Agbébọn ṣe ọṣẹ́ ní fáṣítì Ibadan, òṣìṣẹ́ àjọ NECO pàdánù ẹ̀mi rẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn agbebon kan ṣe ikọlu si ilegbe awọn osisẹ ni fasilti Ibadan, ti wọn si ṣekupa oṣisẹ ajọ NECO kan, to orukọ rẹ n jẹ Vincent Odinko.
Odinko ni iroyin sọ pe o jẹ ayalegbe ni ile gbe awọn osisẹ naa, nitori iyawo rẹ jẹ osisẹ fasiti naa.
Bakan naa ni awọn agbebọn yii tun ko ọpọlọpọ dukia rẹ lọ.
Oun pẹlu mọlẹbi rẹ lo gbe ni fasiti naa ki awọn agbebọn to ṣe ikọlu naa si.
Iyawo ologbe to jẹ osisẹ fasiti Ibadan ni ọkọ oun taji nigba ti awọn agbebọn ọhun ya wọle wọn nitori o sisẹ lọwọ ori ẹrọ kọputa rẹ lasiko naa.
Oni wọn sina ibọn bolẹ fun ọkọ oun lẹyin ti wọn ji awọn dukia rẹ.
Iwadii ti n lọ lọwọ lori isẹlẹ naa - Ọlọpaa Oyo
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ti kede pe awọn ti bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso lo fi ọwọ gbaya bẹẹ fun awọn akọroyin.
O ni ileesẹ ọlọpaa yoo se ẹkunrẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ naa lati ri pe awọn fi imu awọn agbebọn jofin lori ẹsun iṣekupani naa
Osifeso rọ awọn olugbe ipinlẹ Oyo lati maṣe foya tabi bẹru nitori awọn yoo tu isu de isalẹ koko lori iṣẹlẹ naa.
“Iwadi ti n lọ lọwọ bayi, ti a si ma fi to yin leti bi o ṣe lọ.”
Òkú ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá tí wọ́n dédé rí nínú igbó ní ọ̀ná márosẹ̀ Ibilo-Lampese di ọ̀rọ̀ Ọ́lọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo ni oun ti bẹrẹ iwadii lori oku eeyan mẹwaa ti wọn ri ninu igbo kan loju ọna Ibilo si Lampese.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, SP Chidi Nwabuzor sọ ninu atẹjade kan pe awọn ṣawari awọn oku naa lẹyin ti awọn eeyan kan ta ileeṣẹ ọlọpaa, fijilante atawọn ọdẹ lolobo.
Gẹgẹ bii ohun ti Nwabuzor sọ, nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ kinni, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii lawọn ṣadede ṣawari awọn oku naa.
O ni ọga ọlọpaa Ibilo sọ pe inu ọọfisi loun wa ti awọn eeyan fi to oun leti pe awọn ri awọn okun naa, lẹsẹkẹsẹ lo si ko awọn oṣiṣẹ rẹ, to fi mọ awọn ọlọde atawọn fijlante lọ sibẹ.
O ni “Nigba ti wọn de ibẹ, wọn ba oku ọkunrin mẹwaa ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun ọdun mẹtalelogun si ọdun marundinlọgbọn lọ.”
“Ninu iwadii wa, a ya aworan awọn oku naa, a si yẹ ara wọn wo amọ a ko ri apa kankan tabi ohun idanimọ ti a le fi mọ irufẹ ẹni ti wọn jẹ.”
“Bakan naa ni a gbe iwadii wa de ọdọ awọn Hausa ati Fulani to n gbe lagbegbe naa lati wa yẹ awọn oku naa wo, wọn si sọ pe awọn oku ọhun ki ṣe awọn eeyan awọn.”
Nwabuzor sọ pe wọn ti ko awọn oku ọhun lọ sile igbokupamọsi bayii.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ekdo, Mohammed Dankwara ti wa ke si awọn araalu lati fun awọn ni iroyin to le ṣamọna ohun to ṣekupa awọn ọdọkunrin naa.
Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ọhun lati maa ba iṣe wọn lọ lai foya nipa abo ẹmi wọn.














