'Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló pè mi tó fún mi l'ànfàní láti kọrin ayé díẹ̀ kí n tó di olórin ẹ̀mí'

Àkọlé fídíò, Oluwanisola Ayinla blind musician: Ọmọ ọdún àtí ọjọ́ méjì ni ojú mi fọ́, a gbìyànjú di ọsú
'Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló pè mi tó fún mi l'ànfàní láti kọrin ayé díẹ̀ kí n tó di olórin ẹ̀mí'

Ọmọ ọdun kan ati ọjọ́ méjì ni African Stevie Wonder ti awọn eeyan agbegbe rẹ mọ ọ si bayii ti di ẹni ti ko ni oju mọ.

"Lati kekere ni mo ti fẹran lati maa kọrin mo si tun maa n lu ilu fun awọn olorin ko to di pe irawọ temi naa yọ gẹgẹ bi olorin".

Oluwanisola Ayinla Babatunde ti wọn n pe ni African Stevie Wonder sọ fun BBC Yoruba pe Ọlọrun funrarẹ lo pe oun pe oun kan fun un lanfani diẹ lati kọrin fun aye.

Oluwanisola Ayinla

"Nigba ti iya jẹ mi ti awọn eeyan ko gbe iṣẹ fun mi mọ ni mo mọ pe, o dabii pe baba yii lo le ṣee o".

O ṣalaye bo ṣe bẹrẹ lasiko to ni ifẹ si orin Fuji amọ ti o dede yi biri nigba to ni oun gba ipe lati ọdọ Ọlọrun.

Bakan naa ni o gba awọn ọdọ Naijiria nimọran ki wọn wo oun fi ṣe awokọṣe.