A kò lé sàn owó iṣẹ́ tí àwọn olùkọ́ Fásitì kò ṣe fún wọn- Ìjọba Àpapọ̀

aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti salaye ohun to sẹlẹ ti ijọba fi san idaji owo oṣu fun awọn olukọ fasiti lẹyin ti wọn kede pe awọn ti fi opin si iyanṣelodi ọlọjọ gbọrọ ti wọn gun le lati ninu oṣu keji ọdun.

Ajọ ASUU gun le iyanlodi lọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2022 sugbọn gbogbo atotonu ati asẹ lati ileẹjọ, awọn olukọ fasiti gba lati fi opin iyansẹlodi oloṣu mẹjọ ọhun lọjọ kẹrinla oṣu kẹwaa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ osisẹ, Olajide Oshundun, fi sita fun awọn akọroyin ni iroyin ofege lo kaakiri ori ayelujara pe ijọba ko dọgba ni sisan owo fun awọn osisẹ

“A san owo fun pẹlu awọn iwadii ti a ṣe lori ọjọ ti wọn fi sisẹ, bẹrẹ lati ọjọ ti wọn kede opin si iyanṣelodi naa.

“A gbe igbeṣe yii nitori pe a ko le san owo isẹ ti wọn ko ṣe fun wọn. Ọwọ onikaluku lo di bayii.

Gẹgẹ bii Oshundun ṣe sọ, Minisita fun ọrọ osisẹ, Chris Ngige ko fi gba kankan sọ fun ẹnikẹni ko san owo idaji fun awọn olukọ fasiti.

Bakan an ni leeṣẹ ọhun bu ẹnu atẹlu alaga ẹgbẹ olukọ fasiti Asuu ni Usman Danfodiyo, Muhammad Al-Mustapyha, ẹni to ni minisita lọ sọ fun awọn ẹka to san owo osisẹ pe ko san idaji owo fun awọn osisẹ.

Oshundun fikun pe, “Lẹyin asẹ ileẹjọ kotẹmilọrun, eyi to palasẹ fun awọn olukọ pe ki wọn pada si ẹnu isẹ, awọn adari ẹgbẹ fiwe ransẹ si Minisita pe wọn ti pada si ẹnu isẹ .

“Minisita fun ọrọ osisẹ naa si kọ we pe oun ti gba iwe ti wọn fi ransẹ, ti a si ti ti fidi rẹ mulẹ pe

Ìjọba kò pọ́n wa lé ló ṣe fún wa ní ìdajì owó oṣù – ASUU

ASUU strike

Oríṣun àwòrán, Channels

Awọn akẹkọọ fasiti ni Naijria ti fi aidunu wọn lede lẹyin ti jọba apapọ san idaji owo oṣu fun wọn fun oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.

Ọjọbọ ni iroyin gbode pe idaji owo oṣu ni ijọba san fun awọn olukọ naa lẹyin ti wọn fopin si iyanṣelodi wọn oloṣu mẹjọ ninu oṣu Kẹwaa.

Ijọba ko tii sọ nnkankan lori eredi ti wọn ṣe san owo fun awọn olukọ naa ni kete ti wọn fopin si iyanṣelodin wọn.

Ọkan lara awọn olukọ ọhun ni ijọba ti sọ awọn di ẹni to n gba owo iṣẹ oojọ.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni wọn fopin si iyanṣelodi naa, nigba ti wọn pada sile ẹkọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa kan naa.

Ijọba n gbogun ti eto ẹkọ ni Naijiria

Ọkan lara awọn adari ẹgbẹ ASUU, Austen Sado sọ fun BBC pe ohun ti ijọba ṣe naa ba awọn ninu jẹ gidi.

O ni lara awọn ohun ti awọn yanṣelodi si ni bi ijọba ko ṣe san owo gidi fun awọn, bẹẹ awọn oloṣelu n gba owo gọbọi.

 Sado sọ pe ko mu ọgbọn dani pe owo ti awọn n gba kere, ijọba tun n fun awọn ni idaji owo oṣu.

O ni “A ri igbesẹ naa gẹgẹ bii igba ti jọba ba n gbogun ti eto ẹkọ ni.”

Ọmọwe naa fi kun un pe ijọba n gbiyanju layi tu ẹgbẹ ASUU ka.

Idi ti a ṣe fopin si iyanṣelodi wa

Aarẹ ASUU, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke sọ pe aṣẹ ile ẹjọ lo jẹ ki awọn fopin si iyanṣelodi awọn.

O ni awọn tun ro ti apọnle ti wọn ni fun Aarẹ Muhammadu Buhari, ati adari ile igbimọ aṣojuṣofin, Femi Gbajabiamila.

Gẹgẹ bii ohun to sọ ninu atẹjade kan, inu ASUU ko dun si ọwọ ti ijọba fi mu ọrọ naa rara.