ASP ọlọ́pàá ọkùnrin lu akẹẹ́gbẹ́ rẹ̀ obìnrin torí ó kọ̀ láti jẹ́ àlè rẹ̀ ní Osun

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi
Ọga Agba ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba, ti pàṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori ẹsun pe ọlọpaa ọkùnrin kan lu akẹẹgbẹ rẹ to jẹ obìnrin nitori ọrọ ifẹ nipinlẹ Osun. Agbẹnusọ ọlọpaa, Muyiwa Adejobi lo fi ikede naa sita ni ọsan Ọjọru. Saaju ni fidio kan jade si ori ayelujara, ninu eyi ti arábìnrin naa, Bamidele Olorunsogo, ti fẹsun kan Ajayi Matthew, olori ẹka ìwádìí ẹ̀sùn ọdaran ni agọ ọlọpaa to wa n'ilu Ode-Omu, nijọba ibilẹ Ayedaade nipinlẹ Osun, pe o pa oun lára nitori pe oun kọ̀ lati jẹ ọrẹbinrin rẹ. Arabinrin Bamidele sọ pe ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kinni, oṣu Kọkanla, ni iṣẹlẹ naa waye loju àwọn kọnsitebu ọlọpaa meji, ati araalu mewaa. Arábìnrin naa sọ pe ọga òun, Ajayi, ba oun sọ ọrọ ifẹ, sugbọn oun kọ̀, nitori pe iyawo ile ni oun.
Ki lo ṣẹlẹ ninu fidio to gba ori ayelujara kan?
Ninu fidio naa lo ti n sọ pe: "Kini ẹsẹ mi? O deede n lù mi, o ja mi si ihoho, o pami lara ni àyà ati ọwọ. " Ajayi Matthew sọ pe ki n fẹ́ oun, mo si ni mi o ṣe nitori pe mo ti ṣe igbeyawo. Lẹyin naa lo bẹ̀rẹ̀ si ni parọ mọ mi kaakiri." Bamidele ni DCO Ajayi n sọ fun àwọn eeyan pe àwọn n fẹ́ ara awọn. O ni eyi lo bi oun ninu ti ede aiyede fi bẹ̀rẹ̀, deebi pe o lu oun. O tun fi ẹ̀sùn kàn pe Ajayi gbiyanju lati yinbọn mọ oun nitori ọrọ naa.
Ninu ikede to fi sita ni Ọjọru, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola sọ pe kọmisanna ọlọpaa ti ba awọn ọlọpaa mejeeji sọ̀rọ̀. "A ti ri fidio obinrin ọlọpaa, Isipẹtọ Bamidele Olorunsogo, ti ọga rẹ, ASP Matthew Ajayi lu, kọmisanna ọlọpaa si ti fi ọ̀rọ̀ wa awọn mejeeji lẹnu wo. " O si tun pasẹ pe ki iwadii abẹnu bẹrẹ lori iwa itiju to tako ofin isẹ ọlọpaa, naa. "
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post








