Àráàlú rò pé ajínigbé ni wọ́n, wọ́n dáwọ́ lu ẹbí kan tó kó ọmọdé sínú ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, POLICE/INSTAGRAM
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti rọ àwọn ará ìlú láti máa ṣe jẹ́jẹ́ lórí àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi máa ń ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin pàrọwà yìí lẹ́yìn tí àwọn mọ̀lẹ́bí kan jẹ moyó ìyà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn kan lórí afárá Eko bridge.
Hundeyin nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ẹ̀rọ Insatagram rẹ̀ lọ́jọ́rú ṣàlàyé pé àwọn ẹbí náà èyí tí ìyá arúgbó kan wà nínú wọn ń bọ̀ láti òde tí wọ́n sì ṣì wọ́n mú gẹ́gẹ́ bí gbọ́mọgbọ́mọ.
Àwọn ọmọ méjìlá, láti ọmọ oṣù méje títí dé orí ọmọ ọdún méjìlá ló wà nínú ọkọ̀ àwọn ẹbí náà.
Ó fi kun pe orí ló kó àwọn ẹbí náà yọ nítorí àwọn ènìyàn náà kò bá ti lù wọ́n pa tí kìí bá ṣe wí pé àwọn ọlọ́pàá Ebute Ero àti ikọ̀ RRS tó tètè débi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó ní ìwádìí àwọn ṣe àwárí wí pé ẹbí ni gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ọ̀hún àti wí pé láti etí òkun ni wọ́n ti ń bọ̀.
Hundeyin sọ síwájú pé àwọn ẹbí náà lọ ṣe àdúrà ní etí òkun ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ń bọ̀ ni wọ́n kó sọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n rò wí pé ajínigbé ni wọ́n.
Ó ní ọkọ̀ tí wọ́n gbé jáde ni àwọ́n náà jó níná pátápátá.
Bákan náà ló ní àwọn ti gbé ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí àwọn ìwà ọ̀daràn.















