Ikú dóró! Wo bí àwọn ajínigbé ṣe pa òṣìṣẹ́ Hótẹ́ẹ̀lì tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LAUTECH àti oníṣòwò lẹ́yìn tí wọ́n gba N5m

Oríṣun àwòrán, Other
Oniṣowo kan, Olugbenga Owolabi ati akẹkọọ fasiti Ladoke Akintola, Rachael Opadele, ti awọn agbebọn kan jigbe nilu Ogbomoso lọsẹ to kọja ti ku.
Owurọ Ọjọbọ ni iroyin jade pe awọn ajinigbe naa ti pa wọn.
Bakan naa ni iroyin naa sọ pe wọn tun pa ọkunrin ọlọkada to gbe mọlẹbi ẹnikan ninu wọn lọ sibi to ti fẹ san owo itusilẹ, ti mọlẹbi naa si farapa.
Agbegbe Abaa nilu Ogbomoso, ni wọn ti ji awọn eniyan naa gbe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022.
Ọgbẹni Owolabi lo ni ile itura ti wọn ti gbe wọn, ti Arabinrin Opadele si jẹ oṣiṣẹ nibẹ.
Iroyin sọ pe iyanṣẹlodi awọn olukọ fasiti, ASUU, to n lọ lo mu ki ọmọbinrin naa lọ ṣiṣẹ nibẹ.
Ọgọrun miliọnu Naira la gbọ pe awọn ajinigbe naa kọkọ beere fun lọwọ awọn ẹbi wọn.
Mọlẹbi to fidi rẹ mulẹ fun BBC, amọ ti ko fẹ ka da orukọ rẹ, sọ pe ẹbi ko miliọnu marun-un Naira jọ, lẹyin iduna-dura pẹlu awọn ajinigbe naa.
Amọ wọn yinbọn pa awọn eeyan naa lẹyin ti wọn gba owo tan ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ.
Wọn yinbọn mọ ẹni to gbe owo lọ, ṣugbọn o pada ri aaye salọ.
Ijinigbe meji ti kọkọ waye ni Ogbomoso
Laipẹ yii ni awọn ajinigbe gbe alamojuto oko gomina ipinlẹ Oyo nigba kan, oloogbe Alao Akala, Christopher Bakare ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje.
Wọn tun ji dokita kan to ni ileewosan adani nilu naa, Abdulrasheed Oladoye lọjọ kejilelogun, oṣu Keje.
Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, si ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo kede pe ọwọ oun ti tẹ afurasi mẹjọ to lọwọ ninu ijinigbe naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa Oyo, Adewale Osifeso sọ ninu atẹjade pe ọwọ awọn tẹ awọn afurasi naa to n da ipinlẹ Oyo laamu nipa ijinigbe.










