Nọ́ọ́si méjì áti òṣìṣẹ́ ààbò méji dèrò iléẹjọ́ fún ẹ̀sùn gigé ẹran ìyá kàn nílé ìwòsàn
Ileẹjọ giga to n joko ni Iyaganku niluu Ibadan, ti gba beeli nọọsi meji ati osisẹ alaabo meji ti ilewosan Ibadan Central Hospital to wa ni adugbo Ososami nilu Ibadan.
Owo toto ẹgbẹrun lọna igba naira ni wọn fi gba oniduro awọn afurasi naa.
Awọn osisẹ ile iwosan yii ni wọn n kawọ pọnyin rojọ, lẹyin ti awọn idile kan fi ẹsun kan pe wọn ge ẹran ara iya wọn nile iwọsan naa.
Awọn afurasi naa ni Olutọju alaisan Muibat Olatunji, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Oluwafunmilayo Omeh, ẹni ọdun mejilelogun.
Awọn osisẹ alaabo mejeeji tawọn naa jẹ afurasi ninu ẹjọ ọhun, Bamidele Bamiro, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Godwin Omomoh, ẹni ọdun mejilelogun.
Ileẹjọ fi ẹsun meji kan awọn afurasi naa pe wọn ko ṣe apọnle oku iya naa ati pe wọn kọ lati bo ihoho oku naa.
Awọn olujẹjọ naa lo ni awọn ko jẹ bi ẹsun ọhun.
Agbẹjọro fawọn afurasi naa, George Olaniyi wa beere anfani fun awọn olujẹjọ naa lati maa wa lati ile wa jẹjọ naa.

Awọn olujẹjọ ati awọn miiran to ti salọ dijọ lẹdi apo pọ lati ge ara iya naa ni - Ọlọpaa
Adajọ Emmanuel Idowu wa fi onte lu ibeere pe ki awọn olujẹjọ maa wa lati ile, pe ki wọn si san owo to to ẹgbẹrun lọna igba naira pẹlu oniduro meji.
Adajọ Idowu wa sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kọkandinlogun oṣu kejila ọdun 2022.
Ọlọpaa to n ṣe kokari ẹjọ naa, Insipẹtọ Iyabo Oladoyin sọ fun ileẹjọ pe awọn afurasi olujẹjọ ati awọn miiran ti wọn ti fi ẹsẹ fẹ, jọ lẹdi apo pọ lati ge ara iya naa ni.
“Awọn afurasi yii ni ọgbọnjọ oṣu kẹwaa pinnu lati ge ẹya ara, ori ati apa ọtun arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Rachael Boluade.
Boluade lo gbẹmi mi ni ile iwosan wọn ni ọna to lodi si ofin orilẹede Naijiria.”
Bi awọn afurasi naaba si jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, o seese ki wọn fi ẹwọn ọdun meje gbara pẹlu isẹ ase kara.
Ta ló gé ẹran ara ìya wa lọ nílé ìwòsàn lẹ́yìn ọjọ́ kan tó kú?
Awọn mọlẹbi iya agba kan, Rachel Boluade Osanyintolu, ẹni ọdun mọkanlelaadọrun, ti wọn ge ẹran iwaju ori ati apa rẹ lọ nile iwosan to ku si niluu Ibadan, ti ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa.
Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe ọhun, Oludare Henry Osanyintolu sọ pe aisan ẹjẹ riru lo n ba iya agba naa finra, ki wọn to gbe lọ sile iwosan naa
Gẹgẹ bi ohun to sọ, wọn ti n tọju iya awọn nile iwosan ọhun, o si ti n jẹun ki wọn to pe oun pe iya ko le jẹun mọ.
Lẹyin o rẹyin, iya agba naa dakẹ, ti wọn si gbe oku rẹ silẹ nile iwosan naa.

"Awọn osisẹ ile iwosan naa ni awn ko mọ ẹni to ge ẹran ara iya wa lọ la se yari"
Ọkunrin naa tẹsiwaju pe ilẹ ti ṣu lalẹ ọjọ Aiku ti iya agba naa dakẹ, awọn ko si ri ọkọ lati gbe lọ sile igbokupamọ si.
O ni eyi lo jẹ ki wọn fi oku naa silẹ nile iwosan to ku si, ni ikawọ awọn nọọsi atawọn oṣiṣẹ mii to wa nibẹ.
Ọmọ oloogbe naa ni “Wọn ni ka pada wa ni afẹmọju ọjọ keji lati wa gbe oku iya wa... amọ nigba ti wọn yoo fi gbe oku naa jade nibi to wa, a ṣakiyesi pe wọn ti ge ẹran iwaju ori oku naa lọ.”
“A wa n beere lọwọ wọn pe ta ni ẹni to ge ẹran iwaju ori iya wa lọ, wọn ni awọn ko mọ.”
“Nigba ti a tun ni ki a yẹ ẹgbẹ oku naa wo, a tun ṣakiyesi pe wọn ti ge lara ẹran apa rẹ naa lọ."
"Ẹjẹ n da loju ọgbẹ ibi ti wọn ti ge ẹran ara mama wa lẹyin ọjọ kan to ku"
Ni itẹsiwaju ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Henry Osanyintolu fikun pe kayeefi miran to tun sẹlẹ, eyi ti awọn se akiyesi lara oku iya awọn ni ẹjẹ to n da lara mama naa.
"A ri pe se ni ẹjẹ n jade lati oju ọgbẹ mejeeji ti wọn ti ge ẹran ara mama wa.
Eyi si lo n kọ wa lominu pe se o yẹ ki ẹjẹ si maa jade lẹyin wakati mẹrinlelogun ti mama wa ti ku?
A tun beere lọwọ awọn osisẹ ile iwosan naa pe ki lo de ti ẹjẹ fi n da nibẹ, ti wọn ko si ri idahun kankan fun wa."
Ta lo ge ẹran ara iya wa lẹyin wakati mẹrinlelogun to ku?
Henry Osanyintolu ni ohun to wa n ṣe kayeefi fun awọn ẹbi bayii ni pe ilke iwosan naa ko le ṣalaye ẹni to ge ara oku naa ati ohun to fẹ fi ṣe.
O ni ibeere ti awọn si fẹ ki ile iwosan naa dahun si bayii ni pe:
O ni “Ekini, ta lo ge ẹran ara iya wa?
“Ekeji, bawo ni ẹni ti ẹ sọ pe o ti ku lati aago mọkanla abọ ọjọ Aiku, to dẹ jẹ pe ẹjẹ ṣi n yọ lara rẹ ni aago mejila ọjọ keji?”
Henry osanyintolu ni awọn dokita ile iwosan naa ko jade si awọn lati sọrọ lori iṣẹlẹ kayeefi naa, lo mu ki wọn fi ọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
Ẹkunrẹrẹ alaye ohun ti ọmọ oloogbe naa sọ wa ninu fidio to wa loke yii.
Ileesẹ ọlọpaa ti ko awọn alasẹ ile iwosan ti isẹlẹ ti waye
BBC Yoruba wa gbera lọ sile iwosan Ibadan Central Hospital nibi ti isẹlẹ yii ti waye nilu Ibadan.
A si gbiyanju lati bawọn alasẹ ibẹ sọrọ lati gbọ tẹnu wọn nipa bi isẹlẹ yii se jẹ.
Amọ gbogbo igbiyanju wa lo ja si pabo nitori pe wọn ti ko awọn alasẹ ile iwosan naa to le ba wa sọrọ lọ si agọ ọlọpaa.
Ti ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Oyo si sọ fun BBC Yoruba pe iwadii nipa isẹlẹ naa si n tẹsiwaju.
Bawo ni isẹlẹ gigé ẹran iwájú orí òkú àti apá rẹ̀ níléèwòsàn Ibadan se waye?

Oríṣun àwòrán, Google
Saaju lati mu iroyin wa fun yin pe ìdàrúdàpọ̀ ṣẹlẹ̀ nilu Ibadan gẹgẹ bi mọ̀lẹ́bí alaisan ti wọn gbe lọ ileewosan kan fun itọju ṣe yari mọ wọn lọwọ lọ́jọ́ Aje.
Àwọn mọ̀lẹ́bí naa ti ẹni ti wọn gbe lọ ileewosan ti jẹ Ọlọ́run nipe fi ẹ̀sùn kan ileewosan naa pe awọn ẹ̀yà ara kan ko si mọ lara oku ti wọn wa gbé pe awọn nnkan naa ti poora ni oru mọ́jú.
Ṣe ni ero wọ lọ sileewosan naa ti wọn si di gbogbo ẹnu ọ̀nà ibẹ bi wọn ṣe n pe fun idajọ.
Nígbà ti BBC Yoruba kan si Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Oyo atẹjade ti wọn fi ṣọwọ si wa sọ pe ni nnkan bii ago marun àbọ̀ ọjọ Kọkànlelọgbọn Oṣù Kẹ̀wá ni arakunrin kan to n jẹ Osanyintolu Henry to jẹ ọmọ oloogbe Boluade Rachael Osanyintolu.
Wọn ni ẹ̀sùn rẹ ni wipe "iya oun ti wọn gbe lọ ileewosan kan ti a ko fẹ dárúkọ rẹ kú síbẹ̀ ni ọgbọnjọ oṣù kẹwàá ti wọn si gbe e si mọṣuari wọn afi ti wọn de ibẹ ti wọn rii pe apa ibi kan niwaju ori àti oke apa rẹ ti di gige kuro.
Ẹwẹ, Ọlọpaa ni ọwọ ti tẹ àwọn kan ti awọn si ti n ṣe iwadii lori ẹ̀sùn naa. Ohun taa gbọ́ ni wipe ẹni ọdun mọ́kànlélàádọ́rùn-ún ni oloogbe naa ti wọn gbe lọ ileewosan ni o le ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn àmọ́ nigba to ku, ẹbi ni wọn ti yọ ẹ̀yà ara rẹ lẹ́yìn to dagbere faye ni owurọ ọjọ Aiku.
Ki ni tuntun ti wọn ba ni ọjọ keji?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lara awọn ọmọ oloogbe naa ṣàlàyé pe awọn kuro ni ileewosan ọhun ni nnkan bi ago mẹ́jọ alẹ pẹlu èrò lati gbe e lọ si ile igbokupamọsi ni àárọ̀ ọjọ Aiku.
Wọn ni ó ya gbogbo àwọn lẹ́nu pe awọn ri ẹjẹ nilẹ yara ti wọn gbe oku ọhun pamọ si nigba si tun ri pe awọn ẹran ara díẹ̀ niwaju ori ati apa arabinrin naa ti di gige kuro.
Ileeṣẹ iroyin Radio Nigeria ni igbiyanju lati ba adari ileewosan naa sọ̀rọ̀ ja si pabo tori o kọ lati fesi lori ọrọ naa.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ni iwadi ti n lọ lọwọ.
















