Àwọn ọ̀kùnrin tó ń múra bí obìnrin sọ̀rọ̀ sókè lórí àbádòfín tó fòfin de kí ọkùnrin máa ṣè bí obìnrin nípa aṣọ wíwọ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn ọmọ Naijiria to ti pa ẹya ara wọn da kuro ni akọ tabi abo, ti wọn n pe ni ‘Transgender’, ti fi aidunnu wọn han si abadofin to fẹ fi ofin de ki obinrin maa ṣiṣe ọkunrin tabi ki ọkunrin maa ṣiṣe obinrin nipa aṣọ wiwọ.
Abadofin naa lo fẹ fi kun ofin to takọ ki akọ ati akọ fẹ ara wọn, tabi abo ati abo fẹ ara wọn (Same-Sex Marriage (Prohibition) Act (SSMPA).
Awọn ti wọn ma n wọ aṣọ tako ẹda wọn yii, ti wọn n pe ni ‘Transgender’ tabi cross dresser nitori kii ṣe aso eda won ni wọn n wọ.
O ṣeeṣe ki ẹni to ba jẹbi ẹsun yii fi ẹwọn oṣu mẹfa jura, tabi ki o san ̣egbẹrun kan owo dọla ilẹ okeere.
Amọ eyi ko ṣe deede lara awọn ti wọn ti pa ẹda wọn da yii, ti wọn si fi apa janu lori rẹ.
‘’Wiwo aṣọ ẹda ti a yi pada si lo ma n fun wa ni ifọkanbalẹ lori ẹda tuntun ti a yipada si’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ni ọdun 2014 ni aarẹ nigba kan ri, Goodluck Jonathan buwọlu abadofin to tako igbeyawo akọ si akọ tabi abo si abo tabi fifi ifẹ han si ara wọn ni awujọ.
Jonathan sọ nigba naa pe oun fi aṣẹ si ofin naa lati le di opo idile mu ati jẹki itẹsiwaju ba awujọ eniyan.
Bakan naa ni awọn aṣofin ni bi awujọ orilẹede Naijiria ṣe ri ni awọn ṣe gbe igbese naa.
Amọ ọkunrin to ti yipada si obinrin , Fola Francis ni eleyii ba oun lẹru gidigidi nitori lai tii si iru ofin bẹẹ , ojojumọ ni wọn n dunkoko iku mọ oun, ti wọn si n wa ati pa oun.
O ni yoo jasi akọba fun awọn miran bii ti oun ti ko gbagbọ ninu akọ ati abọ.
Bobrisky to jẹ ilumọọka loju opo Instagram rẹ naa lo bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ abadofin naa pe ṣe abadofin ohun ni yoo yanju ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ abi ina ọba to wọngogo.
Bakan naa lo ni ṣe igbesẹ ọhun yoo mu ki orilẹede Naijiria ni iyi si lagbaye.
Ninu ọrọ tirẹ, James Brown ni awọn ti wọn yi ẹda wọn pada n wọ aṣọ ẹya ti wọn yi di nitori yoo fun wọn ni ifọkanbalẹ pe wọn ṣe ohun to wu wọn.
‘’Abadofin naa yoo gbe idile ro’’
Amọ ọkan lara awọn alatilẹyin abadofin naa, Mada Lawal Ulnar ni inu oun dun si aabadofin naa , ti oun yoo si buwọlu u nigba ti wọn ba gbe de fun kika ẹlẹẹkeji ni Ile Aṣofin Naijiria.
Ninu ọrọ tirẹ, Agbẹjọro Manfred Ekpe ni ile aṣofin n ṣiṣẹ takuntakun lati gbe awujọ to bu iyi kun ọmọ eniyan kalẹ.
Bakan naa ni wọn gbe ẹka ẹsẹ Bibeli ati Quran to ṣatilẹyin fun abadofin naa sita.















