Mó dìtẹ̀ ìṣèjọba Jonathan torí òṣèlú- Adams Oshiomhole

Oríṣun àwòrán, @realadamsoshiomhole
Alaga fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress nigba kan ri, Adam Oshiomhole sọ fun aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan pe oun ditẹ iṣejọba rẹ nitori ọrọ ọselu.
Oshiomhole sọ ọrọ yii nigbati o darapọ aarẹ tẹlẹ naa nibi ayẹyẹ iranti ọdun kan ti Idahosa Okunbo jade laye niluu Abuja.
O ni Jonathan fi ipa rẹrẹ silẹ gẹgẹ bi Aarẹ sugbọn oun tako ijọba Jonathan rẹ nitori ija oṣelu.
" Ipa ti aarẹ ti fisilẹ, a ko le ri ẹni ti yoo ṣe bi Aarẹ Jonathan.
“Gẹgẹ bi a ṣe mọ ọrọ oṣelu, angẹli gan ma fidi rẹmi nigba mii ṣugbọn Aarẹ ṣe isẹ takuntakun ti awọn yoku to tẹlẹ wọn gbọdọ wo awukọṣe wọn.
“Ninu iṣejọba yii, ẹ kọ ile iwe fun awọn Almaijiri, nigbati ẹ ro pe ko yẹ ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria kankan wa lori titi, ki wọn ma ni anfani si ile ẹkọ.
“Gbogbo awọn erongba yii ni ko jẹ tuntun sugbọn a padanu ẹmi lati ṣe isẹ naa.
“A ko lo ṣe iyato laarin ọta ati ọrẹ, o di igba ti a ba ku.
“A ki mọ iyi eeyan afi ti ko si lara wa mọ.”
Ẹ yàgò fún àwọn olóṣèlú fẹ́rànjẹ̀kọ́ – Jonathan

Oríṣun àwòrán, @goodluck_ebelejonathan
Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan ti rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati yago fun awọn oloṣelu ti ko fẹran ilu, ti wọn yoo fi owo ra ibo ninu eto idibo ti yoo waye lọdun 2023.
Jonathan sisọ loju ọrọ yii nigbati o darapọ awọn mọlebi Okunbo nibi bi ayẹyẹ iranti ọdun kan ti Idahosa Okunbo jade laye niluu Abuja
Aarẹ tẹlẹ wa rọ awọn eeyan pe ki wọn ro ọjọ ọla awọn ọmọ wọn ti wọn ba ti fẹ yan awọn oludari fun eto iṣejọba, ti wọn si ma jẹ ki ẹnikẹni gbe ẹtọ wọn lọwọ wọn ninu eto idibo orilẹede Naijiria lọdun 2023.
“Saaju eto idibo ọdun 2023, awọn oloṣelu to wa ipo kan, ti setan lati fi ipologo ba wa sọrọ.
“Sugbọn erongba wa ju ọdun 2023 lọ, Nkan ti o kan ju ni bi orilẹede Naijiria yoo ṣe ri adari ti yoo mu tẹsiwaju lati bọ si ipo to ye ko wa ni awujọ awọn orilẹede ile adulawọ yoku,
Imọran mi fun awọn eeyan ni wọn ọjọ ọla awọn ọmọ won ti wọn ba ti n dibo lati yaa adari tuntun.
“Ani lati yago fun awọn oloṣelu fẹranjẹkọ, ti wọn fẹ fi birẹdi tan awọn eeyan jẹ, ki a si ri pe a ko yan awọn oloṣelu ti wọn yoo ba ọjọ ọla jẹ fun awọn ọmọ wa ati arọmọdọmọ wa
“A gbọdọ ri pe a yan oloṣelu ti yo fi itan to da silẹ, ti yoo si mu alaafia ati ifọkanbalẹ wa si orilẹede Naijiria.”















