Wo ọ̀pọ̀ ohun mère-mère tí wọn fi ṣìkẹ́ Ifeanyi, Ọmọ Davido kó tó kú àti bó ṣe dé lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, @davido
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ọpọ ọmọ Naijiria lo bara jẹ lẹyin ti iroyin iku Ifeanyi Adeleke, to jẹ ọmọ gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke tí ọpọ mọ si Davido ati Chioma Roland jade laye.
Ọmọ ọdun mẹta ọhun lo ko sinu omi adagun to wa nile Davido to wa ni Banana Island ni Ipinlẹ Eko.
Yatọ si awọn ololufẹ Davido, awọn akẹgbẹ rẹ ati awọn oloselu lo ti ransẹ ibanikẹkun si idile naa, eyi to ṣafihan pe ọpọ nifẹ ọmọdekunrin ọhun.
Ikú Ifeanyi Adeleke jẹ́ ìbanujẹ ńlá fun Orílẹ̀èdè
Ifeanyi ṣe ayẹyẹ ọjọbi ọdun mẹta rẹ ni ogunjọ oṣu kẹwaa, ti ọpọ latara ifẹ ti wọn ni si baba rẹ si tu sita kaakiri orí ayelujara lati kí ku orire naa.
Baba Ifeanyi, Davido lo jẹ enikan to ti ṣe iranwọ fun ọpọ awọn eeyan ti wọn lilo rẹ, koda ọpọ awọn olorin kekeke ati awọn akẹgbẹ lo kan sara si.
Nítorí iranlọwọ to n ṣe fun awọn araalu lo difa ede kan tí wọn pe ni " We rise by lifting others".
Ninu rere Davido ati ipa rere ninu awujọ olorin, ọpọ eeyan lo nifẹ Ifeanyi gẹgẹ bii wọn ṣe nifẹ Baba rẹ, ọmọ to jọ iya rẹ, Chioma.
Yatọ si pe Davido n ṣe anu fun awọn eeyan, Davido ma da si ọrọ to ba jẹ mọ ilu, ti ko dẹ ki n fi ẹdun pamọ lori awọn ọrọ to jẹ mọ tí araalu.
Tí a ba n sọrọ olorin to lamilaka, ọkan ni Davido jẹ lorilẹede Naijiria, ti okiki rẹ sí tan kaakiri agbaye, eyi to fa kì ọpọ awọn eeyan jankanjakan lati orilẹede miiran ma ba kẹdun lori iku ọmọ rẹ.
Lara awọn oloṣelu to ti ba Davido kẹdun ni Gomina Ifeanyi Okowa ti ipinlẹ Delta, oludije sipo aarẹ Labour Party, Peter Obi, oludije sipo aarẹ APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ati oludije sipo aarẹ PDP, Atiku Abubakar.
Iku Ifeanyi Adeleke dun ọpọlọpọ awọn eeyan to ti n tẹle ere ifẹ Davido ati Chioma lati ibeerẹ, di igba ti wọn bí saye ati igba to bẹrẹ si ni ma dagba.
Wó ìgbà tó dára tí Ifeanyi Adeleke lò nílé ayé
Ifeanyi Adeleke to jẹ ọmọ ọkùnrin akọkọ Davido lo jẹ ọlọyaya ọmọ to n da ọpọ lọrun lori ayelujara pẹlu awọn aworan ati fidio ni igba ti Baba rẹ ba gbe síta lori ayelujara.
Omodekunrin naa ni ọpọ Instagram títẹ ti ìya ati baba rẹ ma ba ṣe agbatẹru rẹ sugbọn ọpọ awọn asiko yii lo wa lori ọpọ ayelujara Davido ati Chioma.
Pali orin Better Time
Davido gbe akọle orin Better Time jade lọdun 2020, ti o si lo Ifeanyi Adeleke gẹgẹ bii aworan orin naa Lara Pali naa ni a ti ri Ifeanyi to n rakoro nilẹlẹ pẹlu napi.
Davido gbe orin ‘A Better Time’ jade ni ọjọ kẹtala oṣu kọkanla ọdun 2020.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Chioma ń fún Ifeanyi Adeleke lọmu.
Chioma gbe ibi to tí ń fun Ifeanyi Adeleke lounjẹ síta lori ayelujara Instagram, ti awọn mejeeji sí n jọ sí ọkan awọn orin Davido.
Ọmọdékùnrin naa n fi ẹsẹ jọ bi ìya rẹ ṣe ń fun ni oúnjẹ. Chioma, ninu akọle rẹ ni Ifeanyi Adeleke fẹran orin.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Àsìkò ìyá àti ọmọ
Ifeanyi ati iya rẹ Chioma ni wọn gbe ere ifẹ wọn de ori opo Instagram ni bi Chioma ti ṣafihan aworan meji to sì ni ti oun ba ti yanu, Ifeanyi ma gbinyanju lati mọ ohun tí ohun jẹ lẹnu.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Ayẹyẹ ọjọ́bi ọdún kẹta
Aworan Ifeanyi Adeleke to fi ṣe ayẹyẹ ojọbi ọdun kẹta gba orí ayelujara logunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2022.
Ati Davido ati Chioma lo bọ sì orí ayelujara lati kan sara ọmọ wọn to n ṣe ọjọbi naa pẹlu adura lorisirisi.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4