Canada ṣíde ètò láti fààyè gba ọmọ Nàìjíríà 1.45 Mílíọ̀nù, àtàwọn míì lọ́dún 2025

Canada

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìjọba Canada ti kede eto rẹ lati ṣi ọna fun eeyan to le ni mílíọ̀nù kan (1.45m) lati orílẹ̀èdè Naijiria àtàwọn orílẹ̀èdè míì lagbaye lati le wa orílẹ̀èdè wọn lọdun 2025. Gẹgẹ bo ṣe wa ni àkọsílẹ̀ àkànṣe eto irina ọdun 2023 si 2025 ni Canada eyi to jade lọjọ Isegun, ẹkùn Ariwa (North America) si gba eyi tọwọ tẹsẹ lati lè ran awọn olokoowo lọwọ lati ri oṣiṣẹ.

Minisita orílẹ̀èdè Canada lori eto irina, ọrọ atipo àti didi ọmọ onilẹ, Sean Fraser sọ pe ilana yii yoo fa ojú awọn to ni iṣẹ́ ọwọ mọra láwọn ẹ̀ka bii ìlera, ipese ati imọ ẹ̀rọ. "Lọdun to kọja, ìjọba Canada gba ajoji to le ni 405,000 wọle, eleyii lo pọ ju ti a ti gba ri laarin ọdun kan. Ìjọba n tesiwaju ninu eleyii nigba ṣíṣe eto sísọ eeyan 465,000 di ọmọ onilu lọdun 2023, 485,000 lọdun 2024 ati 500,000 ni ọdun 2025.

Ki ni anfani eto naa fun awọn ara Canada?

Bákan naa, eto ọhun yoo fi kun afojusun fifa oju awọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé mọra si oniruuru ẹkùn orileede naa to fi mọ awọn ilu kekeke ati ìgbèríko", lára atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Àkànṣe eto irina ti ọdun yii yoo ran awọn oníṣòwò lọwọ lati le ri awọn oṣiṣẹ ti wọn nilo, yoo si mu Canada bọ sipo ti yoo da kun àṣeyọrí ọlọjọ pipẹ ati ti yoo mu wa bojuto awọn eeyan ki wọn ma f'ara gbá iṣẹlẹ wàhálà, ogun àti inúnibíni," Fraser sọ bẹẹ.

Bákan naa ni oludari ẹgbẹ́ awọn oníṣòwò ilé kíkọ ni Canada náà, Sean Strickland ni ẹgbẹ́ awọn fọwọ́ sii "inú wa si dun si ìkéde tonii.

Nínú itan, nipasẹ irinna la fi ri anfani ati mu ojukoo isẹ wa gbooro sii, awọn ẹgbẹ́ wa n kun a sì n kọ ohun amayedẹrun si Canada.

O fi kun un pe agbega to n ba ìwọlé-wọde ṣe pataki fun isẹ ṣíṣe jakejado orileede naa awọn si n reti síi lati ṣiṣẹ́ pọ pẹlu Minisita Fraser ati ìjọba àpapọ̀ lati wa ọna àbáyọ tí a fẹ́ fún ìtẹ́síwájú.

Canada jẹ ọkan lara awọn ilu ti ọpọlọpọ ọdọ Naijiria n mori le lati igba ti iwọde ifẹhonuhan #EndSars ti waye lọdun 2020 ti wọn si n lọ torí ìṣòro eto ẹ̀kọ́ ati àìríṣẹ́ paapaa ariwo "mo fẹ́ jápa" lo gba orílẹ̀èdè Naijiria kan bayi ti awọn ọdọ ko si mu u ni kekere.