Tope Oladiji ní Ondo ti dèrò ilẹ̀ẹjọ lẹ́yìn tó ń dúnkookò láti ṣekúpa Bàbà rẹ pẹ̀lú àdá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Arakunrin kan, Tope Oladiji ni o ti dero ileẹjọ giga nipinlẹ Ondo fun ẹsun pe o dunkoko lati ṣekupa baba to bilọmọ, Kolawole Oladiji pẹlu ada

Oladiji, ẹni ọdun mọkandinlogoji, to tun jẹ ọlọkada, ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ni agbegbe Holy Trinity Italuwo Italuowo niluu Ondo, ti wọn si wọ lọ ileẹjọ lati wi tẹnu rẹ.

Olujẹjọ ọhun ni ileeṣẹ ọlọpaa ni o gbe igbesẹ naa lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2022. Eyi to lo di ofin orilẹede Naijiria ati ofin ipinlẹ Ondo lati ma ṣe dunkoko pe oun yoo ṣekupa eeyan.

Olujẹjọ ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn kan oun rara, ati wọn kuna lati lo ilana ofin gbe oun wa si ileẹjọ .

Agbẹjọro olupẹjọ, Iyabo Omolara, sọ fun ileẹjọ pe oun ni ẹlẹri meji to ṣetan lati jẹri si ẹsun ti wọn fi kan Tope Oladiji.

Adajọ Toyin Olowookere ninu idajọ rẹ gba beeli olujẹjọ pẹlu owo toto ẹgbẹrun lọna adọta naira.

O wa sun igbẹjọ si ọjọ kẹjọ oṣu kejila ọdun 2022.

Bàbá lú ọmọbìnrin rẹ̀ pa tórí ó fà kóró nǹkan ọkùnrin rẹ̀ lásìkò ìjà

Aworan

Oríṣun àwòrán, NPF

Ọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ti tẹ awọn afurasi asekupani mẹta ti wọn ṣe ikọlu ni agbegbe naa.

Lara awọn afurasi naa ni, Baba kan, ẹni ọdun mẹrindiladọrin to ṣekupa ọmọbìnrin rẹ, Ofonmbuk Ime Sunday

Ọjọbọ ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Akwa Ibom ṣe afihan awọn afurasi naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ahamọ ni awọn afurasi naa si wa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ naa, Odinko Macdon ni iṣẹlẹ naa waye ni ojo kẹsan an oṣu kẹwaa ọdun 2022, ti wọn si bẹrẹ iwadi kete ti wọn gba iroyin naa.

Baba to lu ọmọ rẹ pa tun lọ sin loku oru amọ asiri tu - Ọlọ́pàá

Ọlọpaa ni kete to gba ẹmi ọmọ rẹ ẹni ogun ọdun, lo lọ gbe sìn ní bí ira kan nnu agbala rẹ ni Omum Unyiam, ní ìjọba ibilẹ Etim Ekpo.

Gẹgẹ bii agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, ọmọbìnrin oloogbe naa fa baba rẹ lẹpon nigba ti ija bẹ silẹ laarin wọn.

"Mọlẹbi yii ni ede ayede eyi to sokunfa ìdí ija wọn, tí oloogbe si fa baba rẹ labẹ.

"Eyi lo mu kí Baba rẹ fọ igi mọ lori, to si gba ibẹ kú.

"Baba, ninu igbiyanju rẹ láti bo asiri, gbe oku naa lọ sìn."

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti hu oku naa jade, tí wọn yoo si gbe lọ sìn ní agbala ile wọn.

Bakan an ni ọwọ tẹ ọkunrin miiran to ṣekupa ẹnikan ni agbegbe Afaha Ediene ni ìjọba ibilẹ ikono.

Ninu iṣẹlẹ miiran, ọwọ tẹ ẹnikan lori iṣẹlẹ kan tó waye ile ẹkọ gbogbonise kan, to si mú ẹmi eeyan kan lọ.