Kaduna Insecurity: Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà sẹku pa àwọn jàndùkú nínú igbó Kaduna,wo nkan tí wọn rí gbà lọ́wọ́ wọn

Aworan alupupu ati ibọn ti ologun ri gba lọwọ awọn janduku

Oríṣun àwòrán, Samuel Aruwan

Ileeṣẹ ologun lorileede Naijiria ti rẹyin awọn janduku agbebọn kan to n dun koko mọ awn eeyan ipinlẹ Kaduna.

Ninu iroyin to tẹwa lọwọ,aimọye awọn janduku yi ni wọn ṣeku pa ni Galbi ni ijọba ibil Chikun ni ipinlẹ Kaduna.

Kọmiṣana feto aabo labẹlẹ ni Kaduna Samuel Aruwan fi ọrọ yi lede ninu atẹjade kan to fi sita.

Ninu rẹ, o sọ pe awọn ọmọ ogun ofurufu Naijiria ṣina bo ibuba awọn janduku agbebọn yi to wa ni agbegbe Galbi.

Bo tilẹ jẹ wi pe ko daruko pato iye awọn janduku to jẹ Ọlọrun nipe latara ikọlu yi, o ni awọn ọmọ ogun gba ibọn AK-47 mẹta ati alupupu meje lọwọ wọn.

Gẹgẹ bi alaye to ṣe, awọn ọmọ ogun Naijiria sọda odo Kaduna nibi ti ija lile ti waye laarin awọn ati awọn janduku yi.

O ni pupọ wọn lo salo nigba ti wọn ko le koju awọn ologun mọ.

Ẹwẹ, o ni ijọba Kaduna dupẹ lọwọ awọn ọmọ ogun, ọlọpaa ati awọn oṣiṣẹ ọtẹlmuyẹ to pawọ pọ ṣe aṣeyọri yi.

Àkọlé fídíò, xxx

Ipenija aabo ko ṣẹṣẹ bẹrẹ ni Kaduna

Ninu awọn ipinlẹ ti ipenija aabo ko jẹ ki wọn ribi fẹd lori oroonro ni Kaduna wa.

Ni paapa awọn eeyan Birnin Gwari ati Chikun a maa koju idunkoko lọwọ awn janduku yi.

Laipẹ yi ni iroyin gbode pe awọn janduku kan ni Birnin Gwari ti n gbe awọn obinrin Kaduna ni iyawo.

Iṣẹlẹ naa waye ni Tsohuwar Kuyallo taa si gbọ pe awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi Ansaru ti bẹrẹ si ni ṣeto igbeyawo laarin awọn ọmọ ogun rẹ ati awọn obinrin ilu naa.

Amọ ṣa ijọba lawọn ti n ṣe aṣeyọri nipa kikoju awọn janduku yi nitori laipẹ yi lawọn ọmọ ogun ofurufu pa ogbologbo jandukukan Alhaji Shanono ati awọn ọmọ lẹyin rẹ mẹtadinlogun.