Bàbá mi wà nínú ilé tí wọn sun di eérú, ń kò mọ̀ bóyá ó jóná mọ́lé ni tàbí wọn ji gbé lọ - Aṣòfin
Jàǹdùkú da ìpàdé PDP rú ní Ede, ẹ̀mí kan bọ́, wọ́n dáná sun ilé òbí aṣòfin kan

Laasigbo oselu to n ja rainrain nilẹ nipinlẹ Osun saaju eto idibo gomina ati lẹyin rẹ, ni ko tii jẹ rodo, lọ ree sinmi bayii.
Koda, se ni wahala naa tun n fọnna soju si bayii, ti ẹmi awọn eeyan kan si n ba rogbodiyan naa lọ.
Ni ọjọ Ẹti, se ni ipade wọọdu tawọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP se tun gbọna miran yọ, eyi to mu ẹmi l pẹlu.
Akọroyin BBC to wa nilu Osogbo jabọ pe ipade wọọdu naa to waye ni ọlọba Atapara ni ilu Ede nirọlẹ ọjọ Ẹti lo di isu ata yanyan.
Ki lo fa rogbodiyan nilu Ede to mu ẹmi eeyan lọ?
Gẹgẹ bi Asofin Kofoworola Babajide, tii se olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin ipinlẹ Osun, to ba BBC Yoruba salaye ohun to fa rogbodiyan naa.
Babajide ni nigba tohun dé ibi ìpàdé naa, oun ba Arabinrin kan, Silifatu Olalekan, to n sẹ epe fún ọkàn lara awọn ọmọ ẹgbẹ, ti ohun sí gbìyànjú láti rí pe alafia pada jọba nibẹ, ki o to di pe ohun lọ fún ìpàdé miran ni Osogbo.
Amọ o ni lẹyin ti oun kuro nibẹ tan, ni oun gbọ pe janduku kan latinu ẹgbẹ oselu alatako, ko igi ati ada lati maa na awọn eeyan, ti wọn si lo anfaani aawọ abẹnu laarin awọn ọmọ ẹgbẹ to waye naa, lati kọju ija si wọn.
O ni iro ibọn n dun lakọlakọ, ti ọrọ si di ẹni ori yọ, o dile, eyi to mu ki awọn osisẹ ọlọpaa to n paraaro nilu naa, fi duro lati bomi pana aawọ naa.
“Wọn sọ fun mi pe nigba ti awọn ọlọpaa de, lati beere nipa ohun to sẹlẹ, ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ẹlẹgẹ, ti ọlọpaa kan, o fa ibọn yọ lapo rẹ, oun ati ọlọpaa naa si n yin ibọn mọra wọn.
Amọ Ẹlẹgẹ yii ni ibọn dun julọ, to si ku, ti wọn si ni awọn ọlọpaa naa ti gbe oku rẹ lọ.
Isẹlẹ yii lo wa bi awọn alatilẹyin Ẹlẹgẹ yii ninu, ti wọn fi lọ dana sun ile awọn obi olori ọmọ ẹgbẹ oselu to pọ julọ naa.

Wọn dana sun ile obi mi, koda, n ko ri baba mi titi di asiko yii:
Asofin Babajide Kofoworola ni nigba ti ohun de Osogbo, ni wọn pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe awon eeyan kan ti n dana sun ile àwọn Òbí oun.
O ni gbogbo dukia to wa ninu ile naa ni wọn jo kanlẹ gburugburu ayafi orule to nira fun ọwọ ina lati mu lo ku.
“Mama mi ti jade amọ baba mi ti dagba, ti wọn si wa ninu ile, titi di akoko yii, n ko tii ri baba mi.
Boya wọn ye ni, boya wọn pa wọn ni, boya wọn si gbe wọn wọn lọ ni, n ko mọ.
A ti n wa awọn ohun to jona lati mọ boya wọn sun eeyan mọle amọ ohun gbogbo lo ti di eeru.”
Ẹgbẹ oselu PDP faraya lori ikọlu ojoojumọ to n waye nipinlẹ Osun lẹyin ibo:
Adele alaga egbe oselu PDP nipinle Osun, Dokita Adekunle Akindele, ti wa ke si awon osise alaabo nipinle Osun lati mase wo ọrọ wahala ti awon omo egbe oselu alatakoAPC fẹ ma a fa nilu Ede, to je ilu gomina tuntun, Sen. Ademola Adeleke, niran rara.
Akindele salaye pe se ni awon egbe oselu APC n japoro kaakiri bayii, ti won si fẹ sọ ipinle Osun di ibudo ogun.
Gbogbo iyanju BBC Yoruba lati ba awọn asaaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Osun sọrọ, lo ja si pabo.
Amọ a si n gbiyanju siwaju lati gbọ salaye tiwọn naa lori awọn ẹsun idaluru ti PDP fi kan wọn naa.

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun tu ikọ ọlọpaa to n paraaro ilu ka tori isẹlẹ ipaniyan yii:
Alukoro ileese olopaa ni ipinle Ọsun, Yemisi Opalola ti fìdí iṣẹlẹ mulẹ pe ileese olopaa ti n se iwadi isele naa.
Atẹjade kan ti Opalola fisita lori isẹlẹ naa ni Komisana ọlọpaa nipinlẹ Osun, Olawale Olokode ti pasẹ pe ki wọn tu ikọ ọlọpaa to n paraaro ilu naa ka.
Atẹjade naa ni igbesẹ ọhun waye nitori ọpọ ariwisi ati iwa aiba ilana isẹ agbofinro mu ti wọn hu.
Kọmisana ọlọpaa ni igbesẹ naa bẹrẹ lọgan, to si wa lati mu ko jẹ arikọgbọn fun awn ọlọpaa yoku nitori ileesẹ oun ko ni faramọ iwakiwa lati ọdọ agbofinro kankan.
Opalola ni ọwọ ofin yíò gbé gbogbo awọn to lọwọ nínú rogbodiyan naa, ti ko sí ní yo ẹnikẹni sílẹ.
















