Àwọn agbénipaṣètùtùọlà pa ìyá ẹni ọdún 65, yọ ojú rẹ̀ ní Ilesa

Aworan ọwọ kan to mu ọbẹ dani

Oríṣun àwòrán, other

Ni opin ọsẹ to kọja lawọn mọlẹbi iya agbalagba kan ti orukọ rẹ n jẹ Tunmiṣe Oluyẹmi ni ilu Ileṣa ni ipinlẹ Ọṣun ke gbajare sita pe awọn n wa iya agba ẹni ọdun marundinlaadọrin naa.

Gbogbo ibi ti wọn lero pe iya agba naa lee lọ ni wọn wa a de ṣugbọn to jẹ pe pabo ni, wọn ko rii.

Lẹyin ọjọ mẹta ti awọn mọlẹbi yii ti n wa a ni wọn ri pe awọn afurasi agbnipaṣoogun ọla kan ti pa iya agba naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun gbe atẹjade kan sita lọjọ Iṣẹgun pe wọn ri oku arabinrin naa ni oko rẹ, ṣugbọn wọn ti yọ oju rẹ kan lọ.

Iroyin sọ pe lẹyin ti awọn mọlẹbi rẹ fọn sigboro lati wa a ni wọn ri oku rẹ lọjọ Aje.

Ninu atẹjade to fi sita, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ọmọbinrin iya agba naa lo fi to ọlọpaa leti pe wọn ti ri oku iya awọn.

“Ni nnkan bi agogo kan ọsan ọjọ Aje, eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Dare Oluyẹmi lagbegbe Ọdundun ni ilu Ileṣa wa fi ọrọ to ọlọpaa leti pe iya oun, awọn ti ri oku iya oun, Oluyẹmi Tunmiṣe ẹni ọdun marundinlaadọrin ti gbogbo ẹbi ti n wa lati ọjọ Abamẹta.

“O ni wọn ri oku rẹ, ṣugbọn wọn ti yọ oju rẹ kan lọ ni ori oko rẹ to wa lagbegbe Fadahunsi nilu Ileṣa ni nnkan bii agogo mọkanla abọ lọjọ Aje.”

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun ni awọn ti de ibi ti iṣẹlẹ laabi naa ti ṣẹlẹ lati ya aworan gbogbo to lee ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ ninu iwadii wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni arabinrin ọmọ oloogbe atawọn ọmọ miran ti oloogbe naa bi kọ jalẹ lati fun awọn ọlọpaa lanfani lati gbe oku naa lọsi ile igbokupamọsi tabi ṣe iwadii kankan lori iku naa.

O ni koda wọn leri lati kọlu awọn ọlọpaa to lọ sibẹ, ti wọn si ni nṣe lawọn fẹ sin oku awọn.