Kìí ṣe Fulani nìkan ló wà nínú àwọn ọ̀daràn táa mú – Amotekun Ondo

Amotekun Ondo

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun ìpínlẹ̀ Ondo ti ṣàlàyé irú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n mu ní ìpínlẹ̀ náà.

Adarí ikọ̀ Amotekun Ondo, Adeleye Olusanyero tó bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́rú ṣàlàyé pé kìí ṣe àwọn Fulani ní àwọn mú bíkòṣe àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn.

Olusanyero ní ọ̀daràn ni ọ̀daràn ń jẹ́ láì fi ẹ̀yà tàbí ohunkóhun ṣe.

Ó fi kun pé gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà ni àwọn ti mú àwọn afurasí ọ̀daràn márùndínláàdọ́ta yìí.

Ó ní oríṣiríṣi ẹ̀sùn bíi ìjínigbé, ìfipábánilòpọ̀, ìpànìyàn, olè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn mú àwọn afurasí náà fún.

Olusanyero ṣàlàyé pé àwọn mìíràn máa ń jí ọ̀kadà gbé tí wọ́n máa ń tú ẹ̀yà ara rẹ̀ tà láti lọ tun tà sí ilẹ̀ òkèrè.

Ó ní ọ̀sẹ̀ méjì ni àwọn fi ṣe gbogbo àwọn ìwádìí yìí kí àwọn tó nawọ́ gán àwọn tí wọ́n mú náà.

Bákan náà ló ni gẹ́gẹ́ bí òfin tó gbé àwọn dúró gẹ́gẹ́ bí agbófinró ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, Amotekun ní ẹ̀tọ́ láti gbé àwọn ọ̀daràn lọ sí ilé ẹjọ́ láì gba ọ̀dọ̀ ọlọ́pàá.

A ti gbé àwọn mẹ́sàn-án lọ sí ilé ẹjọ́ nínú àwọn afurasí náà

Olusanyero tẹ̀síwájú pé nínú àwọn tí àwọn nawọ́ gán ọ̀hún, àwọn mẹ́sàn-án nínú wọn ni àwọn ti gbé lọ sí ilé ẹjọ́ ní òwúrọ̀ òní ti ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí àwọn yòókù.

“Òfin tó gbé àjọ Amotekun kalẹ̀ fàyè gbàwá láti lo ọ́fíìsì DPP ní iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ láti fi gbé àwọn afurasí lọ sí ile ẹjọ́.”

“Fúnra ra wa la máa ń gbé àwọn afurasí ọ̀daràn ta bá mú lọ sí ilé ẹjọ́.”

Ó fi kun pé àwọn ọ̀daràn tó ti gba àjọ àwọn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ti tó ẹgbẹ̀rún kan láàárín ọdún kan.

Ó ní àwọn márùndínlọ́gbọ̀n niàwọn ti parí ìwádìí lórí wọn tí ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́ lórí àwọn yòókù.