Àbúrò mi ti gba ìdájọ́ òdodo - Ẹ̀gbọ́n Iniuobong sọ̀rọ̀ sókè nípa ìdájọ́ lórí ìkú rẹ̀

Aworan ẹgbọn Iniubong

Ẹgbọn Umoren Iniubong ti arakunrin kan torukọ rẹ n jẹ Akpan ṣekupa lọdun 2021 ti ṣalaye pe inu mọlẹbi oloogbe naa dun pe o ri idajọ ododo gba.

Ni Ọjọbọ ni Onidajọ Bassey Nkanang ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Akwa Ibom kan dajọ iku fun Uduak Akpan pe ki wọn yẹgi fun un fun ṣiṣekupa Iniubong.

Akẹkọgboye ijinlẹ ninu ẹkọ Filọsọfi ni Umoren ki Uduak Akpan to fi ẹtan ipe fun iṣẹ tan an lọ to si gbẹmi rẹ.

“Mi o gbagbọ pe idajọ ododo wa fun mẹkunu bi tiwa. Gbogbo ireti wa lo ti pin lori ero pe magomago yoo wa lori idajọ naa nitori pe a ko mọ awọn ọtọkulu eeyan lawujọ. Amọṣa, a dupẹ pe a ri idajọ ododo gba. O ko le e pa aburo mi, ki o sin oku rẹ ki o si lọ bẹẹ. Gbogbo awa ẹbi ni inu wa dun si idajọ yii.”

Ọrọ yii ni Ukeme to jẹ ẹgbẹn Iniubong sọ fun awọn akọroyin.

Bakan naa ni Ukeme tun rọ ijọba lati ṣugba ẹbi naa pẹlu ọrọ iṣẹ nitori iṣẹ ni aburo oun n wa lọ to fi kagbako iku.

Eto idajọ ti wo ọgbẹ ẹbi Iniubong san- Agbẹjọro agba ni ipinlẹ Akwa Ibom

Aworan bi awọn wọda ṣe n gbe Akpan kuro ni ile ẹjọ

Nigba to n fi ero rẹ han lori idajọ naa, agbẹjọro agba fun ipinlẹ Akwa Ibom to jẹ aṣiwaju ikọ olupẹjọ lori ẹjọ naa kan sara si eto idajọ. O ni idajọ naa fihan pe nnkan rere ṣi n jade lẹka eto iṣedajọ, pẹlu igbagbọ pe idajọ naa yoo wo ọgbẹ awọn mọlẹbi rẹ san lori ọrọ naa.

Nigba to n sọrọ lori ohun to n fa a ti awọn gomina kii fi buwọlu iwe idajọ iku awọn ti wọn ba dajọ uiku fun, agbẹjọro agba naa sọ peohun to jinlẹ naa, ati pe ohun ti awọn eeyan n pe fun bayii ni atunṣe ofin naa eyi ti yoo yi ilana idajọ naa pada.

Akopọ aworan Iniubong ati Akpan to gbẹmi rẹ

Oríṣun àwòrán, Iniubong/bbc

“Ninu ofin Naijiria, ohun kan ṣoṣo ti wọn fi n dajọ iku fun apapniyan ni nipayiyẹgi fun ọdaranbẹẹ. Amọ awọn oṣiṣẹ ayẹgifunni ko fi bẹẹ pọ mọ ni Naijiria. Bi a ba yi ilana fifi idajọ iku lelẹ, yoo dara pupọ.”

Agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Samson Adula ni tirẹ sọ pe inu oun dun pẹlu bi idajọ naa ṣe yọri si nitori ojuṣe oun kii ṣe lati tako ẹsun naa tipatikuuku bikoṣe lati rii pe wọn tẹle ilana ofin gbogbo.

Lori boya yoo pẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa, amofin Adula ni kii ṣe ojuṣe oun lati gbe igbesẹ naa bi ko ṣe ti Uduak.

Kéré o! Ilé ẹjọ dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún ni fún Uduak Frank tó pa Iniuobong Umoren tó tún sin òkú rẹ̀ sí ọgbà bàbá rẹ̀

Uduak ati Iniuobong

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Adajọ agba Bassey Nkanang ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Akwa Ibom ti da ẹjọ iku nipa yiyẹ igi fun arakunrin to ṣekupa arabinrin Iniuobong Umoren.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Umoren jẹ akẹkọgboye imọ ẹkọ Philosophy ni Fasiti ilu Uyo ti wọn pa lasiko to lọ wa iṣẹ ninu oṣu keje ọdun 2021 lẹyin to kawe gboye to si n duro de lilọ ṣe agunbanirọ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn ni ọkunrin naa ṣeku pa Iniuobong to si lọ sin in sinu agbala ile baba rẹ ni ipinlẹ kan naa.

Iniuobong Umoren

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn eeyan to jẹjọ yii ni Uduak-Abasi Akpan to jẹ olujẹjọ akọkọ, Frank Akpan ati Anwan-Bassey Akpan ti wọn jẹ olujẹjọ keji ati ikẹta.

Olujẹjọ akọkọ ni, Uduak Frank ti wọn ni o pe Iniuobong pe ko wa gba iṣẹ.

O jẹjọ lori ẹsun meji iyẹn ifipabanilopọ ati ipaniyan eyi ti ile jọ si ri aridaju pe o jẹbi awọn ẹsun naa.

Ẹwẹ, olujẹjọ keji ati ikẹta to jẹ baba ati aburo obinrin si Uduak gba idalare lọdọ adajọ tori wọn rii pe wọn ko mọ nkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn.