Àwọn ènìyàn dáwọ́ jọ lu àwọn awakùsà fẹ́sùn ìfipabánilòpọ̀

Aworan bí ile to n jo

Awọn olugbe Kagiso ni Johannesburg ni wọn dawọ jọ lu awọn awakusa tí wọn si tun dana sun ile wọn.

Eyi lo waye lẹyin ti foran kan bọ si ori ayélujára níbi tí awọn awakusa naa ti ifipaba àwọn ọmọbìnrin lopọ.

Awọn ọdọmọbinrin ni bi wọn ti ya sinima, ti awakusa naa si ṣe ìkọlù si wọn, tí wọn si ba pupọ laarin wọn sun pẹlu agídí.

Ọpọ lara awọn olugbe agbegbe naa ni wọn ti bẹrẹ lati ma le àwọn awakusa naa kuro agbegbe naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Orilẹede South Africa ti wá kede pe ọwọ wọn ti tẹ eeyan toju 130 lẹyin ti wọn ṣe iwadi lori iṣẹlẹ ifipabanilopọ to waye ni ọsẹ to kọja ni agbegbe naa.

Ifeohunhan ti wa bẹrẹ ni agbegbe naa ti awọn olopaa sì ti balẹ sì bẹ lati pẹtu si awọn eniyan agbegbe ti wọn setan lati fi ofin sì ọwọ ara wọn.