Ẹ fí àwòrán Obasanjo sí owó pépà tí ẹ fẹ́̀ ṣe àtúnṣe sí- Atiku Abubakar

aworan

Oríṣun àwòrán, Screengrab

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti gba ijọba apapọ Naijiria niyanju lati fi aworan aarẹ tẹlẹri Oloye Olusegun Obasanjo si owo pepa ti wọn fẹ ṣe atunṣe si.

Atiku kede ọrọ ọhun lori opo ayelujara 'twitter' rẹ lọjọ Abameta.

O kan saara si Aarẹ tẹlẹ, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọrun un fun akitiyan rẹ ati bi o ṣe kopa ninu eto alaafia lorilẹede Ethiopia

Atiku tẹsiwaju pe orilẹede Naijiria ni lati da Obasanjo lọla fun isẹ takuntakun to n ṣe nilẹ Adulawọ

Paapaa bi o ṣe le waju awọn igbimọ to lọ pẹtu si rogbodiyan ọlọdun meji to waye laarin ijọba Ethiopia ati ẹya Tigrayan, eyi to ti gbẹmii ọpọlọpọ awọn eeyan, to si ti sọ ọpọ di ẹni ti ko ni ile lori mọ.

Ijọba olootu agba fun orilẹede Ethiopia, Abiy Ahmed ati ẹẹya Tigray tọwọ bọ iwe adehun alaafia lati fopin si ija ọhun, ki oni kaluku si ma gbe ni igbe alaafia.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Nigba ti Atiku n sọrọ, o ni aseyori Obasanjo ko jẹ ohun tuntun fun oun rara nitori eyi ki ṣe igba akọkọ ti yoo lewaju awọn igbimọ lati fi opin si rogbodiyan to wa nilẹ Adulawọ.

O ni pe: “Ko ya mi lẹnu rara, nitori mo mọ ọga mi. O ṣe bẹ ni Liberia ati Sao Tome and Pricples nigba ti a jọ wa ni iṣejọba orilẹede Naijiria.

“Ti ko ba ki n ṣe fun nnkan miiran, o yẹ ki wọn fi ami ẹyẹ ‘Noble Prize’ da lọla, koda mo ma dibo pe ki wọn fun Obasanjo ti a ye ba ti si silẹ fun.

"Ile adulawọ ni Ọlọrun fi awọn eeyan jakanjakan ta lọrẹ, arawọn ni Oloye Olusegun Obasanjo. Ẹni ti o yẹ ki aworan rẹ wa lara owo pepaa ti wọn fẹ atunṣe si lorilẹede Naijiria."

Atiku ni fifi aworan Obasanjo si owo pepaa ni yoo ṣe ọpọlọpọ iwuri fun awọn ọdọ to n bọ lẹyin lati wo awu kọse aarẹ tẹlẹ naa fi lo igbesi aye wọn.

“Ọkunrin ti a sọrọ rẹ yii ni o yẹ ki aworan rẹ wa lara owo pepaa wa lati fi ṣe ohun iwuri fun awọn ọjọ ọla orilẹede Naijiria.”