Ìdí rèé ti Femi Otedola ṣé fi ₦2.2bn yà ọkọ ojú omi ṣe ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún - DJ Cuppy

Femi Itedola atawọn ọmọ rẹ ninu ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, @Femi Otedola

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Gbajugbaja adanilaraya, Florence Otedola, ti ọpọ mọ si DJ Cuppy tí ṣafihan idi baba rẹ, Femi Otedola ṣe na obitibiti owo lati ya ọkọ ojú omi fi ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun laye.

Laipẹ yii ni gbajugbaja onisowo naa dá awuyewuye silẹ lori ayelujara lẹyin to fi owo to ju bilọnu meji naira lọ ya ọkọ ojú omi Aristotle Onassis' Christina O super Luxury.

Ọkọ oju omi naa lo fi rin irinajo lori okun Mediterranean fun ọsẹ mẹta.

Bí o se gbaradi fun ayẹyẹ ọjọ ibi, Otedola lori ayelujara opo Instagram rẹ, ṣafihan awọn aworan bí o ṣe gbafẹ pẹlu awọn mọlẹbi rẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Femi Otedola

"Bí mo ṣe wo oju baba mi, mo rí pé inu rẹ dun lọpọlọpọ, nkan ti a pe ni ifẹ ree, ẹbi ni akọkọ"

Nigba to n sọrọ nípa ayẹyẹ ọjọ ibi baba rẹ loju opo ayelujara Instagram rẹ, DJ Cuppy naa ṣafihan awọn aworan bi oun ati mọlẹbi rẹ ṣe gbafẹ pẹlu baba wọn lori ọkọ oju omi naa.

Cuppy salaye pe Baba rẹ, lati kekere lo ti ni erongba lati ṣe abẹwo si ọkọ oju omi Christiana O nítorí Aristotle Onassis, to jẹ eyi to nifẹ si pupọ.

"Lati ti ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun rẹ, ko ki n ṣe pe o ṣe abẹwo si ọkọ oju omi nìkan, o ṣe agbatẹru pe ki gbogbo ẹbi rẹ wa lori ọkọ oju omi fun ọsẹ mẹta.

"Bí mo ṣe wo oju baba mi, mo rí pé inu rẹ dun lọpọlọpọ, nkan ti a pe ni ifẹ re, mọlẹbi saaju."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Femi Otedola

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Femi Otedola