Wàhálà míì tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin ọmọ ẹgbẹ́ Shitte àti ikọ̀ aláàbò

aworan Sheikh Ibraheem El-Zakzaky

Oríṣun àwòrán, El-Zakzaky

Rogbodiyan miran tun bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Shitte atawọn ikọ alaabo nilu Kaduna lọjọ Aje.

Adari ẹgbẹ naa, Sheikh Ibraheem El-Zakzaky, wa fi ẹsun kan awọn ẹsọ alaabo pe wọn ṣekupa awọn ọmọ ẹgbẹ naa mẹfa.

Bakan naa lo ni wọn tun ṣe ogoji eeyan mii leṣe pupọ.

Sheikh Ibraheem El-Zakzaky, ninu atẹsita kan to fi sita fun awọn akọroyin, ni isẹlẹ naa waye nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ Shitte n kopa ninu isẹ akanṣe, ‘ASHURA’ ni agbegbe Zaria ni ipinlẹ Kaduna.

“Awọn ẹsọ alaabo ti yin ibọn fun eeyan bii mẹfa lara awọn alatilẹyin Sheikh Ibraheem El-Zakzaky,.

Wọn tun ṣe eeyan ogoji miiran leṣe pipọ nigba ta n ṣe akanṣe isẹ ti ko lodi ofin, ti ọpọ eeyan maa n ṣe lorilẹede Naijiria.

aworan Sheikh Ibraheem El-Zakzaky

Oríṣun àwòrán, El-Zakzaky

Bakan, ọkan lara awọn adari ẹgbẹ naa ni Zaria, Abdulhamid Bello ni ṣadede ni awọn ẹsọ alaabo bẹrẹ si ni maa yin ibọn fun awọn ẹgbẹ, ti wọn si gba ẹmi awọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Bello ni orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti awọn ẹsọ abo pa ni, Jafar Jushi, Kazeem Magume ati Ali Samaru.

Awọn yoku ni Muhsin Zakzaky, Umar Fatika ati ẹlomiran ti wọn ko fi orukọ rẹ sita.

O ni awọn ko ti le sọ iye eeyan to lubadi iṣẹlẹ naa nitori ọpọ wọn ti wa ni ile iwosan St Lukes ti o wa ni Wusasa.

O tun ni awọn miiran wa ni ile iwosan fasiti Ahmadu Bello ni Zaria..

Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna, DSP Mohammed Jalinge, ni oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ti awọn si ti bẹrẹ iwadi lori ẹsun ti wọn fi kan awọn agbofinro naa.

Agbébọn jí tọkọ-taya túntún àti ọ̀pọ̀ èèyàn míì gbé lọ

Tọkọtaya tuntun ti agbebọn ji gbe lọ

Awọn agbebọn to n soro bii agbọn lẹkun ariwa Naijiria ti ji tọkọtaya tuntun kan, ti wọn sẹsẹ se igbeyawo ji gbe lọ ni ipinlẹ Katsina.

Bakan naa ni wọn tun pa awọn eeyan meji miran lasiko ikọlu ti wọn se lagbegbe Shola nilu Katsina.

Gẹgẹ bawọn aladugbo nibi ti isẹlẹ ọhun ti waye ti wi, awọn agbebọn naa yabo wọn ni deede aago kan kọja isẹju mẹẹdọgbọn loru, ti wọn si n yin ibọn lakọlakọ fun ọpọlọpọ wakati.

Wọn wa fidi rẹ mulẹ pe ọpọ awọn araalu to fi ara wọn silẹ lati doju ogun kọ awn agbebọn naa, ti wọn n pe ni Volunteers lo padanu ẹmi wọn.

Ilakaka awọn ọmọogun abẹle naa, lati daabo bo tọkọtaya tuntun ọhun, ki awọn agbebọn naa maa ba ri wọn gbe lọ, lo ja si pabo, ti wọn si fi ẹmi ara wọn di.

Koda wọn ni ọpọ wọn gan lo tun fi ara pa.

Amọ nigba to ya, iyawo funra rẹ gan lo ni ki awọn ọmọ ogun abẹle naa du ẹmi wọn, ki wn si maa salọ, nitori agbara tawọn agbebọn ju tiwọn lọ

Lẹyin tọkọ-taya tuntun, agbebọn tun ji ọpọ eeyan miran lọ:

Olugbe adugbo Shola kan to ba BBC sọrọ salaye pe ọkada ni awọn agbebọn ọhun gun wọ adugbo naa lana pẹlu ibọn, ti wọn si n yinbọn soke takotako.

Ọkunrin naa ni lati ẹyin ile naa ni awọn agbebọn ọhun gba wọle eyi to sokunfa iku eeyan meji nibẹ, ti eeyan meji miran si tun fara pa.

Bakan naa ni awọn olugbe adugbo yii tun fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan miran mii, ti wọn ko le sọ iye wọn ni awọn agbebọn naa gbe lọ yatọ si awn tọkọ-taya.

“Isẹlẹ yii kii se igba akọkọ tawọn agbebọn yoo klu adugbo Shola. O si ti le ni osu kan sẹyin ti wọn ti wa kẹyin.

A ti gba itusilẹ eeyan mẹfa, ta si pa agbebọn meje to n sisẹ ijinigbe:

Nibayii, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, Gambo Isah ti fidi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni awọn osisẹ awọn ti n saayan lati gba itusilẹ tọkọ taya naa atawọn eeyan miran ti wọn gbe lọ.

Bakan naa lo fikun peileesẹ ọlọpaa ti doola ẹmi eeyan mẹfa ti wọn ji gbe labule Tandama ati Danja.

O ni awọn osisẹ ọlọpaa gba idande awọn eeeyan naa lasiko ti wọn wọ ibuba awọn ajinigbe naa lọ.

Gambo fikun pe awọn ọlọpaa gbẹmi agbebọn kan, Abdulkarim Faca-faca ati awọn ọmọ ikọ ajinigbe rẹ meje lopin ọsẹ.

Isẹlẹ naa ni agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Katsina sọ pe o waye nijọba ibilẹ Safana nigba ti ọkọ ijagun ofurufu kan ya igbẹ iku le wọn lori ni ibuba wọn.

Ẹmi ọlọ́pàá méjì, aráàlú mẹ́rin bọ̀, bí agbébọn ṣe jí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè gbé lọ ni Kogi

Aworan awọn ajinigbe agbebon

Oríṣun àwòrán, DefencyHQ

Awọn afurasi agbebọn kan ti gba ẹmi ọlọpaa meji ati eeyan mẹrin miran, ki wọn to ji awọn ọmọ orilẹede India mẹrinla gbe lọ ni ipinlẹ Kogi.

Isẹlẹ naa lo waye lori afara odo Niger ni agbegbe Itobe, nijọba ibilẹ Ajaokuta ni asalẹ ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Awọn afurasi naa lo ṣe ikọlu si awọn arinrinjo nigba ti wọn n ti ileesẹ to n se awo, West African Ceramics bọ ninu bọọsi akero.

Osojumikoro to ba awọn akọroyin ṣorọ, ni kete ti awọn afurari agbebọn naa ganni awọn arinrinajo, ni wọn sina bole.

“Kete ti wọn bẹrẹ lati ma yin ibọn, eeyan mẹfa pẹlu ọlọpaa meji jẹ Ọlọrun ni pe, ti wọn si tun ji awọn ọmọ orilẹede india mẹrinla lọ.

“Ọjọ buruku miiran ni agbegbe Ajaokuta, a ko ti bọ lọwọ bi wọn ṣe pa awọn ọlọpaa meje ati bi wọn ṣe ji awọn ọmọ meta kan lọ, a tun ti ri isẹlẹ miiran.”

Kíni ìjọba ìpínlè Kogi sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

Aworan Gomina Yaya Bello

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba ipinlẹ Kogi ti kede pe awọn yoo ṣisẹ pẹlu awọn agbofinro lati dola awọn ti awọn afurasi agbebọn ji gbe lọ.

Ninu atẹsita ti Kọmisana fun irọyin ati ibanisọrọ, Kingsley Fanwo, fi sita fun awọn akọroyin, o ni awọn kọlọransi ẹda ni wọn gbinyanju lati ba isẹ ijọba ipinlẹ naa jẹ.

Fanwo wa rọ awọn araalu lati maṣe sọ igbagbọ wọn ninu ijọba nu nitori pe ẹtọ ijọba ni lati dola ẹmi ati dukia awọn araalu.

“Ipinlẹ Kogi da yatọ ti a ba sọrọ didola ẹmi ati dukia awọn araalu ati si awọn amulelẹgbẹ ipinlẹ naa.”

“Kete ti isẹlẹ naa waye ni awọn ẹsọ oju popo ti gbera lọ sibẹ, ti wọn ri pe ọwọ tẹ awọn ọdaran naa.”

Fanwo ni ijọba ipinlẹ Kogi mọ pe ẹmi araalu ṣe koko, ti awọn si ti ṣetan lati doola ẹmi araalu lọwọ awọn ajinigbe naa.

O wa rọ awọn olugbe Ajaokuta ati ipinlẹ Kogi lapapọ lati mase bẹru, amọ ki wọn si tẹsiwaju ninu karakata wọn nitori ijọba ti pese abo to peye fun wọn.

Àwọn afurasí agbébọn ṣékú pá ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn níwájú ṣọ́ọ̀bù ìyàwó rẹ̀ l'Osun

Aworan eeyan nilẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iroyin to n lọ kaakiri ni pe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ awakọ ti a mọ si NURTW ni ipinlẹ Osun, Rabiu Tajudeen, ni awọn afurasi agbebọn kan lori ọkada ṣe iku pa pẹlu ọmọbinrin rẹ lọjọ Ẹti.

Ẹwẹ, Ọlọpaa fi idi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe Tajudeen jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Ẹyẹ’ ni ipinlẹ naa.

Ki o to jẹ Ọlọrun nipe, Tajudeen, jẹ ọkan lara awọn osisẹ awakọ NURTW ni ibudokọ Eko to wa niluu Osogbo, ti wọn si ma n ri pẹlu Alaga awọn awakọ ni ẹka Oroki, Kazeem Oyewale, ti ọpọ mọ si Asiri Eniba.

Gẹgẹ bi oṣojumikoro ṣe sọ fun awọn akọroyin, o ni iwaju sọọbu iyawo rẹ to wa ni agbegbe garaaji Ileṣa ni awọn afurasi agbebọn naa ti yin ibọn fun un.

“O n ra ọṣẹ lọwọ ni awọn ọkunrin mẹta kan lori ọkada ṣina ibọn bolẹ fun un niwaju sọọbu iyawo rẹ ni garaaji Ilesa, ti o si ku lẹsẹkẹsẹ.”

Agbenusọ ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fi idi isẹlẹ na mulẹ pẹ, arakunrin naa ẹni ọdun marundinlaadọta ti jade laye latari bi awọn afurasi agbebọn naa ṣe yin ibọn fun un.

“A gba ipe ni ago kan ku iṣeju diẹ, ti a si mori le ibi isẹlẹ naa. A ba oku arakunrin kan ti orukọ rẹ jẹ Tajudeen Rabi, ẹni ọdun marundinlaadọta, ti oun naa jẹ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti awọn afurasi agbebọn to wa lori ọkada yin nibọn niwaju sọọbu iyawo rẹ".

“Kete ti wọn ṣe isẹ buruku naa ni awọn afurasi agbebọn ọhun fẹsẹ fẹẹ.”