Ìjọba Naijiria ra ọkọ̀ tí iye owó rẹ̀ tó ₦1.4b fún ètò àbò orílẹ̀-èdè Niger Republic

Buhari

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Ijọba Naijiria ti sọ pe lootọ ni oun ra ọkọ ti iye owo rẹ to ₦1.4b fun orilẹ-ede Niger Republic lọna ati le koju eto abo to mẹhẹ nibẹ.

Minisita eto iṣuna, Zainab Ahmed lo fidi ọrọ naa mulẹ lọjọru.

O ni kii ṣe igba akọkọ ree ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe iranwọ fun orilẹ-ede naa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Buhari lagbara lati ṣe bẹẹ gẹgẹ bii Aarẹ orilẹ-ede, oun ko si laṣẹ lati bere eredi to fi ṣe bẹẹ lọwọ rẹ.

O fi kun pe iranwọ naa waye lẹyin ti ijọba Niger bere fun un, ati pe orilẹ-ede Naijiria naa yoo janfani ibaṣepọ ọhun.

Minisita naa lo fi ọrọ yii lede lasiko to n dahun awọn ibere kan lẹyin ipade igbimọ ijọba apapọ to waye l’Abuja, eyii ti Aarẹ Buhari dari rẹ.

Ṣaaju ni awọn iwe kan ti kọkọ ṣafihan pe ijọba apapọ buwọlu owo naa fun lilo orilẹ-ede Niger Republic laarin oṣu Keji ọdun yii.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba Naijiria yoo gbe owo kalẹ fun akanṣe iṣẹ fun orilẹ-ede Niger.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2021 ni ijọba Naijiria kede pe oun yoo kọ oju ọna reluwe kan lati Naijiria lọ si Nigeri Repuclic yii kan naa.

Gẹgẹ bii ohun ti minisita eto irina, Rotimi Amechi sọ, iye ti oju ọna irin naa yoo na Naijiria ko ni din ni biliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika.

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Ki lo fa alaye yii lati ọdọ ijọba apapọ?

Gbajumọ ori ayelujara kan ni o kọkọ gbe iroyin sita lori ayelujara pe aarẹ Buhari ti buwọlu aṣẹ kan ni ọjọ kejidinlọgbọn ọdun 2022 lati fi owo gọbọi ra ọkọ fun orilẹede Niger.

Ibeere lori eyi ni awọn akọroyin beere lọwọ minisita eto iṣuna, ti o fi dahun pe lootọ ni ati wi pe Naijiria ni ilana kan lati maa ṣe eto iranwọ fun awọn orilẹede to yii ka, paapaajulọ awọn orilẹede to yii po lati rii pe abo wọn di abo fun Naijiria.

Minisita feto iṣuna, Zainab Ahmed

Oríṣun àwòrán, Screenshot

“Ẹ jẹ ki n laa mọlẹ fun yin bayii pe, Naijiria gbọdọ gbaruku ti awọn alamuleti rẹ.

Igba akọkọ kọ niyi ti Naijiria yoo maa ṣe iranwọ fun Niger, Cameroun tabi Chad, bẹẹni aarẹ lo n gbe ọrọ yẹwo lati mọ ohun ti wọn nilo pẹlu arọwa ti aarẹ orilẹede wọn ba gbe tọ aarẹ orilẹede Naijiria wa niwọn bi o ti ṣe niiṣe pẹlu abo orilẹede Naijiria.

“Awọn ọmọ Naijiria lẹtọ lati beere ibeere, bakan naa ni aarẹ pẹlu ni ojuṣe lati gbe e yẹwo ohun to dara fun orilẹede yii. Emi naa o lee pe igbesẹ aarẹ lẹjọ. Mo ti sọ pe igba akọkọ kọ niyi ti orilẹede Naijiria yoo maa ṣe iranwọ fun awọn orilẹede to yii ka lẹyin ti aarẹ ba gbe e yẹwo lati mọ boya yoo ṣanfani fun Naijiria lati ṣe bẹẹ.”