'Kìí ṣe torí kí n lè ní Pálí ìgbélù America ni mo ṣe fẹ́ ọkọ mi tó wà lórí "wheelchair", ǹkan tí mo fẹ́ lára rẹ̀ rèé'
"Màmá mi gan tí mo lérò pé wọ́n á bínú, mi ò lérò pé wọ́n bí ọkọ mi títí di ọ̀la pé kílódé tó fi wa lórí Kẹ̀kẹ́ Arọ".
Akọṣẹmọṣẹ oniroyin kan to fi ilu amẹrika ṣe ibugbe, Ranti Agbaminola ti kẹnu bọ itan lati bu ẹnu atẹ lu aduru ọrọ ti awọn eeyan n sọ sii lori ayelujara ati kaakiri lori iru ẹni to yan lati fẹ gẹgẹ bi ọkọ.

Oríṣun àwòrán, Temitayo Agbaminoja
O ṣalaye pe ọpọlọpọ eeyan lo n bu oun lori nkan ayọ oun ti wọn si n sọ pe boya tori owo ati tori ati ni iwe igbelu ilẹ Amẹrika loun ṣe fẹ Temitayo toun ti ẹsẹ rẹ mejeji to ti rọ to si ti dee mọ ori kẹkẹ arọ.
Ni ti Ọgbẹni temitayo Agbaminoja, inu rẹ dun ayọ rẹ si kun tori o ni ero awọn eeyan si oun yatọ nitori ipo ilera rẹ.

Oríṣun àwòrán, Temitayo Agbaminoja
O ṣalaye fun BBC Yoruba nipa bi iṣẹlẹ naa ṣe kọ lu u nigba to ṣi wa ni ọmọ oṣu meje.
Iyawo rẹ tun sọ bi ọpọlọpọ eeyan ṣe n rọjo epe lee lori nigba ti wọn ri fọto ati fidio igbeyawo wọn ti aye gbọ ti ọrun si mọ to tun wa gba ori ayelujara kan ni ibẹrẹ ọdun 2022.

Oríṣun àwòrán, Temitayo Agbaminoja
Amọ lodi si ero awọn eeyan ati iroyin ti wọn n gbe kaakiri, Ranti ṣalaye bi o ṣe gba iwe igbelu Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Temitayo Agbaminoja



