Ìbọn bá Olóòtú ìjọba Pakistan tẹ́lẹ̀, Imran Kahn níbi ìfẹ̀hónúhàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olootu ijọba Pakistan tẹlẹ, Imran Kahn ti fara gbọta ibọn lasiko tifẹhonuhan kan niluu Wazirabad.
Khan fi ẹsẹ ṣeṣe lasiko ti ẹni kan dana ibọn ya, bẹẹ naa ni eeyan mẹrin miran farapa lasiko ikọlu naa.
Ijọba orilẹ-ede ọhun ko ti sọ nnkankan nipa ikọlu naa, amọ awọn eeyan kan sọ pe ikọlu naa jẹ igbiyanju lati pa Khan.
Eredi ifẹhonuhan naa ko ṣẹyin bi awọn araalu ṣe n pe fun eto dibibo ni kankan.
Ọgbẹni Khan, to jẹ ẹni aadọrin ọdun lo lewaju iwọde naa ti wọn n ṣe lọ siluu Islamabad, to jẹ olu ilu orilẹ-ede ọhun.
Ninu fidio kan to n milẹ titi lori ayelujara ni a ti ri olori ijọba tẹlẹ naa ti wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan.
Ẹnikan to gbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu rẹ sọ pe o ṣeeṣe ki ibọn naa ba ni ẹrẹkẹ.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn adari ẹgbẹ oṣelu rẹ, PTI, to tun jẹ minisitia eto ilera, Yasmeen Rashid sọ pe ara rẹ ti n balẹ nile iwosan to wa.
Ọlọpaa ti mu afurasi kan
Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa ti fi fidio kan lede, ninu eyii ti ọkunrin kan ti wọn mu lori ikọlu ọhun ti sọ pe oun loun gbiyanju lati ọkunrin naa.
A kọ le sọ boya wọn ti kọkọ fiya jẹ afurasi naa ko to sọrọ ninu fidio ọhun, amọ awọn ọlọpaa bere lọwọ rẹ eredi to ṣe yinbọn lu Khan, so si fesi pe Khan “n ṣi awọn eeyan lọna lo jẹ ki n gbinyanju lati pa. Mo fẹ pa.”
Fidio ifẹhonuhan naa ṣafihan bi ọgbẹni Khan atawọn ololufẹ rẹ ṣe n fẹhonuhan ki iro ibọn to dun, lẹyin naa ni Khan gbiyanju lati fori rẹ pamọ, ti awọn ololufẹ rẹ ọhun si ṣuru bo.
Fidio mii ṣafihan ibi ti wọn ti n gbe Khan kuro ni gbagede ifẹhonuhan naa lẹyin ti wọn yin nibọn tan.














