EFCC ká ọ̀pọ̀ báàgì owó Dọ́là àti Náírà mọ́ olùdíje ile aṣòfin lọ́wọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, EFCC

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria EFCC ti tẹ oludije sipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi, labẹ asia ẹgbẹ oselu New Nigeria Peoples Party, NNPP, ti wọn si ti gbe lọ ileẹjọ.

Ọwọ tẹ arakunrin ọhun, Ismaila Yusuf Atemeyi pẹlu owo toto milọnu lọna ọgọrun un mẹta owo naira ati ẹgbẹrun un lọna ogoje dọla owo ilẹ okere.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Wilson Uwujaren ni ọwọ tẹ arakunrin naa to fẹ soju ijọba ibilẹ Ankpa ni ile aṣofin Kogi ni ọgbọnjọ oṣu kẹwaa.

Bakan an ni ọwọ tẹ Joshua Dominic, afurasi oni gbajuẹ ni agbegbe Macedonia to wa ni Gwarinpa niluu Abuja.

"Ọwọ wa tun tẹ osisẹ banki to jẹ agbodegba fawọn ole to n fọ banki"

Uwujaren tẹsiwaju pe ọwọ ajọ naa tun tẹ Abdumalik Salau Femi, ẹni to jẹ osisẹ banki tẹlẹ ri.

Ẹsun ti wọn fi kan ni pe oun lo fun awọn janduku ni iroyin nípa bii wọn yoo ṣe ṣe ikọlu si ile ifowopamọ.

Gẹgẹ bii Uwujaren ṣe sọ, o ni ile ìtura Radisson niluu Eko ni owo ti tẹ arakunrin naa.

O ni kete ti owo tẹ, ni awọn morile ile gbe rẹ, ti awọn si salabapade owo toto ẹgbẹrun lọna ọgọrun un mẹrin dọla nibẹ.

Ọkàn lára àwọn afurasí náà wá lára àwọn tó ṣé ìkọlù sì ilé ifowopamo, jí owo tó jù bilọnu kán lọ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, EFCC

Wilson Uwujaren salaye pe bi ọwọ ṣe tẹ àwọn afurasi yii ko sẹyin iwadi olosu gbọrọọ ti awọn ṣe lẹyin ti awọn janduku ṣe ikọlu ayelujara si awọn ile fowopamọ kan.

O ni ọpọ igba ni ọwọ tí tẹ Dominic for ẹsun jibiti ati pe oun gan lo ṣe iranlọwọ fun Atumeyi ati Abdumalik.

"Ọpọ igba ni ọwọ awọn ileeṣẹ ọlọpaa tí tẹ Dominic, ẹni to ni oun jẹ oludari Brisk Capital Limited fun ẹsun jibiti owo toto bilọnu meji naira lọdun 2021.

"O le ni ọgọrun un marun-un eniyan ti Dominic tí lu ni jìbìtì latara ile isẹ rẹ."

Uwujaren ni gbogbo ọna ni ajọ EFCC gba láti dẹkun iwa ibajẹ àti jibiti lorilẹede Naijiria paapaa julo sì awọn ile ifowopamọ.