Bí ọmọbìnrin tó tan mọ́ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣe gòkè àgbà di Ọgagun, Brigadier General l'Amẹ́ríkà

Amanda Azubuike

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@CG_ARMYROTC

Ọna wo ni Amanda gba di Ọgagun Agba ologun Amẹrika?

Amanda Azubuike

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/AZUBUIKE_IG

Ọgagun Amanda I. Azubuike ti kọ́kọ́ gba iṣẹ́ rẹ ni Fáṣítì Central Arkansas ni Oṣù Kejìlá ọdun 1993 níbi to ti kawe tan gboye Bachelors Degree ninu imọ ibanisọrọ.

Lọdun 1995 lo kẹ́kọ̀ọ́ pari nile ẹ̀kọ́ wiwa ọkọ ofurufu gẹgẹ bii UH-1 pilot. O wa bẹ̀rẹ̀ isẹ pẹlu ọwọ ogun oju ofurufu - 924th Aviation Battalion pẹlu awọn

Hunter Army Airfield ni Georgia nibi to ti jẹ adarí ikọ ogun.

Nigba to ya lo tun ṣiṣẹ́ gẹgẹ bi ologun to n moju to irina ofurufu, lẹyin rẹ lo tun di adari ikọ platoon ni Ileeṣẹ ologun ofurufu ni Sinai, Egypt.

Bakan naa lo tun ti ba ikọ ogun South Korea ṣiṣẹ́.

Bẹẹ si lo ti ṣiṣẹ́ ni North Carolina gẹ́gẹ́ bi adari ikọ ogun Alpha Company, Victory Brigade.

Amanda Azubuike

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@CG_ARMYROTC

O tun lọ kawe kun iwe ti wọn si gbe e ga gẹgẹ bii adari ikọ ogun ni Kuwait laarin ọdun 2005 si 2006 nibi to ti n ṣiṣẹ́ nipa ọrọ to kan araalu.

Wọn pada yan an lọ ṣiṣẹ́ ni olu Ileeṣẹ ologun to wa ni Amẹrika.

Ọgagun Azubuike tun ṣiṣẹ́ gẹgẹ bii ologun to n moju to ọrọ iroyin àtàwọn araalu ni Georgia.

O tesiwaju lati kawe gboye ipele Masters to fi di ẹni to n ṣiṣẹ́ ni ọ́fíìsì ọga agba awọn ologun.

Lẹyin to lọ ile ẹ̀kọ́ imọ ijagun (war college), wọn tun gbe e ga lẹ́nu isẹ gẹgẹ bii oludari eka to n rí sí ọ̀rọ̀ awọn araalu wọn si gbe e lọ si Afghanistan lati lọ ṣiṣẹ́.

Kete to gba igbega de ipo Colonel ni wọn gbe e lọ si olu Ileeṣẹ àpapọ̀ awọn ologun ni Washington DC to si wa lara ikọ to gbaruku ti eto ifilọọlẹ Ààrẹ ikejidinlọgọ́ta.

O ṣíṣe adari ẹ̀ka Ileeṣẹ wọn ni Florida ati kaakiri agbegbe naa pẹlu oniruuru àkọsílẹ̀ isẹ takuntakun to sì ti gba ọpọlọpọ àmì ẹ̀yẹ titi to fi de ipo to wa lonii.

Amanda Azubuike

Oríṣun àwòrán, Amanda Azubuike