Pásítọ̀ Davido àti Chioma sọ̀rọ̀ síta lórí ipò tí tọkọ-taya wà
Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí àyẹ̀wò CCTV ní ilé Davido

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Pasitọ Tobi Adegboyega to jẹ orẹ timọtimọ Davido ti sọrọ lori ipo ti Davido ati Chioma wa lori iku ọmọ wọn Ifeanyi Adeleke.
Pasitọ Tobi loju opo Instagram rẹ ni eemeji ọtọọtọ ni oun ti ba Davido ati Chioma sọrọ lori foonu lati mọ nipa alaafia wọn.
O ni alaafia ni wọn wa , ti ara wọn si n mokun si ju ti atẹyinwa lọ.
‘’Mo ba No.1 OBO sọrọ fun igba keji. Ara rẹ n mokun si. Ko rẹwẹsi mọ bi ti atẹyinwa, ara awọn mejeeji n mokun si. Adupẹ lọwọ Ọlọrun.
Bakan naa lo fi ọrọ itunu ranṣẹ si wọn pe wọn yoo dide pẹlu idalare, ti wọn yoo si di ẹni to n fun awọn eniyan ni ireti ati okun laipẹ.

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí àyẹ̀wò CCTV ní ilé Davido
Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kede pe gbogbo igbiyanju n lọ lọwọ lati ṣewadii ohun to fa iku ọmọdekunrin olorin Davido, Ifeanyi Adeleke.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo sọ bẹẹ fun awọn akọroyin lasiko ti wọn n sọrọ nipa ibi ti ọrọ de duro lori iku ọmọde naa.
Ni Ọjọ Aje ni iroyin gbalẹ kan pe Ifeanyichukwu tii se ọmọkunrin kan soso ti gbajumọ akọrin takansufe, Davido bi ti jade laye amọ ti ọpọ eniyan ko gbagbọ.
Aarọ ọjọ keji ni agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin pe lootọ ni Ifeanyi ti jade laye.
O ni ọmọ naa lo ko sinu omi ti wọn fi n luwẹ to wa ni ile Davido lasiko ti baba ati iya rẹ ko fi si ninu ile.
A o ṣe agbeyẹwọ CCTV ti a ri ninu ile Davido - Ọlọpaa Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter
Bakan naa lo ni o seese ki wọn se ayẹwo oku ọmọ naa lati tubọ mọ ọna to ba lọ si ọrun aibaamọ ejo le lọwọ ninu.
Lori ẹrọ CCTV ninu ile Davido, Hundeyin ni awọn yoo sagbeyẹwọ rẹ ki iwadii le tẹsiwaju lori bi ọmọ naa ṣe kosi inu omi adaju ninu ile naa.
Bakan naa lo ni fidio to n ja ranyin nita kii ṣe ti CCTV inu ile Davido nitori awọn ko i tii sayẹwo rẹ nigba ti fidio ofege kan gba ori ẹrọ ayelujara kaakiri.
‘’A ko i tii wo fidio CCTV ti a gbe kuro ninu ile Davido, fidio kankan ti ẹ ḅẹ ri ni ori ẹrọ ayelujara, ofege ni.’’
Saaju ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye ni kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun tẹlẹri, Edward Ajogun ti fi ero rẹ lede pe ṣiṣe ayẹwo ẹrọ CCTV ninu ile naa ni yoo tan imọle si bi iṣẹlẹ iku ọmọ naa ṣe waye.
















