Ikun Akoko: Ọba Yorùbá gbọdọ̀ ṣe tán láti ṣe ẹ̀sìn àbáláyé - Ààrẹ ẹgbẹ́ òníṣẹ̀ṣẹ̀ Ìpínlè Ọsun

Ọba Yorùbá gbọdọ̀ ṣe tán láti ṣe ẹ̀sìn àbáláyé - Ààrẹ ẹgbẹ́ òníṣẹ̀ṣẹ̀ Ìpínlè Ọsun

Ọba Onikun ati Dokita Atanda

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lẹyin iwọde ti o waye ni ilu Ikun Akoko ni ijọba ibilẹ Iwọ oorun Akoko ti awọn ọdọ ati awọn agbaagba ilu ti ṣe iwọde lori awọn isẹlẹ to n waye ninu ilu Ikun Akoko, awuyewuye ti gbode kan ti awọn ero ori ayelujara naa si ti n da si ọrọ.

Ẹwẹ, Aare ẹgbẹ awọn ẹlesin ibilẹ nipinle Ọsun Oluseyi Atanda ti bu ẹnu atẹ lu awọn iroyin nipa aibikita Ọba wọn, Olukumbola Adedoyin lori awọn isẹlẹ to n sẹlẹ ninu ilu Ikun Akoko.

Wọn fẹsun kan pe eku ko ke bi eku, ẹyẹ ko si ke bi ẹyẹ ati pe ṣe ni awọn ọdọ n ku ni rewe rewe ninu ilu naa. Wọn si ni ṣe ni Ọba wọn rọ mọ ẹsin Kristẹni to ṣẹṣẹ yipada si lai ṣe etutu to yẹ.

Ninu Ọrọ rẹ, Oluseyi Atanda ni awọn Ọba Ilu koọkan nilẹ Yoruba ni ojuṣe ti wọn n ṣe pẹlu awọn alawo ki ilu baa le roju raye.

O ni idalu ni iṣelu, ọpọlọpọ ilu lo ni asa tabi oro ti wọn maa n ṣe ti Ọba ilu yoo pese nnkan etutu ti yoo si ṣe adura, ṣugbọn Ọba ti ko ba gbagbọ ninu esin iṣembaye o ṣeeṣẹ ki o fa ifasẹyin fun ilu rẹ.

Nigbati o sọrọ lori rogbodiyan to waye ni ilu Ikun akọkọ, Atanda ni awọn ara ilu Ikun Akoko ko jẹbi lati fi ehonu han lori aibikita Ọba ilu wọn lati ṣe etutu lati dinwọ iku ku ni ilu wọn nitori ti ijiya ai ṣe etutu tabi rubọ ba de, gbogbo awọn ara ilu ni yoo kopa ninu ijiya naa.

Aarẹ ẹleṣin abalaye ti ipinle Osun ni gbogbo Ọba ti ko ba ṣetan lati ni ibaṣepọ pẹlu awọn ẹleṣin ibilẹ ko yẹ ki o de ade Ọba, nitori igbakigba ti kabiyesi ba de ade Ọba o ti sọọ di oriṣa.

Atanda ni Ọba ti ko ba ṣetan lati ṣe ti awọn ooṣa ati ẹsin ibilẹ, oye Ọba ko too sii.

Rògbòdìyàn yíì kí ṣé nǹkan ńlá - Ọba Olakunbola Adedoyin

Ọba Olakumbola Adedoyin Onikun ti ilu Ikun ni, gbogbo iṣẹlẹ to n sẹlẹ ninu ilu ohun kii ṣe nkan babara.

Adedoyin nii ki ṣe nitori wi pe ohun jẹ ẹlesin onigbagbọ lo fa rogbodiyan nitori ohun ti lo odun mokandinlogun lori ite gẹgẹ bi Ọba, ti alafia ati ifẹ si wa ninu ilu laarin awọn ẹlẹsin mẹtẹẹta.

Aráàlú Ikun Akoko fọnmú pé oríadé tó di Krìsítẹ́nì ló ń fa ikú àìtọ̀jọ́ nílùú

Ikun Akoko gbóná báwọn ọ̀dọ́ ṣe yarí fún ọba tó ní òun kò ṣe ètùtù

Aworan

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Awọn ọdọ ati awọn agbaagba kan ni ilu Ikun-Akoko nipinlẹ Ondo ti fariga lẹyin ti ọba wọn darapọ mọ ẹsin Kristẹni.

Awọn ọdọ ilu naa ṣe ifẹhọnuhan lọ si aafin Onikun ti Ikun, Ọba Olokunbola Adedoyin.

Awọn ọdọ naa gbe ewe dani, imọ ọpẹ ati awọn akọle ti wọn si n rin kaakiri ilu naa lati fi aidunnu wọn han.

Lati igba ti Onikun ti di Kristiẹni ni ijamba ti n sẹlẹ nilu wa - Awọn ọdọ

Ẹsun ti wọn fi kan ọba naa ni pe lati igba to ti darapọ mọ ẹsin Kristẹni, ni ijamba ti n sẹlẹ ni ilu naa.

Wọn ni niṣe ni ọba naa n kaakiri igboro, to si n sọ fun awọn eniyan wi pe oun ti fi aye oun fun Jesu Kristi.

Bakan naa ni wọn ni Ọba kọ lati ṣe etutu to yẹ ko ṣe ni ilu naa, ti eleyii si ti fa ọpọlọpọ ijamba ni ilu naa.

Wọn tun fikun un pe awọn etutu to yẹ ko ṣe gẹgẹ bi ilana oba ni ilẹ naa lo kọ lati ṣe, ti ko si fi iye si awọn ohun abalaye ni ilu naa.

Awọn afẹhọnuhan naa tun ṣekọlu si ileepo kan ṣoṣo to jẹ ti ọba naa to wa ni ilu ọhun.

Gbogbo igba ni mo n gbadura fun ilu Ikun Akoko - Ọba Olokunbola Adedoyin

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ninu esi rẹ si awọn akọroyin, Ọba Adedoyin ni oun gun ori oye awọn baba oun ni nkan bii ọdun mọkandinlogun ṣẹyin.

O ni lati igba naa ni oun ti n sa ipa oun latiu mu idagbasoke ba ilu naa

Ọba ni awọn to ṣekọlu naa fẹ pa oun ati ọmọ ọun ni ki wọn to lọ si ileepo oun lati jo mọlẹ.

Bakan naa ni Ọba fikun un pe awọn ọdọ naa ṣa osiṣẹ ileepo naa ni ada nigba ti wọn ṣekọlu sibẹ, ti o kere tan awọn irinṣẹ ti wọn bajẹ si fẹrẹ to miliọnu meji naira.

Ọba naa ṣe apejuwe ara rẹ gẹgẹ bi aladura, to si n fi gbogbo igba rẹ gbadura fun awọn ara Ikun Akoko.

Iroyin fikun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ mu awọn kan to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn yoo si foju ba ileẹjọ.