Àwọn agbésùnmọ̀mí ti ń gbé àwọn obìnrin Kaduna ní ìyàwó, wo ibi tí wọn ń gbée gbà

Aworan afihan ọmọ obinrin ilẹ Hausa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n de si eti igbọ wa lati agbegbe Birnin Gwari ni ipinlẹ Kaduna sọ pe awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi Ansaru ti bẹrẹ si ni ṣeto igbeyawo laarin awọn ọmọ ogun rẹ ati awọn obinrin ilu naa.

A gbọ pe iru iṣẹlẹ naa tun waye ni ilu Tsohuwar Kuyallo, lọjọ Iṣẹgun nibi ti igbeyawo ti waye laarin awọn agbesunmọmi yii ati awọn ọmọ obinrin ilu.

Olugbe Birnin Gwari kan fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC to si ni iru rẹ ko ṣẹṣẹ maa waye lagbegbe naa.

O fi kun un pe ni nkan bii oṣu meji sẹyin awọn ọmọ ikọ naa kan fẹ awọn ọmọ obinrin meji kan ni agbegbe ọhun.

Ileeṣẹ BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kaduna lori iṣẹlẹ yi.

Esi wọn ni pe awọn n ṣe iwadii lori ọrọ naa.

Ṣugbọn onimọ nipa eto aabo kan Muhammad Kabir Isa ti Fasiti Ahmadu Bello ni Zaria loun gbagbọ pe aiduro deede ijọba nipa aabo lo jẹ ki ikọ agbesunmọ yi maa lo ọna naa lati wọ aarin awọn araalu.

''Nigba ti wọn ba bimọ fun wọn, awọn ọmọ ilu yi di ti wọn niyẹn. Eyi jẹ ọna fun wọn lati mu ki araalu gba ti wọn''

O ni aifun araalu ni itọju ati amojuto to yẹ lati ọdọ ijọba lo jẹ ki awọn ikọ yi tọ araalu lọ ti wọn si n ṣe iranwọ fun wọn ki wọn ba le gba ti wọn

Agbegbe Birnin Gwari ni Kaduna jẹ ọkan lara awọn ibi tawọn agbebọn ti n ṣe ikọlu si lẹnu ọjọ mẹta yii.

O jẹ ibi to ṣe pe lera lera lawọn janduku a maa ṣe ikọlu sawọn arinrinajo ti wọn a si maa ji awọn eeyan gbe tabi ki wọn si pa wọn.

O jẹ ibi tawọn eeyan foju si lara lẹnu lọọlọ yi lẹyin taa gbọ pe awọn ikọ agbesunmọmi Ansaru ti pẹka sibẹ.

Iroyin gbode nipa bi wọn ti ṣe gba akoso awọn agbegbe kan ni Birnin Gwari koda wọn ni ikapa lori awọn nkan to n ṣẹlẹ lawọn ilu mi lẹgbẹ rẹ.

Nkan bi ọdun mẹwaa sẹyin ni wọn da ikọ agbesunmọmi Ansaru yi silẹ ni Naijiria gẹgẹ bi ileeṣẹ iwadii aabo ISS ti ṣe sọ.

Ẹka yi yapa kuro lara Boko Haram nitori ede aiyede to wa laarin awọn alakatakiti ninu wọn ati awọn ti tiwọn ṣi rọ diẹ.

Lati igba naa ni wọn ti n gbooro si nipa ibaṣepọ pẹlu awọn agbegbọn ti wọn a si maa ji awọn eeyan gbe lagbegbe ibi ti wọn ba wa.