Díẹ̀ lára ìgbà tí Amotekun ti mú àwọn afurasí ọ̀dàrán ní Ondo

Awọn oṣiṣẹ Amotekun

Oríṣun àwòrán, Other

O ti to asiko diẹ ti iroyin n jade, nipa bi ajọ alaabo Amotekun ṣe n mu awọn afurasi ọdaran jakejado ilẹ Yoruba, paapaa nipinlẹ Ondo.

A ṣe ayẹwo diẹ lara awọn igba ti ajọ Amotekun nipinlẹ Ondo ti mu awọn afurasi ọdaran to n dunkooko mọ eto aabo ipinlẹ naa ree.

Amotekun mu afurasi ọdaran 45

Ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni ajọ alaabo Amotekun nipinlẹ Ondo kede pe oun mu afurasi ọdaran marunlelogoji nipinlẹ naa.

Bo ti lẹ jẹ pe nigba ti iroyin naa jade, ọpọ lo sọ pe ẹya Fulani ni gbogbo awọn ti wọn mu.

Ṣugbọn ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ, oludari ajọ naa, Oloye Adetunji Adeleye sọ pe kii ṣe gbogbo wọn lo jẹ Fulani.

O ni mẹfa lara awọn eeyan naa jẹ ajinigbe, to ma n fi oogun mu awọn to ba ko si panpẹ wọn.

Awọn mọkandinlogoji yooku ni wọn mu fun ẹsun idigunjale, ifipabanilopọ ati ẹran nkan ọsin jiji.

Ọwọ Amotekun tẹ awọn afurasi to kọlu ile ijọsin ni Owo

Amọtẹkun nipinlẹ Ondo sọ pe oun mu awọn eeyan kan to lọwọ si ikọlu oati ipaniyan to waye ni ile ijọsin St. Francis Catholic Church, nilu Owo.

Ni ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2021, ni ajọ alaabo Amotekun nipinlẹ Ondo fi iroyin sita pe oun fi ofin mu irinwo maalu nipinlẹ naa.

Oṣu Kẹfa ni ikọlu naa waye lasiko ti isin ọjọ Aiku n lọwọ. Eeyan to le ni ni ọgọrun lo kagbako ikọlu naa, ti ọpọ ninu wọn si ku.

Oludari ajọ naa nibẹ, Oloye Adetunji Adeleye sọ pe nilu Akure, ati awọn ijọba ibilẹ mii, ni awọn ti ko awọn maalu naa, to n rin laarin igboro.

Igbesẹ naa waye lẹyin ti ijọba ipinlẹ Ondo ṣe ofin pe ẹnikẹni ko gbọdọ da ẹran laarin igboro mọ.

Ninu oṣu kẹsan-an bakan naa, wọn ni awọn tun mu maalu ti ko din ni ọgọsan, pẹlu darandaran mẹta to wa pẹlu wọn, nilu Akure.

Amotekun mu ọkunrin mẹtadinlogun pẹlu aja 35 ati oogun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ karundinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2022, ni Amotekun kede pe ọwọ oun tẹ arinrinajo to jẹ gende ọkunrin mẹtadinlogun, to wọ ipinlẹ naa.

Wọn ṣalaye pe nilu Okitipupa, nijọba ibilẹ Okitipupa, ni ọwọ ti tẹ wọn, pẹlu aja marundinlogoji, ati ọpọlọpọ ada, ati oogun ti wọn ko dani.

Awọn araalu naa lo ta ajọ Amotekun ni olobo, nigba ti irin awọn ọkunrin naa bẹrẹ si mu ifura dani, paapaa nigba ti wọn n wọ inu igbo nla kan to wa lẹyin baraaki ologun nilu naa.

Oludari Amotekun ni ipinlẹ naa sọ pe awọn afurasi naa ni awọn wa ba ẹnikan ṣiṣẹ oko nilu naa ni.

O ni ṣugbọn, gbogbo igbiyanju awọn lati ri ẹni ti wọn lo gba wọn siṣẹ ba sọrọ tabi fojuri titi di asiko ti iroyin naa jade, lo ja si ofo.

“Awọn ọkunrin naa sọ pe lati Ariwa Naijiria ni ọkọ̀ ti ko awọn wa si Okitipupa fun iṣẹ.”

Botilẹ jẹ pe ajọ naa ma n sọ pe oun ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lori awọn afurasi to ba mu, a ko le fidi eyi mulẹ, paapaa bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ma n sọ ni ọpọ igba pe oun ko mọ nipa awọn ti ọwọ Amotekun ba tẹ.

Fun apẹẹrẹ, eyi waye lasiko ti Amotekun kede pe awọn mu lara awọn to ṣe ikọlu si ile ijọsin nilu Owo.