Ìyàwó lè lo ọwọ́ rẹ̀ fi ba ọkọ ṣeré lásìkò Halaada rẹ̀, èyí kò ba ẹ̀sìn jẹ́- Aafa Abdullateef Lanre

Àkọlé fídíò, Ìyàwó lè lo ọwọ́ rẹ̀ fi ba ọkọ ṣeré lásìkò Halaada rẹ̀, èyí kò ba ẹ̀sìn jẹ́- Aafa Abdullat

Aafa Abdullateef Lanre tun menuba awon sitaili ibalopọ ti ko ba ẹ̀sin Islam jẹ laarin lọkọlaya

Lori ọpọlọpọ ibeere ti a gba nipa ọna ibalopọ to tọna ni BBC ṣe wa Aafa Abdullateef Lanre to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ ibalopọ to tun jẹ onimọ ninu ẹsin Islam kan.

Aafa yii ṣalaye pe ọna meji ni oju ti awọn onimọ Islam fi wo ibalopọ alafi-ẹnu-ṣe ti oloyinbo n pe ni: Oral Sex

Ibalopo alafenuse kini Islam sọ nipa rẹ̀: Oral Sex
Àkọlé àwòrán, Ibalopo alafenuse kini Islam sọ nipa rẹ̀: Oral Sex

Kini Onimo yii tun salaye lori re?

Aafa Abdullateef Lanre tun sọrọ nipa koko pe ọkunrin ni anfani ninu Islam lati fẹ obinrin titi de ori mẹrin.

Ati pe ti iyawo rẹ kan ko ba fẹran ibalopọ alafienu se, yoo ri obinrin mii ti o fẹran rẹ ki ot o fẹ iyawo de merin.

Ni afikun, iru okunrin bẹẹ ko lẹtọ lati kọ iyawo ti ko ba fẹran ibalopọ alafiẹnu ṣe sile rara ninu Islam.

Kini Islam sọ nipa ibalopo alafienu se?

O ni Laarin Halaali ati Haraamu ni ibalopo alafẹnuṣe wa.

Labẹ Shariah, Haram ni nkan ti a ko faaye gba. Halal ni eleyi ti a faaye gba.

Eyi to ṣe pe bi a koba ṣe e, a o gba laada. Bi a ba si ṣe e ko si ijiya fun wa ni wọ n n pe ni Makrooh.

Aafa Abdullateef sọ pe ọkọ ko le kọ aya rẹ silẹ nitori pe ko fẹran ibalopọ alafenuse sugbon Islam faaye gba ọkunrin to ba kundun rẹ lati fẹ iyawo de ori mẹrin ninu eyi ti yoo ti ri obinrin ti oun naa fẹran iru ibalopọ bẹẹ.