olootu sinima ati agbẹjọro ni Funke Akindele.

Odu si ni lagbo tiata ati ni orilẹede Naijiria lapapọ.

O ti gbe orisirisi sinima sita eyi to mu ko gbajumọ bi isana ẹlẹẹta.

Lara awọn sinima ọhun ni Jenifa, ọmọ bibi ilu Ikorodu nipinlẹ Eko si nii se.

Ta ba wo ti ọjọ ori, ọmọ bibi inu Bola Tinubu lo jẹ, ti wọn kii si se irọ̀ rara.

Laipẹ yii Funke Akindele jade sita pe oun fẹ dije sipo igbakeji gomina nipinlẹ Eko.

O ni oun fẹ dije bii igbakeji oludije gomina fẹgbẹ oselu PDP, Abdulazeez Olajide Adediran, ti inagijẹ rẹ n jẹ Jandor.

Awọn mejeeji yii si ni wọn jẹ alatako gboogi fun gomina to wa lori oye lọwọ nipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu.

Oludije fun ẹgbẹ oselu APC ni Sanwo-Olu, to si n beere fun saa keji nipo gomina, ti oun ati Bola Tinubu si dijọ jẹ ọm ẹgbẹ oselu kan naa.

Ìdí tí a kò ṣe fi Tinubu jófin rèé lórí ẹ̀sùn yíyí sabuké - Ọ̀gá Ọlọ́pàá

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Tinubu kii ṣe afurasi lọdọ iléeṣẹ́ Ọlọpaa Naijiria.”

Ọga agba awọn Ọlọpaa, Usman Alkali Baba ti sọ fun ile ẹjọ́ giga ilu Abuja pe wipe oludije si ipo Ààrẹ ni ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Bola Ahmed Tinubu ko ni iwe ẹjọ́ tabi ẹ̀sùn kankan pẹlu Ileeṣẹ ọlọpaa kankan jakejado Naijiria.

Ọga agba Ọlọpaa naa tun ṣi aṣọ loju rẹ pe Tinubu kii ṣe afurasi lọdọ iléeṣẹ́ Ọlọpaa Naijiria.

“Ìdí ti Ileeṣẹ ọlọpaa ko si ṣe gba tẹle Tinubu lati fi ofin mu u wa gedegbe ninu iwe ẹda iwe ẹri to n jẹ “affidavit” eyi ti to wa ni àkọsílẹ̀ ni ile ẹjọ́ giga ni Abuja eyi ti agbejoro Wisdom Madaki gbé ka iwaju ile ẹjọ́ naa.

Ta lo n fẹ ki Ọlọpaa gbe Tinubu?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eyi jẹ esi si ẹ̀sùn ti ẹgbẹ́ kan, pe Tinubu pe ki Ọga agba Ọlọpaa fi ofin gbé Tinubu ki wọn si fi jofin lori yíyí iwe ẹri, Ọga Ọlọpaa ni awọn ko lee fi Tinubu jofin lai ri ẹṣẹ to ṣẹ.

Ẹwẹ, Ọga Ọlọpaa gba pe lóòótọ́ ni òun gba iwe ẹ̀sùn meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lati ọwọ ẹgbẹ́ kan lori ẹ̀sùn yii.

Alkali tesiwaju pe ẹ̀sùn naa ti di ọrọ ti ile ẹjọ́ giga julọ ti gbọ́ lati ọdun 2002 nigba ti oloogbe ajijagbara Gani Fawehinmi pe ẹjọ́ naa.

Ẹda ìwé ẹri “affidavit” naa si fihan pe niwọn igba ti ileẹjọ́ giga julọ ti yanjú ọrọ náà, ko si idi kankan fun Ọlọpaa lati tun ṣi ọrọ naa loju.

Yàtọ̀ fun ìyẹn, Ọga Ọlọpaa ni awọn ko nílò àṣẹ ilé ẹjọ́ kankan lati fi panpẹ ofin mu èèyàn tori ninu iwe ofin ni agbara awọn wa.

Alkali wa ke si ile ẹjọ́ lati fagile ẹjọ́ ti wọn gbe wa siwaju wọn lori èyí tí wọn tún ti lọ mọ Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni ẹsẹ.

Ẹwẹ, adajọ Inyang Edem Ekwo sọ esi Ọlọpaa ṣẹ de iwaju òun ni to si ni oun yoo boju woo.

Wọn ti da ọjọ́ Kọkàndínlógún Oṣù Kínní ọdún 2023 lati gbọ́ ẹjọ́ náà.

Ẹgbẹ́ Incorporated Trustees of Centre for Reform and Public Advocacy lo wọ ọga Ọlọpaa lọ sile ẹjọ́ lori ẹ̀sùn pe o kọ lati fi ofin gbe oludije ipo Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.