Ooni tí Ile-Ife fún àwọn ránṣọ-ránṣọ 300 ní ìrànwọ́ ní Ile-Ife

Oríṣun àwòrán, Ooni Ogunwusi
Ọọni ti Ile-Ife, Ọọni Adeyeye Enitan Ogunwusi Ojaja II ti fun awọn obinrin to le ni ọọdunrun ni ohun elo irinṣẹ ni Ile Ifẹ ati ayika.
Eyi pẹluu igbeṣẹ rẹ onigun mọkanla lati ran awọn eniyan ti ko ri aje jẹun lọwọ.
Lasiko ti Ọọni sọrọ nibi ayẹyẹ aṣekagba awọn to kẹkọ imọ aṣọ riran jade ni Ojaja Fashion Training Institute ni Ọba naa fi idunnu rẹ han.
Ogunwusi ki Olori Temitope Ogunwusi ku oriirẹ lori iṣẹ takun-takun to n ṣe ni ileeṣẹ rẹ ti kii ṣẹ ti ijọba, Hopes Alive Initiative (HAI), ki o to di olori.
O ti pe ti emi ati Ayaba Temitope Ogunwusi ti n ba a bọ - Ọọni Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Ooni Ogunwusi
O ti pe ti emi ati Olori Temitope ti n ba irinajo wa bọ, ohun kan pato ti mo le sọ nipa rẹ nipe o jẹ eniyan to lawọ to si ma n ‘se aanu awọn alaini lai wo ẹyin.
Idi niyẹn to fi gbe iru iranwọ yii kalẹ fun awọn eniyan lai fi ti ara rẹ ṣe.
Lasiko ti Ooni naa n ba awọn to jẹ anfaani yii sọrọ lo ti ni gba wọn nimọran lati tẹra mọ iṣẹ wọn ki wọn si fi ẹbun ọfẹ ti wọn ri gba naa jẹ eniyan pataki laye.
Bakan naa ni Ọọni gboriyin fun awọn obi to ṣe atilẹyin fun awọn ọmọ wọn lati kọ iṣẹ ọwọ ko le dara fun wọn ni ẹyinwa ọla.
Ohun ti Olorun ran mi wa si ile aye wa ṣe ni mo n ṣe lo fi mu mi di ayaba - Olori Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Ooni Ogunwusi
Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ, Olori Temitope Ogunwusi gboriyin fun ọkọ rẹ fun iṣẹ takun-takun gẹgẹ bi olori ni ilẹ Yoruba.
Olori Ogunwusi ni ohun ti Ooni fẹ ni ki gbogbo eniyan ṣe oriire laye, to si ma n gbiyanju lati ran awọn ọmọ alaini lọ si ileẹkọ tabi fun wọn ni iṣẹ ọwọ.
‘’Ti ẹnikẹni ba fẹ sọ ohunkohun nipa Ooni, ohun pato ti wọn yoo sọ ni ifẹ rẹ fun awọn araalu nitori o mọ pe ika ko dọgba.’’
Oun mu ileri aṣeda ṣe nigba fifun awọn eniyan ni anfaani lati jẹ eniyan laye.
Mo gbagbọ pe ohun ti Olorun ran mi wa si ile aye wa ṣe ni mo n ṣe lo fi mu mi di ayaba, ti Ooni si n ran mi lọwọ lati mu ileri ṣe.
Bakan naa lo rọ awọn eniyan to ni anfaani lati ran awọn eniyan lọwọ lati maṣe fa ọwọ ṣẹyin fun awọn eniyan, nitori oore ṣiṣe dara.















