Ìbúgbàmù Offa tó ba ilé àti sọ́ọ̀bù jẹ́, ṣe èèyàn léṣe kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìkọlù Amẹ́ríkà, ohun tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà rèé

Oríṣun àwòrán, BBC/Abdulganiy Saad
Bi iroyin ikọlu Amẹ́ríkà si apa kan apá Oke ọya, lati ṣẹgun awọn agbesunmọmi ni Naijiria ṣe wáyé lọ́jọ́ Kérésì, ibẹrubojo tun bẹ silẹ ni ilu Offa, ni ijọba ibilẹ Offa, ni ipinlẹ Kwara.
Èyí kò sẹ́yìn bí ado oloro ṣe balẹ si ilu naa lalẹ ọjọ ọdun Keresimesi, eyi to ba ọpọlọpọ nnkan jẹ.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, a ko ti i mọ ibi ti wọn ran ado yii si ni pato.

Àwọn èèyàn kan sọ pé awọn Ṣọ́jà kan ni wọn n dan irinsẹ wọn wo, tí àdó ikú náà fi balẹ
Awọn kan sọ pe isẹ ọwọ awọn ọmọ ogun aarẹ Donald Trump ti ilẹ America ni.
Wọn ni ilu Babanla ti ijinigbe ti peleke ni agbegbe naa ni ado naa n lọ ko to sina balẹ̀ silu Offa.
Sugbọn awọn mii sọ pe ko ri bẹẹ, pe awọn Ṣọ́jà kan ni wọn n dan irinsẹ wọn wo.
Amọ latigba ti iṣẹlẹ naa ti sẹlẹ ni awọn eeyan ti n sa kijokijo, ti ọkan araalu ko balẹ.
Ado oloro naa ni a gbọ pe, lẹyin ti awọn erunrun rẹ ti ba awọn ile kan jẹ ní agbegbe Yidi, niṣe lo tun lọ balẹ si inu ile itura kan nitosi ibẹ.

"Aago mọ́kànlá alẹ́ kọjá ni ṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, banga là ro pe o dùn, àárọ̀ yìí la to mọ pé àdó olóró lo balẹ̀, ó sì ba nǹkan jẹ"
BBC News Yoruba kan si ọkan lara awọn osisẹ ile ìtura Solid Worth, tí àdó olóró balẹ̀ sí lánàá lori aago.
Ọgbẹni Musbau Adeyemi ṣalaye fun wa pe ado naa tobi gan-an, o si ba ni lẹru.
Adeyemi sọ pe latigba ti ado naa ti balẹ ni awọn ṣọja ti ti otẹẹli naa pa.
O ni eeyan kankan ko le wọle mọ, to fi mọ awọn osisẹ to ka mọ ita.
O ni koda, oun gan-an ko le ba wa sọrọ pupọ nitori awọn ṣọja naa n wo oun.
Nígbà to n bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, ọkàn lára àwọn èèyàn ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe àkóbá fún ilẹ̀ wọn, Tirimisiyu Tiamiyu Babatunde ṣalaye pe deede aago mọ́kànlá alẹ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
"Ana yẹn ni odun Kérésì, banga àti iná knockout ń dùn, èyí ló mú káwọn èèyàn tètè má kọbi ara ṣì pé àdó olóró lọ ń dùn.
Banga ni gbogbo wa ro pe o n dùn, àwọn èèyàn to wa ni adugbo ibi tí àdó ikú náà balẹ̀ sí nìkan ló mọ pe nnkan ṣẹlẹ̀ sáwọn.
Mo gbọ ìró bíi ìgbà tí bàálù ń bọ̀, a ro pe banga ni, ojú sanmọ lo tí balẹ, ó sì tún balẹ̀ sí ojú sanmọ padà, àárọ̀ yóò là to mọ pe o bá nnkan jẹ.
Àárọ̀ yóò náà là to mọ pe ilé ìtura Solid worth ni àdó oloro náà tí lọ balẹ̀. "

Oríṣun àwòrán, Abdulganiy Saad
Bákan náà, Kazeem tó ń gbé ní àdúgbò Yidi nilu Offa ṣàlàyé fún ikọ̀ BBC News Yorùbá pe bíi aago mọ́kànlá alẹ́ ni ọrẹ òun kan sọ pé àdó olóró dún ni àdúgbò àwọn.
"Àwọn sọọbu àti ògiri ọ̀pọ̀ ilé wo, mo lọ sí ẹ, mo fojú rí òun to ṣẹlẹ, àwọn ènìyàn miran gan farapa.
Àwọn agbófinró tí de síbẹ̀ àmọ́ a dupẹ pé ko si ẹnikẹni to kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ẹ̀rọ 'droonu' ni àwọn ọmọ ogun ń dán wo, lára àdó ikú to gbé sára ló ré bọ́ sílẹ̀ - Alága ìbílẹ̀ Offa
Lati fidi ohun to fa ibugbaamu yii mulẹ gan-an, BBC News Yoruba kan si Alaga ijọba ibilẹ Offa, Ọnarebu Sulyman Olanrewaju.
Ninu alaye Alaga naa ni awọn ologun kan lo dan ẹrọ droonu (drone) wo, ati pe awọn ohun ti droonu naa gbe lo re bọ silẹ.
Ọnarebu Olanrewaju sọ pe ohun to sẹlẹ ko ni i ṣe pẹlu awọn ogun ilẹ Amerika rara.
Alaga naa ni kawọn araalu ma ṣe bẹru, nitori gbogbo nnkan to n sẹlẹ wa labẹ isakoso.
Ẹwẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, SP Adetoun Ejirẹ Adeyemi, fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn oniroyin lọjọ Ẹti.
O ni iwadii to muna doko n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, lati foju ohun to sẹlẹ ni pato han gbangba.














