PDP Oyo àti Seyi Makinde fìjà pẹ́ẹ́ta torí àtakò tó ń ṣe fún Atiku

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Irọ́ ni, igbákejì Makinde kò ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu nílé Fasoranti -

Aworan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ipinlẹ Oyo ti kede atilẹyin rẹ fun oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu naa, Atiku Abubakar, ti wọn si tako ọrọ ẹnu gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde pe awọn ko lọwọ ninu rẹ.

Nigba ti ṣe ipade lana níluu ibadan, awọn agba ẹgbẹ oṣelu PDP ni Makinde sọrọ fun ara rẹ nìkan ni, ko ki n ṣe agbẹnusọ gbogbo ẹgbẹ.

Makinde kede lọsẹ to kọja lori redio pe oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP kan yoo sisẹ tako àṣeyọrí oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu naa fun idi kan tabi kejì.

Makinde ni oludije láti ariwa ko lẹtọ lati di aarẹ Orilẹede Naijiria lẹyin isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari. 

O tẹsiwaju pe ko lẹtọ ki oludije sipo aarẹ ati alaga ẹgbẹ oselu wa igun kana lorilẹede Naijiria, eyiu apa Ariwa orilẹeede Naijiria.

"Ti Makinde ba ni ka ma dibo fun Atiku, ta ni ka dibo fun?"

Nibi ipade pajawiri naa, alaga fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ipinlẹ Oyo, Elder Wole Oyelese ati agba ọjẹ ninu ẹgbẹ ọhun, Engr Femi Babalola sọrọ̀ ilẹ kun.

Wọn ni Makinde nikan lo mọ ohun to n sọ ati pe ko sọrọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ipinlẹ Oyo.

Oyelese ni awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ipinlẹ Oyo yoo sisẹ pupọ lati ri pe Atiku Abubakar bori eto ìdibo aarẹ lọdun 2023. Gẹgẹ bii Oyelese ṣe sọ, "oloselu gidi ko ni sọrọ ba yẹn.

Fun Makinde lati sọrọ pe oun ko ni sisẹ pẹlu Atiku, ko ni nkankan ṣe pẹlu wa.

Orí ọwọ rẹ lo wa, agba ofifo lasan ni. To ba ni ki a ma dibo fun Atiku Abubakar, ta ni kí a wa dibo fun.

"Makinde sẹsẹ de sinu oṣelu ni Ipinlẹ Oyo ni sugbọn awa ko ni sisẹ tako àṣeyọrí ẹgbẹ oselu PDP.

A wa ti bẹrẹ ìgbésẹ tí yoo mu Atiku Abubakar bori eto ìdibo aarẹ lọdun 2023 ni Ipinlẹ Oyo.

 “Ibo gan ni ilẹ Yoruba wa lori ọrọ ti Makinde sọ?

Yoruba ko si ni ibi kọọkan rara. Baba Adebanjo n sọ eleyi, Baba Fasoranti n wi miiran., nibo la wa n lọ?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Oyo insight

"Bi Makinde ba n binu pe ara ariwa tun dije sipo aarẹ, sebi Ibadan nikan lo n gba ipo gomina nipinlẹ Oyo"

Bakan naa, Femi Babalola ti ọpọ mọ si Jogor, ní Makinde gan jẹbi awọn ẹsun to fi kan oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ naa, Atiku Abubakar.

"Mo ti yannana ọrọ yii finifini, n jẹ ṣe ó da ki oludije lati apa ariwa gba isejọba lọwọ Buhari?

Ibeere kejì ni, n jẹ ṣe o da ki ọmọ ibadan gba isejọba lọwọ ọmọ ibadan miiran?

Lara nkan ti Makinde n jẹ anfani rẹ loni nìyẹn, ti ko ri pe ohun to burú ní, kí wa ni idi to fi tako Atiku Abubakar?

"Bakan naa, ṣe pin awọn ipo nla fun awọn to yẹ, pupọ lara awọn to awọn to janfaani ipo oselu lo wa lati ìjọba ibilẹ rẹ, Ibadan North East.

"Ọrọ ko tọ si Makinde lẹnu rara.

Àwa ko ni pada lẹyin oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu wa, a setan lati sisẹ pẹlu rẹ lati bori ninu eto ìdibo aarẹ lọdun 2023."

Aworan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

"Makinde ko fi òǹtẹ́ lú Tinubu rárá, yóò siṣẹ padà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láìpẹ́"

Oludije sipo sẹnẹto labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Hon Akinwale Solomon Akinwole ti sọpe Gomina Seyi Makinde ko fi igba kan fi ontẹ lu oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, eyiun Bola Ahmed Tinubu.

Wolekanle ni lara igbiyanju awọn ẹgbẹ oselu alatako lati yí ọkan awọn eeyan to tí pinnu pe awọn yoo dibo fun ẹgbẹ oselu PDP pada.

 "Mo ba gomina sọrọ, ko si figba kọọkan sọ fun wa pe oun fi ontẹ lu ẹnikẹni fun ipo aarẹ.

"Gomina Makinde ti sọ tipẹ fun awọn alátilẹyin ati awọn araalu pe ẹgbẹ oselu PDP jẹ oun logun pupọ, tí oun yoo sisẹ lati ri pe ẹgbẹ oselu PDP borí gbogbo eto ìdibo lorilẹede Naijiria."

O fikun pe Gomina yoo ṣe Ipade pẹlu awọn agba ẹgbẹ oṣelu PDP lati mọ bí ọrọ naa yoo ṣe ni iyanju.