Kí ló ń jẹ́ Eyo, níbo ló ti wá sílú Eko, àwọn wo ló ń gbé e, kí sì ni èèwọ̀ rẹ̀?

Àkọlé fídíò, Kí ló ń jẹ́ Eyo, níbo ló ti wá sílú Eko, àwọn wo ló ń gbé e, kí sì ni èèwọ̀ rẹ̀?
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ilu kọọkan to wa nilẹ Yoruba lo ni ami idamọ tiẹ, ati awọn ọdun ibilẹ ti wọn n se, eyi ti wọn maa n ki oriki wọn mọ.

Bi Orò se wa nilẹ Ijẹbu, ti Olóòlú wa ni Ibadan, naa ni ọdun Ẹyọ wa nilu Eko.

Ẹyọ yii, ti wọn tun n pe ni Adamu Orisa, gẹgẹ ba se ri ka latara akojọpọ iroyin nipa rẹ loju opo Wikipedia, lo jẹ ọdun ibilẹ pataki, tawọn ọmọ bibi ilu Eko kii fi sere rara.

Amọ lojumọ to mọ loni, wọn ti gbe ọdun naa larugẹ debi pe o ti di apeyawawo, ti wọn fi n se irinajo afẹ, eyi to n mu owo wọle wa fun ilẹ wa.

Àmọ́ ẹẹkan ni ọdún méje ni wọn ń ṣe ayẹyẹ ọdún Eyo nílùú Eko.

Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Eyo to wọ aṣọ funfun

Kí ni ìtumọ̀ Eyo?

Ẹyọ lo tumọ si awọn onijo ti wọn n wọ asọ ibilẹ to yatọ, wọn yoo bori lati oke delẹ bii eegun pẹlu asọ funfun, wọn yoo de ate tabi akẹtẹ sori, ti wọn yoo si ma jo kiri pẹlu ọpa lọwọ lasiko ọdun.

A le ni ọdun Ẹyọ yii lo jẹ ohun ti awọn ẹgbẹ awo nilu Eko n se agbatẹru rẹ, ọgbẹri ko si le mọ nipa rẹ.

Laye ijọun, awọn Ẹyọ ni wọn maa n sin ọba tabi oloye pataki to ba waja lọ si itẹ, ti wọn si tun maa n se ayẹyẹ fun ọba tuntun to ba gun ori itẹ.

Ere ẹyọ yii lo dun wo, to si n se afihan asa ilẹ adulawọ, eyi ta le fi we ajọdun asa to maa n waye nilẹ Brazil.

Yatọ si ọdun Ẹyọ awọn ọdun mii wa tawọn eeyan Eko a maa se bi ọdun Egungun Awoo Ode, Oko aje ati ọdun Oya.

Amọ lara awọn ohun idanimọ ti ilu Eko fi di ilumọọka ni ọrọ aje to burẹkẹ nibẹ.

Ọkọ bogini kan tí Eyo léwájú rẹ

Oríṣun àwòrán, Lagosstategovernment

Níbo ni Eyo ti ṣẹ̀ wá?

Itan fi ye wa pe awọ̀n Ẹ́yọ̀ akọ̀kọ̀ lo jade to lọ̀wọ̀ọ̀wọ̀ nilu Eko ni ogunjọ osu keji ọ̀dun 1854 ni erekusu Eko, ni agbegbe Iga Iduganran.

Wọ̀n si se ọ̀dun Ẹ́yọ̀ yii lati se ayẹ́yẹ́ fun igbe aye Ọ́ba Akitoye tilu Eko ni.

Amọ̀ itan salaye pe ilu Iperu nipinlẹ Ogun ni Ẹyọ ti wa, ibẹ si ni orirun rẹ.

Pupọ eeyan nipinlẹ Eko lo gbọnju ba ọdun Ẹyọ pẹlu ọdun mii bi ọdun Igunnu tawọn babanla wọn maa n se.

Onírúurú Eyo to wọ aṣọ funfun

Oríṣun àwòrán, Lagos state government

Orisi Iga Ẹyọ to wa ni Eko ati Orukọ idile ti wọn n soju

Eyi ni àwọn Iga Ẹyọ to wa ni Eko ati Orukọ idile ti wọn n soju

Iga Ẹyọ to wa lati Iperu Akesan la le pin awọn idile to n gbe si marun, eyi ti wọn fi n sọri orisi Ẹyọ to wa nilu Eko.

Awọn si ni iwọnyi:

  • Iga Pakerike eyi to tumọ si Ẹyọ oni fila pupa
  • Iga Agbọnmagbẹ tii se Ẹyọ oni fila buluu
  • Iga Ẹyọ Odoru
  • Iga Ẹyọ Mogusen tabu Amororo
  • Iga Ẹyọ Fibigbuwa
Àwọn Eyo bíi marun to tẹle ara wọn. Wọn wọ aṣọ funfun gbagẹrẹ pẹlu ate funfun lórí, tí wọn sì dabu ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, Lagosstategovernment

Bi ọdun Ẹyọ se bẹrẹ ree:

Gẹgẹ bi itan se fi ye wa, Oba Eko nigba naa lọhun, Oba Akinsemoyin lo tọ Ẹyọ lọ, ki aburo rẹ Erelu Kuti baa le ri ọmọ bi.

Erelu Kuti pada ri ọmọ bi, to si se wipe awọn arọmọdọmọ rẹ ni wọn n jẹ alẹnulọrọ lori awọn to n jẹ Ọba ni Eko titi di oni.

Itan tun sọ fun wa pe, adugbo Oke Ipa to sun mọ agbegbe Glover ni Ikoyi, ni wọn ti kọkọ se ọdun Ẹyọ ni igba naa lọhun.

Orisirisi Eyo

Oríṣun àwòrán, Lagos state government

Ilana bi wọn ti n se ọdun Ẹyọ nilu Eko

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oke Ipa ni ibi tawọn ọba ati oloye maa n rinrin ajo ọlọjọ mẹta lọ lati le pejọ wo ere Ẹyọ.

Diẹ diẹ ere Ẹyọ di alarinrin ti wọn si n mu iyipada ba sise ere naa bi ọdun se n gun ori ọdun.

Lọpọ igba ti ọba ba waja ni wọn a maa se ere Ẹyọ tabi ni igba ti ọba mi ba gun ori apere.

Lode oni, wọn a maa se ere Ẹyọ lati fi se apọnle eekan ilu Eko to ba papoda tabi ti awọn alejo pataki kankan ba wa sabẹwo si ipinlẹ Eko.

Wọn a maa saba pari pọpọnsinsin Ẹyọ yii gbọngan nla Tafawa Balewa Square ni Ilu Eko.

Bẹẹ naa ni awọn Ẹyọ a tun maa kopa ninu ajọdun asa ti awọn alakoso ipinlẹ Eko ba seto, Arts and Culture Festival.

Bakan naa ni ipinlẹ Eko maa n gbe Ẹyọ lọ kopa ninu idije asa ati ibilẹ ni Naijiria, National Arts and Culture Festival

Ohun kan to se koko ni pe ere Adimu Orisa yii ko le ma waye ni Eko ti Ọba Eko ba waja.

Fawọn mọlẹbi to ba fẹ fi ere Ẹyọ se ayẹsi eeyan wọn pataki to papọda, o di dandan ki wọn kan si Akinsiku ilu Eko, to jẹ olori awọn ẹyọ fun iyọnda rẹ kawọn elere Ẹyọ to jade sita.

Àwọn onírúurú Eyo

Oríṣun àwòrán, Lagos state government

Gbogbo ọ̀nà ló máa ń di pa lásìkò ọdún Eyo nilu Eko

Lẹyin ti wọn ba ti mu awọn nkan etutu ati ẹbun to yẹ wa, ẹyin igba naa ni wọn to le da ọjọ ti Ẹyọ yoo jade sere .

Lọjọ ajọdun Ẹyọ, nise ni wọn maa n di gbogbo oju ọna ni erekusu Eko.

Lati oju ọna afara Carter Bridge titi de Tinubu Square, awọn alajọdun yii maa n di oju ọna naa ni.

Lati ibẹ ni wọn yoo ti wọ lọ si Iga Idunganran, ikorita Tafawa Balewa ni wọn si maa n pari gbogbo eto wọn si.

Awọn eewọ to maa n waye lasiko ọdun Ẹyọ:

Eyi ni àwọn eewọ to maa n waye lasiko ọdun Ẹyọ:

  • Ko gbọdọ si lilọ tabi bibọ Okada, kẹkẹ tabi mọto lati gbe ero
  • Ẹnikẹni ko gbọdọ wọ bata olokun ta mọ si Sandal
  • Awọn obinrin ko gbọdọ di irun Suku lati se ọdun Ẹyọ
  • Ẹnikẹni ko gbọdọ mu siga tabi fa igbo
  • Obinrin kankan ko gbọdọ we gele tabi bo irun ori rẹ pẹlu asọ kankan tabi wọ bata kankan
  • Ọkunrin kankan naa ko gbọdọ de fila lasiko ọdun Ẹyọ
  • Eewọ ni ki eeyan wọ ẹku Ẹyọ mọjumọ tabi ko wọ lati fi sọda odo tabi adagun omi kankan
  • Ẹnikẹni to ba rufin oke yii ni awọn Ẹyọ yoo fi ọpa ọwọ wọn na gidigidi.
Àwọn onírúurú Eyo

Oríṣun àwòrán, Lagos state government

Koko pataki nipa ajọdun Ẹyọ:

Ọsẹ kan saaju ki ajọdun naa to waye, awọn Ẹyọ agba maa n na ọpa sita fun gbogbo eeyan lati foju ri. Eyi tumọ si pe ọsẹ to n bọ ni wọn yoo jade Eyọ.

Lowurọ ọjọ ajọdun"Orisa Oniko" maa n jade lati wọ gbogbo aburu to wa ninu ilu danu.

Awọn ikọ mẹrẹẹrin Ẹyọ maa n to jade lọọkọọkan laarin ọjọ Aje si ọjọbọ. Awọn ikọ naa ni (Laba (Red), Oniko (yellow), Ologede (Green) ati Eyọ Agere (Purple)

Lẹnu ọjọ mẹta yii, wọn kii se ọdun Ẹyọ bii ti atẹyinwa mọ nilu Eko.

Akọsilẹ taa ri ni pe lọdun 2017 ni wọn ti se Ẹyọ kẹyin ni Eko, boya ọna lati dena iwa jagidijagan si ni eyi fi ri bẹẹ.

Nitori naa pupọ eeyan ni ko ni ranti Adamu Orisa ati pọpọsinsin ti o maa n ba ajọdun yii wa nipinlẹ Eko.